Ara ÈkéÀpẹrẹ

Ádámù àti Éfà ṣ’ọ̀tẹ̀ sì Ẹlẹ́dàá wọn, t'ori ìbẹ̀rù wípé Ó ń sẹ́ àwọn ní oun tó lè mú ayée wọn dára síi. Ó ṣe wọn nínú u wọn bíi pé ǹkan ku díẹ̀ káàtó, torí náà wọ́n wá ǹkan ṣe síi fún ra wọn.
Ronú s’ẹ́yìn sí ìgbà ọ̀dọ́ rẹ, tó ń jí àádùn míràn jẹ àbí tí ò ń lọ sí ibi tí wọn ò gbà ọ́ láàyè láti lọ. Kí ló mú ọ kọjá àwọn àlà wọ̀n yí?
Gbogbo ìlànà tí a ti rú wá láti ọwọ́ ẹni tó lérò wípé òun mọ̀ ju ẹni tó ṣe ìlànà náà lọ. Bíi alárìnkiri tó sọnù tó sì kọ̀ láti gbẹ́kẹ̀lé àwọn àmì ìtọ́sọ́nà tó wà l’ójú ọ̀nà ẹ̀, a má ń tan ara wa wípé a mọ oun to dára ju - tí àwọn tó jù wá lọ kùnà láti mọ̀.
Ojú àmì ìyípadà ti ìbàjẹ́ ayé yìí ṣíwájú ìgbà tí ènìyàn jẹ èso ẹ̀ṣẹ̀. Ìpilẹ̀ṣẹ̀ òjìji ara èké bẹ̀rẹ̀ nígbàtí Ádámù àti Éfà ṣe iyè méjì nípa oore Ọlọ́run. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n pàdánù ara wọn tòótọ́ jùlọ - tí a ṣe ní ìṣẹ̀dá àwòrán Ọlọ́run.
Èyí daríi wa sí ìbéèrè pàtàkì kan: Tí ara èké bá jẹ́ ìdánimọ̀ tí a bí làti inú ìbẹ̀rù, báwo ló ṣe má a rí tí a bá gbé ìgbé ayé tí ìfẹ́ ń darí - láti jẹ́ ara wa tòótọ́?
Láti mọ ẹni tí a dá wa láti jẹ́, a ní láti wo Ẹlẹ́ẹ̀dá wa fún ra rẹ̀.
Ìfẹ́ ni Ọlọ́run, gbogbo ẹni tí ó bá sì ngbe nínú ìfẹ́ ń gbé nínú Ọlọ́run, Ọlọ́run sì ń gbé nínú wọn. (1 Jòhánù 4:16b)
Àwòrán Ọlọ́run kìí kàn ń ṣe ǹkan tí a ní àbí tí a ń fihàn (bótilẹ̀jẹ́pé ó jẹ́ àwọn ǹkan wọ̀nyí); ìpè e wa ni - ìdí abájọ wa.
Nígbàtí ó bá yé wa bí ìfẹ́ Ọlọ́run sí wá ṣe tóbi tó, títẹ̀lée á di orísun ìyè àti òmìnira dípò o ìnira.
Ìríṣí:
Ǹjẹ́ ìfẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ nínú Ọlọ́run ń ṣe ìwúrí fún ọ láti gbọ́nràn síi l’ẹ́nu?
Àdúrà:
Ọlọ́run, nígbàtí ìmọtara ẹni bá bo ìdánimọ̀ mi lójú, ràn mí lọ́wọ́ láti rí ọ bí o ṣe jẹ́ nítòótọ́. Daríì mi nínú ìfẹ́ rẹ. Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ǹjẹ́ àwọn ìbẹ̀rùbojo ati àìláàbò ayéè rẹ ti tì ọ́ sínú ìdánimọ̀ tó ṣe àjèjì? Kíni ìwọ̀n ìyàtọ̀ tó wà ní àárín ẹni tí ìwọ jẹ́ ní òtítọ́ àti àwòrán rẹ tí o fi ń han àwọn míràn? Ní ìbásepọ̀ pẹ̀lú LUMO àti OneHope, àti tó dá lórí ìwàásù Àlùfáà Tyler Staton, ètò ọlọ́jọ́ méje yí yóò mú ẹ ṣe àyẹ̀wò òtítọ́ kodoro tó wà lẹ́yìn “ara èké.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ OneHope fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: www.lumoproject.com









