ÀDÌTÚ ORIN ÌYÌNÀpẹrẹ

ỌJỌ́ KÉJE: Ìyìn jẹ́ oun ìja
Ní ikàdii àwọn àdìtú inu orin ìyìn: Mo fẹ́ ṣe àfihàn òtítọ́ tó ga jùlọ: Ìyìn jẹ́ oun ìjà, lójú àwọn ìṣòro tí ó le koko, nínú ooru ti ẹ̀rù, nínú ìdùnnú ìṣẹ́gun. Jẹ́ ki ìyìn jẹ oun ìja rẹ.
Nígbà tí àwọn ọmọ ogun alágbára ti Moabu, Amoni ati Òkè Seiri wá láti bá Júda jagun. Ẹ̀ru ń ba Jehoṣafati. Ṣùgbọ́n, dípo kí o jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún ẹ̀rù, ó wá ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run nínú ààwẹ̀ àti àdúrà, kedere ni ìdáhun Ọlọ́run, ẹ máṣe bẹ̀rù tàbi kí ẹ fòyà nítori àwọn ọmọ ogunńlá wọ̀nyí. Ogun náà kìí ṣe tiyin, bíkò ṣe ti Ọlọ́run. ( kronika keji 20:15)
Ní ìdáhùn si ìdánilójú àtòkè wá yì: Jehoṣafati yan àwọn akọrin àti àwọn olùjọ́sin láti ṣaájú àwọn ọmọ ogun. Bí wọn ti n yan lọ sí ojú ogun, oun ìjà wọn ni agbára ìyin wọn. Kìí ṣe agbára àwọn ológun wọn.
Wọ́n kọrin, ´´ Ẹ fi ìyin fún Olúwà, nítorí ifẹ́ rẹ́ dúró títí láe,’’ bí wọ́n ṣe ń ṣe èyí, Ọlọ́run rán àwọn ọmọ ogun láti pa ọ̀tá wọn, ó sì mú kí wọn máa bá ara wọn ja.Àwọn aráa Júda gba ìṣẹ́gun wọn, wọ́n ko ìkógun láì gbé idà sókè. Ní tòótọ́ Ọlọ́run ti já fún wọn ńipa lílo oun ìjà ńla ti iyin.
Ìgbàgbọ máa n mu ki ìdààmú bá ọ̀tá, nítorípé ó ń wá lati inú igbàgbọ́, kìí ṣe ìbẹ̀rù, ó máa ń polongo ìṣẹ́gun kí wọn to ṣẹ́gun ogun náà. Àdìtú orin ìyin gẹ́gẹ́ bíi oun ìjà ´ó si jọ̀wọ́ ara wa fún ìfọwọ́kàn rẹ.
ÌRÍSÍ:
Iru ogun wo lò ń doju kọ? Gẹ́gẹ́ bi i Jehoṣafati , yan orin gẹ̀gẹ̀ bii aṣáájú oun ìja rẹ, kéde àṣeyọrí rẹ lóri gbogbo ogun. Mo jọ̀wọ́ ogun mi fún Ọ, mọ̀ dájú wípé OÓ jà fún mi. Amin
ÀDÚRÀ:
Oluwa, mo dúpẹ́ fun ìdánilójú wípé ogun mi tìrẹ ni, jẹ́ ki ìyin mi jẹ oun ìja mi, kéde agbára àti àṣeyọrí lóri gbogbo ogun, mo jọ̀wọ̀ gbogbo wàhálà mi fún ọ, mọ̀ dájú wípé oó jà fúnmi.
Mo nírètí wípé àwọn àdítú inú orin ìyìn ti ìfọkànsìn yi yóò tọ́ọ sọ́nà sí ìyìn tó jilẹ̀ tó sì níye lóri sí Olúwa wa.
Ẹ tẹ́tí sí orin tuntun Dunsin Oyekan. Juda, Nibi.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn ohun ìjinlẹ ti Ìyin: Nínú ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ méje yìí, Dúnsìn Oyèkan ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn àdìtú inú orin ìyìn gẹ́gẹ́ bí ohun ìjà àwọn onígbàgbọ́. Bi o ṣe kàá, ìwé májẹ̀mú Láíláí àti Májẹ̀mú Titun sì yànnànáa rẹ̀. Gbìyànjú láti lo àwọn oun ìjà ti ẹ̀míi nì, ní àkókò ayọ ju àkókò ìpèníjà lọ.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Integrity Music fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: dunsinoyekan.com