ÀDÌTÚ ORIN ÌYÌNÀpẹrẹ

ỌJỌ́ KARÙN-ÚN: Ẹ̀mí ni ìyìn
Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i ní àwọn ọjọ́ tó kọjá, ìyìn kò so mọ àwọn ipò wa, bí ǹka ṣe rì lára wa tàbí ibi tágbára wa mọ. Ìyìn jẹ́ nípa gbígbé orúkọ Ọlọ́run ga. Sùgbọ́n báwo ni a ṣe leè yìn-ín bí ó tí wùú, ṣé nípasẹ̀ àwọn orin tí a kọ láìnídìí ni tàbi sísọ àkọ́sórí?
Nígbà tí krísítì n bá obìnrin aráa Samáríà sọ̀rọ̀ ni eti kàǹga, ó rú àwọn òfin àti ìlànà àwùjọ láti rí òtítọ́ tó jinlẹ̀, Ẹ̀mi ni Ọlọ́run, àwọn tó n yìnín gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀mí àti ní òtítọ́. Níní ìjínròrò tó rọrùn yìí tó sì ní ipa tó lágbára, Jesu yi àfojúsun Rẹ̀ lati ìta sí àṣà ìbílẹ̀, agbègbè, ìbọ̀rìṣà àti ìrisi, si òtítọ́ inú àti àjọṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run.
Láti yin Ọlọ́run ni tòótọ́:
A gbọ́dọ̀ mọ ẹni ti a yìn: Bàbá kan ṣoṣo ti ó jẹ olódodo, ọmọ àti ẹ̀mí mimọ́
( Jòhánì 17: 3).
A tún gbọ́dọ̀ mọ ìdí ti a fi ń yìn-ín, nítori oore rẹ̀ àti ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀.(Orin Dáfídì 100:5).Agbọ́dọ̀ mọ ìgbà ti a ní láti yìnín: Ní gbogbo ìgbà, Ní ipò kípo (Orin Dáfídì 34:1)
ṣùgbọ́n, ìjiroro ti kristi ni pẹ̀lú obìnrin aráa Samáríà dá lórí i ọ̀nà ìyìn.
Ìyìn ń sànláti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mi ti o sopọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run wa ti ó jẹ ẹ̀mí, àti ọkàn ti ó fìdí múlẹ̀ nínu òtitọ́ àti ọ̀rọ̀ rẹ̀, kìí ṣe nípa kíka àwọn àkọ́sórí nìkan tàbí nípa àwọn iṣẹ́ ìtagbangba: Ó jẹ́ nípa ìbáṣepọ̀ tòótọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Láti yìn-ín nínú ẹ̀mí, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ kí ó darí wa, ki ó kọ́wa ní oun gbogbo ki ó si ro ìyìn wa ní agbára
(Jòhánù 14: 26). Láti yìn-ín ní tóótọ̀, a gbọ́dọ̀ mú ọkàn wa ró nínú òye ọ̀rọ̀ rẹ,gbà wípé òun ni ọba aláṣẹ, ayérayé àti dídára.
Ìyìn jẹ́ ìdúró ní ẹ̀mí àti ọkàn. A dúpẹ́, àpẹẹrẹ ti Krísti fi lelẹ fun wa ni èyí, tó ń fi bí a ṣe leè ní àjọṣepọ̀ tó dára pẹ̀lú Bàbá wa hàn.
ÌRÍSÌ:
ki ni ìyìn rẹ fi hàn lónìí ? Ṣe bárakú ni tàbi ó ń wá láti inú ìsopọ̀ ti o kún fún ẹ̀mi Ọlọ́run alààyè?
ÀDÚRÀ:
Olúwa, mo dúpẹ́ pé o pèmí láti yìn ọ́ nínú ẹ̀mí àti ní tòótọ́. Kọ́ mi nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ rẹ láti yìn ọ́ pẹ̀lú ọkàn àti ẹ̀mi tó gbé ọ ga ní tòótọ́. Ràn mí lọ́wọ́ láti mọ̀ ọ́ dáradára àti láti máa fi òtítọ́ rẹ hàn nínú oun gbogbo tí mo bá n ṣe.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn ohun ìjinlẹ ti Ìyin: Nínú ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ méje yìí, Dúnsìn Oyèkan ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn àdìtú inú orin ìyìn gẹ́gẹ́ bí ohun ìjà àwọn onígbàgbọ́. Bi o ṣe kàá, ìwé májẹ̀mú Láíláí àti Májẹ̀mú Titun sì yànnànáa rẹ̀. Gbìyànjú láti lo àwọn oun ìjà ti ẹ̀míi nì, ní àkókò ayọ ju àkókò ìpèníjà lọ.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Integrity Music fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: dunsinoyekan.com