Ara ÈkéÀpẹrẹ

Ẹ̀yà araà rẹ wo ló ń bà ọ́ lẹ́rù láti wo ní iwájú Ọlọ́run?
Ní àsìkò tí ó ṣe é ṣe wípé ojúlówó òtítọ́ jẹ́ ìwà tí a fẹ́ jùlọ, ó yani lẹ́nu láti ṣe àgbérò bí ìbòjú tí a ń wọ̀ ṣe pọ̀ tó. O lè lọ sí ẹnu isẹ́ kí o sì bo àwọn áléébù rẹ pẹ̀lú ìbòjú ìgboyà.
Bóyá ò ń lo ẹ̀gàn gẹ́gẹ́ bíi ìbòjú láti bo ìbẹ̀rù rẹ fún àṣìṣe.
Pelu agbègbè titun kọ̀ọ̀kan, a ń ṣe ẹ̀dá ìdánimọ̀ eke. A kò rí ara wa bí ẹni tó pé tó, torí náà a ń ṣe àlùpàyídà àwòrán Ọlọ́run tó wà nínú wa láti bárajọ pẹ̀lú àìní àsìkò.
Ṣùgbọ́n kí ló dé tí a fi má ń fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ìpele ìdánimọ̀ wa tí a ń fojú rí tí a sì ma ń ṣe ìgbàgbé ìpele ara wa tó jinlẹ̀ jùlọ? Kò lè rara: Ẹ̀rù ló ń bà wá.
Ìbẹ̀rù, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ òranyàn tó fẹ́ràn láti fi àwòrán ara ẹni tó bójúmu hàn, ló ń tì wá kúrò ní ẹni tí àwa jẹ́ ní tòótọ́. Èyí ló má a ń fa bíbí i ara èké. Ara èké yí ni ìdánimọ̀ tí a bí nínú olúkúlùkù wa nítorí ìbẹ̀rù láì i ṣe tí ìfẹ́.
Síbẹ̀síbẹ̀, àni nínú ìtàkùn àìdánilójú yìí, a kò wà ní aìnìí ìrètí. Bíbélì kọ́ wá wípé ìfẹ́ ni Ọlọ́run, àti wípé ìfẹ́ pípé a má a lè ìbẹ̀rù jáde.
Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ẹni tí a jẹ́ gangan, ẹni tó dá wa ní àwòrán ara rẹ̀. Ọrẹ ọ̀fẹ́ rẹ̀, nígbàtí a bá gbà á, ń nu òwúsúwusù kúròní ojú u wa tí n ṣe ìrẹ̀wẹ̀sì kí a lè bẹ̀rẹ̀ sí rí ara wa bí òun ṣe ń rí wa.
Ara èké ń sọ pé: “Mo ní láti ṣe àṣehàn.”
Ọlọ́run sọ pé: “Nínúù mi ni ìdánimọ̀ rẹ wà.”
Ara èké ń sọ pé : “Bẹ̀rùu ìtẹ́wọ́gbà àwọn ènìyàn.”
Ọlọ́run sọ pé: “Bẹ̀rù mi kí ó sì bọ̀wọ̀ fún mi.”
Ara èké ń sọ pé: “Aláìníláárí ni ẹ́.”
Ọlọ́run sọ pé: “Àyànfẹ́ mi lo jẹ́. “
Ìríṣí:
Báwo ni àlà tó wà láàárín ẹni tí ó ń fi hàn àwọn ènìyàn àti ẹni tí ó jẹ́ ni tòótọ́ ṣe fẹ̀ tó? Àwọn ìbẹ̀rù wo ló ń fi ìtara darí ẹni tí ò ń fihàn?
Àdúrà
Ọlọ́run, mo dúpẹ́ fún ifẹ rẹ aláínìdí. Fúnmi ní ojú inú láti rí àwọn apá kànkan ayéè mi ti ọ̀pọ̀ ẹ́rù ń bà mí láti dojúkọ. Lóní, mo yàn láti gbẹ́kẹ̀lé ọ nìkan. Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ǹjẹ́ àwọn ìbẹ̀rùbojo ati àìláàbò ayéè rẹ ti tì ọ́ sínú ìdánimọ̀ tó ṣe àjèjì? Kíni ìwọ̀n ìyàtọ̀ tó wà ní àárín ẹni tí ìwọ jẹ́ ní òtítọ́ àti àwòrán rẹ tí o fi ń han àwọn míràn? Ní ìbásepọ̀ pẹ̀lú LUMO àti OneHope, àti tó dá lórí ìwàásù Àlùfáà Tyler Staton, ètò ọlọ́jọ́ méje yí yóò mú ẹ ṣe àyẹ̀wò òtítọ́ kodoro tó wà lẹ́yìn “ara èké.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ OneHope fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: www.lumoproject.com









