ÀDÌTÚ ORIN ÌYÌNÀpẹrẹ

ỌJỌ́ KẸ́TA: ìyiìn jẹ́ okun
ṣé àwọn ìpèníjà ìgbésí ayé ti mú kí o rẹ̀wẹ̀sì débi pé o kò fi lèjà? Gẹ́gẹ́ bíi Gídióni , ẹ̀rù leè bà ọ́, ìrẹ̀wẹ̀sì tàbí ṣíṣe iyàméjì sí ìpè Ọlọ́run lórí ayé rẹ. Nígbà tí áńgẹ́lì Ọlọ́run fara han Gídíónì, Ó ń pèé ní ‘’alágbára ogun’’ Ìdáhùn tí Gídíóni fún-un fi bí ìdàmú ọkàn rẹ̀ ṣe pọ̀ tó hàn. Bí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú wa, èéṣe ti gbogbo ǹkan wọ̀nyi ṣe ń ṣẹlẹ̀ síwa? ‘’ (Àwọn onídajọ́ 6: 13) kìí ṣe pe Gídíónì ń ṣiyèméjì nípa agbára ara rẹ̀ nìkan, ó tún ń ṣiyèméjì nípa bóyá Ọlọ́run wa nínú ìgbésí ayé rẹ̀.
Síbẹ̀, Ọlọ́run Kò pa Gídíónì tì nínu ẹ̀rù rẹ̀, ó fi dáa lójú wípé, ‘’ lọ nínú agbára rẹ …Èmi kò ha rán ọ bí? ‘’ (Àwọn onídájọ́ 6: 14). Ọlọ́run bá Gídíónì níbi tí ó ti ń ṣe iyèméjì, ó sì rán-an léti wípé orísun agbára rẹ kìí ṣe ipò tí ó wà bíkòṣe ìwàláàyè Ọlọ́rum àtí ìlérí rẹ̀.
Nígbà tí Gídíóni kó àwọn ọmọ ísírẹ́lì lọ gbógunti àwọn ará mídíánì , ẹ̀rú sì ń bàá, ní pàtó, Ọlọ́run ti dín àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kù láti ẹ́gbẹẹgbẹ̀rún mẹ́wa sí ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùrin, kò dájú pé àwọn ọmọ ogun yìí leè ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá tó pọ̀ bí eeṣu.
Ṣùgbọ́n àdìtú ìyìn nìyí: Ọlọ́run kò nílò agbára púpọ̀. Ó kàn nílò ìgbọràn àti ìyìn. Nítorí náà: ó mu ki Gídíónì jade pẹ̀lu fèrè àti ìkòko. Ìyìn wọn àti ìgbọràn wọn jẹ́ oun ìjà tí Ọlọ́run lò láti tú wọn sílẹ.
Ìtàn yíì ránwalétí wípé, ìyin jẹ́ ìgbésẹ̀ agbára tó n polongo ìgbagbọ́ nínú ẹni tó ń jà fún wa. Bíi Gidíónì, kò dìgbà ta bá ní oun gbógbó ka tó yin Ọlọ́run. Nínú àìlera àti ìbẹ̀rù wa, Ìyìn lágbára tó láti fún wa ní aṣeyọrí.
Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ gbàgbọ́ pé agbára Ọlọ́run jẹ́ pípe nínú àìlera wa.
ÌRÌSÌ:
Àwọn ǹkan wo ló máa ń tojú sú ọ nínú ìgbésí ayé rẹ? Gbàgbọ́ wípé bí o ba
Yin olúwa, wa gba okun láti doju kọ àwọn ìṣòro náà.
ÀDÚRÀ:
Olúwa, mo dúpẹ pe o bámi pàdé nínu ìyèmejì àti ìfòyà mi, gẹ́gẹ́ bíi Gídíónì. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń lérò pé n kò jámọ́ nkankan tí n kò si leè dojúkọ ìpèníjà ayé. Ràn mí lọ́wọ́ lati gbàgbọ́ nínú okun rẹ, ki o sì jẹ́ kí ìyìn mi polongbo agbára àti òótọ nínu gbogbo ogun tí mò ń là kọjá.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn ohun ìjinlẹ ti Ìyin: Nínú ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ méje yìí, Dúnsìn Oyèkan ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn àdìtú inú orin ìyìn gẹ́gẹ́ bí ohun ìjà àwọn onígbàgbọ́. Bi o ṣe kàá, ìwé májẹ̀mú Láíláí àti Májẹ̀mú Titun sì yànnànáa rẹ̀. Gbìyànjú láti lo àwọn oun ìjà ti ẹ̀míi nì, ní àkókò ayọ ju àkókò ìpèníjà lọ.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Integrity Music fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: dunsinoyekan.com