A. Oni 7:17-22

A. Oni 7:17-22 YBCV

On si wi fun wọn pe, Ẹ wò mi, ki ẹnyin ki o si ṣe bẹ̃ gẹgẹ: si kiyesi i, nigbati mo ba dé opin ibudó na, yio si ṣe bi emi ba ti ṣe, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o ṣe. Nigbati mo ba fun ìpe, emi ati gbogbo awọn ti mbẹ lọdọ mi, nigbana ni ki ẹnyin pẹlu ki o fun ìpe yiká gbogbo ibudó na, ki ẹnyin ki o si wi pe, Fun OLUWA, ati fun Gideoni. Bẹ̃ni Gideoni, ati ọgọrun ọkunrin ti mbẹ lọdọ rẹ̀, wá si opin ibudó, ni ibẹ̀rẹ iṣọ́ ãrin, nigbati nwọn ṣẹṣẹ yàn iṣọ́ sode: nwọn fun ipè, nwọn si fọ́ ìṣa ti o wà li ọwọ́ wọn. Ẹgbẹ mẹtẹta na si fun ipè wọn, nwọn si fọ́ ìṣa wọn, nwọn si mú awọn òtufu li ọwọ́ òsi wọn, ati ipè li ọwọ́ ọtún lati fun: nwọn si kigbe li ohùn rara pe, Idà OLUWA, ati ti Gideoni. Olukuluku ọkunrin si duro ni ipò rẹ̀ yi ibudó na ká: gbogbo ogun na si sure, nwọn si kigbe, nwọn si sá. Awọn ọkunrin na fun ọdunrun ipè, OLUWA si yí idà olukuluku si ẹnikeji rẹ̀, ati si gbogbo ogun na: ogun na si sá titi dé Beti-ṣita ni ìha Serera, dé àgbegbe Abeli-mehola, leti Tabati.