ÀDÌTÚ ORIN ÌYÌNÀpẹrẹ

ỌJỌ́ KẸ́RIN: ìyìn nínú ìmúṣẹ
A mọ Joánù onítẹ̀bọmi gẹ́gẹ́ bíi aṣáájú Krístí, àti nítòótọ́ , àwọn nǹkan ìyanu wo ló wáyé nígbà tí wọ́n bí ọmọ náà, ìyẹn àlùfáà tí Èlísabẹ́ẹ̀tì bí fun Sekariah . Fún ọ̀pọ̀ ọdún, tọkọtaya olùfọkànsìn yi ń gbàdúrà fún ọmọ, wọ̀n ń jìjàdu nígbà gbogbo pẹ̀lú ìrora dídúró tí wọ́n sì n sọ̀rọ̀ tí kò ṣeé ṣe bí wọ́n ṣe ń dàgbà. Nígbà tí áńgẹ́lì olúwa farahanSekariah . Ó polongo pé yóò bí ọmọ ọkùnrin, Sekariah ṣe iyèmejì. Àìgbàgbọ́ rẹ̀ kò dí ètò Ọlọ́run lọ́wọ̀, sùgbọ́n o fi sílẹ̀ fúngbà diẹ̀ láì leè sọ̀rọ̀—ní àkókò ìdákẹ́ rẹ̀ ni ìlérí ọlọ́run jẹyọ ní ẹ̀mí àti nì ara.
Níkẹyìn ọjọ́ ìmúṣẹ dé nípasẹ ìbí Jòánù. Ní àkókò ìsọmọlórúkọ , ahọn Sekariah tú, oun ti ó kọ́kọ́ ṣe ni ó yin olúwa, ìpolongo rẹ̀ nípa oore rẹ̀ mú kí ìbẹ̀ru gbilẹ̀ láwùjọ wọn, ó ṣaájú àwọn ènìyàn láti polongo oun ti Ọlọ́run ṣe. Nígbà tí a bá n yọ ayọ̀ ìdùnnú, ó leè jẹ́ ìdánwò fúnwa láti gbàgbé orísun ayọ̀ náà, a leè rò wípé àwọn ìṣe wa ló fàá, àdúrà wa ìgbà dé ìgbà tàbi sùúrú.Sekariah rán wa létí pé kí a máa fi ẹ̀hónú wa hàn nípa fífi ìyìn fún Ọlọ́run ní àkókò ìmúṣẹ.
Àdítí inú orin ìyìn ni pé ó ń gbé Ọlọ́run ga, ó si n mú àwọn ènìyàn súnmọ́ọ. Nígbà tí a bá yin ọlọ́run ní gbangba fún ìlérí ìmúṣẹ rẹ̀ ní ayé wa, ó ń gbin èso ìgbàgbọ́ fún àwọn tí ó wà níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bii Sekariah. Jẹ́ kí ìyìn rẹ́ kí ó tàn – kìí ṣe ní ìkọ̀kọ̀ nìkan, ní ọ̀nà tí ẹnu yóò fi ya ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyan fún dídára Ọlọ́run àti agbára rẹ̀.
ÌRÍSÍ:
Ìlérí wo ni Ọlọ́run múṣẹ nínú ayé rẹ láìpẹ́ tàbí tẹ́lẹ̀ rí? Báwo ni o ṣe leè polongo ìyìn rẹ fún ìbùkún yì? báwo lo ṣe leè yin Ọlọ́run fún àwọn ìbùkún yìí lọ́nà tí yóò jẹ́ kí àwọn mìíràn mọ Ọlọ́run.
ÀDÚRÀ:
Olúwa, mo dúpẹ́ fún òtítọ́ rẹ nínú ayé mi. Kódà tí mo bá ń ṣiyèméji. O jẹ́ olóòótọ́ síàwọn ìlérí rẹ. Ràn mí lọ́wọ́ láti dá àwọn ẹ̀bùn tí o fún mi mọ̀ àtipé kí ìyìn mi kí ó máa dá ògo padà fún ọ ní gbogbo ìgbà,kí àwọn mìíràn si ní igbẹkẹ̀lé nínú rẹ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn ohun ìjinlẹ ti Ìyin: Nínú ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ méje yìí, Dúnsìn Oyèkan ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn àdìtú inú orin ìyìn gẹ́gẹ́ bí ohun ìjà àwọn onígbàgbọ́. Bi o ṣe kàá, ìwé májẹ̀mú Láíláí àti Májẹ̀mú Titun sì yànnànáa rẹ̀. Gbìyànjú láti lo àwọn oun ìjà ti ẹ̀míi nì, ní àkókò ayọ ju àkókò ìpèníjà lọ.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Integrity Music fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: dunsinoyekan.com