ÀDÌTÚ ORIN ÌYÌNÀpẹrẹ

ỌJỌ́ KEJÌ: Ìyìn jẹ́ àìlábàwọ́n
Ọ̀kan lára àwọn àṣìṣe tí onígbàgbọ́ lè ṣe ni láti lérò pé ìyìn tọ́ sí Ọlọ́run nígba ti gbogbo ǹkan bá ń dára. Ìyìn wa gbọ́dọ̀ dá lórí oun ti à ń là kọjátàbí ìmọ̀lára àtinúwá. Méjeeji leè yípadà, dípo bẹ́ẹ̀, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ oun ìgbàdéigbà, Ọlọ́run wa àìyípadà ní , ó jẹ́ olóòótọ títíláé.
A rí àpẹẹrẹ eyí lára Paulu àti Sílà,fojú inú wo bí òru ọgbà ẹ̀wọn kan ṣe dákẹ́ rọ́rọ́, tí àwọn orin ìyìn ń dun , ta ni yóò kọrin ní irú ibi àìnírètí bẹ́ẹ̀, ta ni yóò máa kọrin ìyìn ní ihámọ́ ìgbèkùn?Bí ó tilẹ̀ jẹ́pé, gbogbo ara wọn ni wọn dè ní èwọ̀n, Paulu àti Síla mọ̀ pé kò sí ẹni tó leè dí ẹ̀mi wọn lọ́wọ́, nítorí náà , wọ́n sin Ọlọ́run pẹ̀lú ìgboyà, pẹ̀lí oùn rara, débi pé àwọn to wà ni ayíká wọn ṣe àkíyèsí.
Bí ètè wọn ṣe ń polongo dídára Ọlọ́run, Ọlọ́run fi ara rẹ̀ hàn nínú ipò tí wọ́n wà, Ọ̀kan lára àwọn àṣírí ìyìn ni pé ó n mú àwọn ipò tàbí èrò ti ara bá ipò ti ẹ̀mí mu, oun tí a rí ní ìbámu pẹ̀lú oun tí a kò rí, ó kéde pé Ọlọ́run ni ọba aláṣẹ lóríi gbogbo ẹ̀dá. Pipe agbára rẹ̀ láti yí gbogbo àìṣedéédé wa padà. Nítorí náà, nígbàkugbà tí
O bá wà nínú ìṣoro, ìrora, tàbí ìdèkídè, gbé ìyin àìlábàwọ́n sí Ọlọ́run, fi ẹ̀mí rẹ fún òtítọ́ oore rẹ̀.
ÌRÍSÍ:
Àwọn ẹ̀wọ̀n wo? —Bóyá ti ìbẹ̀rù, ìyèméjì tàbí ìbànújẹ́ ló n fà ọ́ sẹ́yìn? Lo ìyìn láti polongo òmìnira rẹ nínu Kristi.
ÀDÚRÀ:
Olúwa, ránmilétí pé àwọn ìdè mi ti já nínú Jésu Kristi. Jẹ́ ki ìyìn mi , jẹ́ kí ìyìn mí gòkè bíi ti Paulu àti Síla, ìgboyà, àìlábàwọ́n ati àìnídènà, polongo oore rẹ níbikíbi tí mo bá wà. Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn ohun ìjinlẹ ti Ìyin: Nínú ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ méje yìí, Dúnsìn Oyèkan ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn àdìtú inú orin ìyìn gẹ́gẹ́ bí ohun ìjà àwọn onígbàgbọ́. Bi o ṣe kàá, ìwé májẹ̀mú Láíláí àti Májẹ̀mú Titun sì yànnànáa rẹ̀. Gbìyànjú láti lo àwọn oun ìjà ti ẹ̀míi nì, ní àkókò ayọ ju àkókò ìpèníjà lọ.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Integrity Music fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: dunsinoyekan.com