Ara ÈkéÀpẹrẹ

Ara Èké

Ọjọ́ 3 nínú 7

Òdòdó kìí mú ìjàkadì pẹ̀lú ìdánimọ̀ rẹ̀ - láì tiraka ó ń fi ògo fún Ọlọ́run bí a ti ṣe ìṣẹ̀dá rẹ̀.

Ó ṣe é ṣe kí gbogbo wá ti ní ìrírí i kí ẹnìkan ṣì wá mú fún ẹlòmíràn nínú ẹbí wa. À ń gbọ́ tí wọ́n á sọ wípé, “O jọ bàbáà rẹ,” abi “ojú ìyáà rẹ lo mú.“ A má ń tẹ̀síwájú pẹ̀lú àfijọ àwọn tí wọ́n ṣíwájú wa - a má ń ní àwọn ìṣesí àwòrán wọn.

Ṣùgbọ́n ìdánimọ̀ tí a jogún yìí, kò dá lórí bí a ṣe rí nìkan, ó fẹ́ ẹ̀ ṣẹ́ sí gbogbo abala ayée wa, pẹ̀lú oun tí a gbàgbọ́ nípa ara wa.

Ara èké má ń fi akíyèsí sí àwọn irọ́ tí ọ̀tá ń jù sí wa. Àwọn irọ́ tó ń lé wa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run àti kúrò ní ìdí kádàráá wa.

Nígbatí a bá gba àwọn irọ́ tó ní àwa ò tó gbọ́, níṣe ni à ń dín kú lára ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìdánimọ̀ tí Ọlọ́run tira rẹ̀ fún wa - gẹ́gẹ́bí ẹni tí a fẹ́ láìníìdí àtí láìṣeàníàní.

Ọba àgbáyé dá ọ láti ní ìbáṣepọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Ní abẹ́ ẹ àṣẹ ńlá rẹ̀, a pe gbogbo wa láti yege nínú oore ìfẹ́ Ọlọ́run. Nínú èyí, àwa náà ní ipa láti ṣe ìtọ́jú tó jinlẹ̀ fún ọmọnìkejì wa gẹ́gẹ́ bíi ọmọ ẹgbẹ́ ìdílé ti ọ̀run kan náà.

Síbẹ̀, oun tí a bá ṣe pẹ̀lú ìṣe àtọ̀runyàn yìí kú sí wa lọ́wọ́ pátápátá.

Oun tí ó darí ìpinnu wa yóò dá l’órí ìbẹ̀rù wa àbí oun tí Ọlọ́run pè ní òtítọ́.

Ìríṣí:

Kini ǹkan náà ni ayé rẹ tó o ní láti jọ̀wọ́ fún Ọlọ́run kii ìwọ kò lè fi àwòrán rẹ̀ hàn dáadáa síi?.

Àdúrà:

Ọlọ́run, mo dúpẹ́ wípé ó dá mi láti nípa nínú ẹbíì rẹ. Ìwọ pè mí ní Tìrẹ, òun sì ni mo jẹ́. Jọ̀wọ́ fi àwọn ìbòjú tí mo ti yàn hàn mí tí kò bà òun ti ìwọ pè ní òtítọ́ mu. Àmín.

Nípa Ìpèsè yìí

Ara Èké

Ǹjẹ́ àwọn ìbẹ̀rùbojo ati àìláàbò ayéè rẹ ti tì ọ́ sínú ìdánimọ̀ tó ṣe àjèjì? Kíni ìwọ̀n ìyàtọ̀ tó wà ní àárín ẹni tí ìwọ jẹ́ ní òtítọ́ àti àwòrán rẹ tí o fi ń han àwọn míràn? Ní ìbásepọ̀ pẹ̀lú LUMO àti OneHope, àti tó dá lórí ìwàásù Àlùfáà Tyler Staton, ètò ọlọ́jọ́ méje yí yóò mú ẹ ṣe àyẹ̀wò òtítọ́ kodoro tó wà lẹ́yìn “ara èké.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ OneHope fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: www.lumoproject.com