Ara ÈkéÀpẹrẹ

Ara Èké

Ọjọ́ 5 nínú 7

Nínú ìjọsìn tó kọjá, Ádámù àti Éfà rí ara wọn láwòtán fún ìgbà àkọ́kọ́, wọn si fi èwe igi ọ̀pọ̀tọ́ bora.

Ronù nípa èyí dáadáa. Àwọn èwe wọnyẹ yóò pàpà gbẹ, èyí tí yóò mú kí Ádámù àti Éfà wá ọ̀nà míràn láti bo èrè àìgbọràn wọn. Èyí ni ipa ìtìjú; a má a tì wá lọ pàdé àwọn aìní wa nípa lílo àwọn ọrọ̀ ti Ọlọrun ó yàn fún wa láti lò.

Ẹ̀rí ọkàn wá nípa ìwà - mo ṣe ǹkan tí kò tọ́. Ìtìjú wá nípa ìdánimọ̀ - ń kankan wá tí kò tọ̀nà nípa à mi.

Bótilẹ̀jẹ́pé ẹ̀rí ọkàn lè ṣe ìwúrí fún wa sí ìrònúpìwàdà, ìtìjú kò wà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ó ńkọlu ìdánimọ́ wá, ó ńpa irọ́ fún wa wípé, “O jẹ́ lọ wá ǹkan láti fi bo èyí bíbẹ̀ẹ̀kọ́ a kò ní ní ìfẹ́ ẹ̀ rẹ mọ́.”

Àwọn èwe igi ọ̀pọ̀tọ́ wá, àwọn ǹkan tí à ń fi síwájú ìbòjú ara èké wa láti bo àwọn àlèébù wa, ma ń wá ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà:

Iyì: Iyìn tó dá lé ipò láwùjọ.

Agbára: Ìṣàkóso l’órí àwọn míràn àti ìṣẹ̀lẹ̀.

Gbajúmọ̀: Ìfọwọ́sí tó ń fún wa níyì.

Ènìyàn: Àwọn ìbáṣepọ̀ tó ń ṣètumọ̀ ìdánimọ́ wa

Pípé: Ìgbìyànjú fún ayé tí kò lábàwọ́n.

Èyí tó burú ju nípa àwọn èwe igi ọ̀pọ̀tọ́ wa ni pé wọn ń ṣíṣe, ìbá à ṣe fún ìgbà díẹ̀. Wọn ń ti ìtìjú wá bọlẹ̀ kí ayé tó yí wa ká lè rí ǹkan tí a fẹ́ kí wọn rí nìkan. Ṣùgbọ́n aò lè tan Ọlọ́run jẹ. Bíi Ádámù àti Éfà nínú ọgbà, ìfẹ́ rẹ̀ wọnú ara èké wá kọjá, ó sì rí wa bí a ṣe jẹ́ lòtítọ́ - ẹni tó nílò ìgbàlà gidi gan.

Ìyìn rere na si rè: Ọlọ́run ò dáa dá wa láti wọ ìjàkadì pẹ̀lú àwọn ààbò èké àti ìtìjú fún ra wa. Ó rán Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ wá láti pọn wá kún pẹ̀lú àfihàn Ọlọ́run àti agbára rẹ̀. Ẹ̀mí Mímọ́ ń fún wa lágbára láti bọ́ àwọn èwe igi ọ̀pọ̀tọ́ wá - ká fi ara èké wá sẹ́yìn - ká sí ṣàwárí ẹni tí a jẹ lóòótọ́ nínú Jésù.

Ìríṣí:

Ṣé àwọn èwe igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ má ń ṣú ọ? Ǹjẹ́ ìtìjú rẹ ti mú ọ gbé nínú ìbẹ̀rù dípò inú ìfẹ́ Ọlọ́run? Lónì, o lè jọ̀wọ́ ayé rẹ fún òmìnira Ọlọ́run kí o sì jẹ kí ó da àfihàn Ẹ̀mi Mímọ́ àti ìfẹ́ rẹ̀ bò ọ́.

Àdúrà:

Ọlọ́run, dáríjì mí fún gbogbo ìgbà tí mo ti gbìyànjú láti ṣètumọ̀ ìdánimọ́ mi yàtọ̀ si ìwọ. Fi Èmi Mímọ́ rẹ kún inú mi láti rán mi lọ́wọ́ nínú àìlera mi. Àmín.

Nípa Ìpèsè yìí

Ara Èké

Ǹjẹ́ àwọn ìbẹ̀rùbojo ati àìláàbò ayéè rẹ ti tì ọ́ sínú ìdánimọ̀ tó ṣe àjèjì? Kíni ìwọ̀n ìyàtọ̀ tó wà ní àárín ẹni tí ìwọ jẹ́ ní òtítọ́ àti àwòrán rẹ tí o fi ń han àwọn míràn? Ní ìbásepọ̀ pẹ̀lú LUMO àti OneHope, àti tó dá lórí ìwàásù Àlùfáà Tyler Staton, ètò ọlọ́jọ́ méje yí yóò mú ẹ ṣe àyẹ̀wò òtítọ́ kodoro tó wà lẹ́yìn “ara èké.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ OneHope fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: www.lumoproject.com