Ara ÈkéÀpẹrẹ

F’ojú inú wòó pé o lè ti ọkàn rẹ bọ ẹ̀rọ kan tó fi ìjìnlẹ̀ èrò ọkàn, ìrètí àti ìbẹ̀rù rẹ hàn. Kò sí àṣírí kankan. Kò sí ìbòjú kankan. Ó jẹ́ ìwọ nìkan ní àdáyébá, ẹni tí o jẹ́ lóòótọ́.
Óṣeéṣe kó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìrántí kan tí o ti gbìyànjú láti pamọ́, bíi ìgbàtí inú rẹ ru sí ẹni tí o fẹ́ràn àbí ìgbàtí tí o pa irọ́ láti dáàbòbo òkìkí rẹ.
Bí a sì ṣe ríi ní Genesisi kẹ́ta, gbígba ìyànjú láti fi àwọn àléébù wa pamọ́ fún Ọlọ́run kii lọ bí a ṣe lérò. Rírí ìhòhò àti àìlágbára wọn, Ádámù àti Éfà fi èwe igi ọ̀pọ̀tọ̀ bo ara wọn. Wọ́n ṣe bí àwọn nílò láti pa ara wọn mọ́ kúrò lọ́dọ̀ Ẹni tó ní ìfẹ́ wọn jùlọ.
Ifè ni Ọlọ́run. Ìhìn rere nìyẹn pẹ̀lú òjìji biribiri. Ìhìn rere ni wípé àyànfẹ́ ni ọ́ nísìnsinyìí láìsí àlàyé àbí ìdíwọ́. A fẹ́ràn rẹ ní ọ̀nà tí o kò fi lè pàdánù. Òjìjí biribiri inú rẹ náà ríi wípé ìfẹ́ ṣòro láti gbàgbọ́ kódà ó lè gan láti gbẹ́kẹ̀lé. Gbogbo ìtàn rẹ há sí àárín ogun méjì wọ̀nyí.
A má ń sábà, láìtọ́, l’érò wípé ìfẹ́ Ọlọ́run dá lé agbára wa láti jẹ́ pípé. Nígbà tí àwọn èrò tí a kò fẹ́ bíi owú àbi ìfẹ́kùfẹ́ bá wọ ọkàn wa, a máa ń ja fitafita láti bò wọ́n mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ìbòjú ẹnití a jẹ́ àbí ìgbéraga.
Bí a ti wí nínú Romu 3:23, gbogbo ènìyàn ló ti ṣẹ̀, tí nwọ́n sì kùnà ìlànà pípé Ọlọ́run. Èyí ni ìdí tí Jésù ṣe wá - láti gba ọkàn wa là àti láti tún ayé wa ṣe padà sí bí Ọlọ́run ṣe dá a láìlábàwọ́n, tó kún fún ìfẹ́ àti oore ọ̀fẹ́.
Aò lè ṣiṣẹ́ gba ìfẹ́ Ọlọ́run, aò sì pilẹ̀ṣẹ̀ wa láti ṣe bẹ́ẹ̀. yẹ kó rí. Oun tí a lè ṣe, síbẹ̀, ní kí a jọ̀wọ́ ayé wa l’ódidi fún Ọlọ́run. Tí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a lè rí òmìnira àti ìyè nínú ìfẹ́ rẹ̀.
Ìríṣí:
Ẹ̀yà rẹ wò lọ ń bá ìléru láti fi hàn Ọlọ́run? Ǹjẹ́ o mọ bó ṣe rí láti gbé pẹ̀lú òmìnira nínú ìfẹ́ Ọlọ́run?
Adura:
Ọlọ́run, mo mọ̀ pé mo ń gbìyànjú láti fi ara mi pamọ́ fún ọ. Jọ̀wọ́ mú gbogbo àwọn àléébù , ẹ̀ṣẹ̀, àti àṣìṣe mi kúrò. Mo nígbàgbọ́ wípé ìwọ yóò gbà mí. Ìwọ kò ní fi mí sílẹ̀. Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ǹjẹ́ àwọn ìbẹ̀rùbojo ati àìláàbò ayéè rẹ ti tì ọ́ sínú ìdánimọ̀ tó ṣe àjèjì? Kíni ìwọ̀n ìyàtọ̀ tó wà ní àárín ẹni tí ìwọ jẹ́ ní òtítọ́ àti àwòrán rẹ tí o fi ń han àwọn míràn? Ní ìbásepọ̀ pẹ̀lú LUMO àti OneHope, àti tó dá lórí ìwàásù Àlùfáà Tyler Staton, ètò ọlọ́jọ́ méje yí yóò mú ẹ ṣe àyẹ̀wò òtítọ́ kodoro tó wà lẹ́yìn “ara èké.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ OneHope fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: www.lumoproject.com









