ÀDÌTÚ ORIN ÌYÌNÀpẹrẹ

ỌJỌ́ KẸFÀ: Ìyìn jẹ́ ìdáni lójú
Bí a ṣe ń dàgbà nínú Ọlọ́run, ìyìn wa gbúdọ̀ máa pọ̀ si pẹ̀lú ìdánilóju, a kọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run ní kíkún, ìgboyà nínu òtítọ́ Rẹ̀. Kódà, kí a to ri ìmúṣẹ àwọn ìlérí rẹ, Eyí ni àditú inú orin ìyìn: ó jẹ́ ìdánilójú nípa ìwà àti iṣẹ́ Ọlọ́run. Saáju ìfarahàn ẹ̀rí.
Ní ibojì Lásárù, Jésù fi hàn wá ohun tí ó jẹ láti máa yin Ọlọ́run lọ́nà to fi hàn pé ọkàn wa balẹ̀. Ó ní ìbànújẹ́ gidigidi nítorí ikú ọ̀rẹ́ Rẹ̀àti ìbànújẹ́ tí ìfẹ́ tó ní sí Lásáru dùn-un gidigidi. Síbẹ̀, ní ojú ikú, Ó gbé ohùn rẹ̀ sókè láti yin Ọlọ́run, kò dúró kí Ọlọ́run jí lásárù kí ó tó yìn-Ín, Ó yìn-Ín, ní ìdánilójú wípé Bàbá máa n gbọ́ nígbàgbogbo a si ṣe é.
Jésù kéde, ‘’Baba, mo dúpẹ wípé o tí gbọ́ tèmi. Mo mọ̀ wípé o máa n gbọ́ tèmi ní gbogbo ìgbà,’’ Nítori náà, kín ni ìdí tí ó fi yin Ọlọ́run ni oùn gooro? Ó nílò láti fi ìdánilójú yìí hàn kí àwọn ènìyàn tí ó dúró nítòsí le è gbàgbọ́ nínú agbára Ọlọ́run àti òtítọ́ ti iṣẹ́ rẹ̀.
Íru ìdánilóju náà tí ó darí Jésì láti yin-In sì n bẹ síbẹ̀ fún wa, Bí a bá gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, níní ìgbẹkẹ̀lé nínu oore àti títóbi rẹ̀, Ìyìn ti di oun tí a gbọ́dọ̀ máa ṣe nígbàgbogbo. Ó ń kéde pé a gbàgbọ́ nínú ìléri Rẹ, kódà tí iṣòro náà bá dàbí ẹni pe ọ̀nà àbáyọ kò si, ó n kédé pé Ọlọ́run nífẹ wa ati pé òun ló rán wa’
Kín ni ò ń là kọjá ti o nílo ìdánilójú yìí? Bí o bá ṣe n dúpẹ fún ohun tí Ọlọ́run n ṣe, kóda, kí ó tó fara hàn .
Ìyìn rẹ di ìgbésẹ̀ ìgbàgbọ́ láti mú kí ọkàn rẹ bà ìfẹ́ Rẹ mu, àti lati kéde fún àwọn èniyan pé Ọlọ́run ló rán ọ.
ÌRÍSÍ:
Iru ìléríwo lò n gbàgbọ́ wipé kí Ọlọ́run mú ṣẹ? Lo àkókò kan láti fi ìdànilójú rẹ hàn nípa fífi ìyìn fún-Un lónìí.
ÀDÚRÀ:
Baba, mo dúpẹ́ pe ò ń gbọ́ temi, kọ́ mi láti yìn Ọ́ pẹ̀lu ìdánilójú àti ìgbẹ́kẹ̀le, kí n sì gbà ọ́ gbọ́ kí èsì àdúrà mi to dé. Kí ìyìn mi kí ó jẹ́ ẹ̀rí fún ẹlòmíràn gẹ́gẹ́ bíi oore rẹ ti kìí kùnà.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn ohun ìjinlẹ ti Ìyin: Nínú ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ méje yìí, Dúnsìn Oyèkan ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn àdìtú inú orin ìyìn gẹ́gẹ́ bí ohun ìjà àwọn onígbàgbọ́. Bi o ṣe kàá, ìwé májẹ̀mú Láíláí àti Májẹ̀mú Titun sì yànnànáa rẹ̀. Gbìyànjú láti lo àwọn oun ìjà ti ẹ̀míi nì, ní àkókò ayọ ju àkókò ìpèníjà lọ.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Integrity Music fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: dunsinoyekan.com