Ara ÈkéÀpẹrẹ

C.S. Lewis sọ pé: Kò sí bí ẹ̀ṣẹ̀ náà ṣe kéré tó, kòsí ìsòro níwọ̀n tí àkójọpọ̀ ipá wọn bá ń tí ènìyàn kúrò nínu ìmọ́lẹ̀ sí inú òfìfo.”
Ọ̀rọ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ ní èdè Gíríìkì, “hamartia,” túnmọ̀ sí ìpàdánù ojú àmì bi ọọlọ́fà tí kò tafà sójú àlà.” Ẹ̀ṣẹ̀ wá kii sábà jẹ́ ìmọ́mọ̀ṣe ọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìgbìyànjú to kùnà láti pèsè fún àwọn ìní wa. Ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀dá ti Ọlọ́run dé bi pé ó fẹ́ pá gbogbo ẹ̀dá énìyàn run nígbà ayé Noah.
Ó wù wá kí wọn fẹ́ wa, torí náà a ń lépa ìbáṣepọ̀ àláìmọ́ dípò ká sá si ọwọ́ Jésù. A ń fẹ́ ọ̀wọ̀, torí náà a ń tẹ àwọn ènìyàn lójú mọ́lẹ̀ dípò ìsinmi nínú ọ̀wọ̀ tó wà pẹ̀lú jíjẹ́ ọmọ Ọlọ́run.
Ara èké jẹ́ esi “hamartia” ti wa, àti àsìkò o pípàdánù ojú àmì wa. Èyí ni ìtumọ̀ ẹ̀ṣẹ̀: òun kò òun tí a bá sọ, ṣe, àbí rò, tí kò bá ọkàn àti ìfẹ́ inú Ọlọ́run lọ.
Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ a ti dá bíi ẹran ẹ̀gà tó ń yí àwọ̀ padà láti bá àyíká dọ́gba bí a ṣe ń di ẹrú sí ìfẹ́kúùfẹ́. À ń ta òmìnira ayérayé fún ìtẹ́lọ́rùn ìgbà dí ẹ̀.
Orin Dáfídì 103 sọ pé, “ó fi òun tó dára tẹ́ ìfẹ́ ọkàn mi lọ́rùn.” Ádámù àti Éfà yé gbàgbọ́ nínú èyí wọn sì dẹ́ṣẹ̀. Àwa náà yẹ gbagbọ nínú èyí a sì dẹ́ṣẹ̀. Bíi Ádámù àti Éfà, ẹ̀ṣẹ̀ wá ń yà wá kúrò lọdọ Ọlọ́run at iwájú rẹ̀.
Jésù wọlé, ẹni tí kò pàdánù ojú àmì ríí. Bótilẹ̀jẹ́pẹ́ a dán an wò ní gbogbo ọ̀nà, Jésù ó mikàn. Ìfẹ́ Ọlọ́run kárí ayé nípasẹ̀ ìrúbọ Ọmọ rẹ̀ tó yí ayé padà.
Ṣùgbọ́n ó kú sí wa lọ́wọ́ láti bọ́ ìbòjú wa sílẹ̀ ká sí gba ìfẹ́ rẹ̀. Àti nípasẹ̀ ìtọ́sọ́nà Ẹ̀mí rẹ̀, o lè “...jẹ́ kí Ọlọ́run yí ọ padà sí ẹni tuntun nípasẹ̀ yíyí ona ti o ń gba ronú padà.”
Ọkàn ni ojú ogun ẹ̀mí wà, ati lati lè rọ̀wọ̀ mú nínú ogun wa pelu ọ̀tá àní láti gba Ọlọ́run láyè láti ṣàtúnṣe ọkàn àti àyà wá. Ní ṣíṣe bẹ́ ẹ̀, a lè tún ojú wa gbé sì òun ti a dá wa lati ṣe: mímọ, nínífẹ̀ẹ́, àti sínsin Ọlọ́run.
Ìríṣí:
Báwo ló ṣe tí pàdánù ojú àmì? Àwọn ìní wo ló ń gbìyànjú láti bá dípò wíwá ìtẹ́lọ́rùn nínú Ọlọ́run? Àwọn èrò ati ìṣesí wo ló ń láti yí padà fún ọ láti padà s’ójú àlá?
Àdúrà:
Ọlọ́run, mo wá nínú ìjà fún ayé mi. Mo nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ. Fi àwọn ìrọ́ tí mo ń gbàgbọ́ hàn mí, kí ó sì dárí mi sí ìmọ́lẹ̀ ìfẹ́ rẹ̀. Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ǹjẹ́ àwọn ìbẹ̀rùbojo ati àìláàbò ayéè rẹ ti tì ọ́ sínú ìdánimọ̀ tó ṣe àjèjì? Kíni ìwọ̀n ìyàtọ̀ tó wà ní àárín ẹni tí ìwọ jẹ́ ní òtítọ́ àti àwòrán rẹ tí o fi ń han àwọn míràn? Ní ìbásepọ̀ pẹ̀lú LUMO àti OneHope, àti tó dá lórí ìwàásù Àlùfáà Tyler Staton, ètò ọlọ́jọ́ méje yí yóò mú ẹ ṣe àyẹ̀wò òtítọ́ kodoro tó wà lẹ́yìn “ara èké.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ OneHope fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: www.lumoproject.com









