Rúùtù: Ìtàn Ìràpadà ìfẹ́ Ọlọ́runÀpẹrẹ

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìtàn aládùn a máà parí pẹ̀lú, "Nwọn si gbé ní ìdùnnú lẹhin náà". Tí Rúùtù kò rí bayi. Ìtàn eléyìí kọjá "ìdùnnú lẹhin náà" sì ìran Kristi. Ẹsẹ mẹ́fà tí ó gbẹ̀hìn nínú ìwé Rúùtù ni ó ṣe pàtàkì nínú ìwé náà nítorí pé wọ́n fi hàn wá gbàngba, lẹ̀ẹ̀kàn sì bí Ọlọ́run ṣe ń mú gbogbo nǹkan ṣíṣẹ́ pọ fún rere fún àwọn tí ó fẹ́ràn Rẹ̀. (Romu 8:28) Láti ibẹrẹ de òpin ìwé Rúùtù yí, a rí bí Ọlọ́run ṣe ṣe àgbékalẹ̀ ìgbésí ayé ènìyàn láti mú ètò Rẹ̀ wá sí ìmúṣẹ. Àwọn ẹsẹ ìparí náà ṣe àfihàn bí a ṣe rí ìfẹ́ Ọlọ́run pípé gba láì fiṣe àbùkù àwọn ìpinnu wá àti ìkọ̀sẹ̀ nípasẹ̀ ìgbésí ayé wa
A wà nínú ìfẹ́ Ọlọ́run pípé ṣùgbọ́n kò dá lórí wa nìkan. Nínú ìwé rẹ̀Ọlọ́run Olòótọ́: Àtúpalẹ̀ Ìwé Rúùtù, Sinclair Ferguson sọ wípé, "Ìjìnlẹ̀ ohun tí Ọlọ́run ń ṣe tó làpẹẹrẹ tayọ ìgbé ayé àringbùngbùn ìwà rẹ". Àpapọ̀ àwọn tí ó gbagbọ sisẹ́ fún ìdí tí ó ga ju ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé wọn lójoòjumọ̀. Èyí jẹ ẹri nípasẹ̀ òtítọ́ pé ìwé náà jẹ àwọn iṣesí ẹni mẹ́ta ti o rọ sinu iranti ni awọn ẹsẹ mẹ́fà ti o kẹhin, nitori tí wọn kii ṣe ìtàn àkọ́kọ́. Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn iṣesí náà kò apá kan gbogi nínú ìtàn ìgbàlà. Ìfẹ́-inú rere tí Rúùtù àti Bóásì fi hàn yí ni ó ṣe okùnfà bí ìgbàlà ṣe tán káàkiri àgbáyé
Ó han kedere láti inu awọn ẹsẹ diẹ ti o kẹhin nínú iwe Rúùtù pe idi ti o dara julọ tí Ọlọ́run ṣe mú ohun gbogbo tí ó wà nínú ìtàn yí ṣẹlẹ̀ ni láti mú àṣeyọrí bá idi kan pato: ibi Jesu Kristi. Èyí kan Náómì bí ó ṣe lọ sí Móábù, bí Rúùtù ṣe yàgàn ni ìbẹ̀rẹ̀, ikú ọkọ Náómì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, bí Rúùtù ṣe ń ṣe àkójọ lẹhin ìkórè ni oko Bóásì, ètò ẹlẹgẹ́ Náómì (tí ó ṣiṣẹ́), ìkọ̀sílẹ̀ ìbátan-olurapada yòókù, àti bíbí Obed láti ipasẹ̀ Bóásì ati Rúùtù.
Jẹ́nẹ́sìsì 3:15 tí ó gbajúgbajà gẹ́gẹ́bíi àkọ́sọ-ìhìnrere nítorípé òhun ni (proto) ìkéde ìhìnrere àkọ́kọ́ (euangelion). Ọlọ́run ṣèlérí láti bá Sátánì ja nípa irú-ọmọ Éfà. Nígbà tí Ọlọ́run tọ́ka sí àwọn ọmọ Éfà, Ó túmọ̀ sí Jésù Kristi, Ọmọkùnrin rẹ̀ kan ṣoṣo, ẹni tí ó sẹ́gun Sátánì nígbà tí Ó kú lórí àgbélébùú. Nínú Àkòrí mẹ́ta péré sínú Bíbélì, ní ẹsẹ yìí gbé ìtàn Jésù kalẹ̀, èyí tó ń tẹ́ síwájú nípasẹ̀ Rúùtù àti ìyókù Ìwé Mímọ́. Ìlérí Jẹ́nẹ́sísì 3:15 wá sí ìmúṣẹ nítorí ìpèsè ọba aláṣẹ Ọlọ́run nínú ìdílé kékeré kan, tí ó dà bí ẹni pé kò ní láárí ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.
Àwọn ìtàn ìran-di-rán wọ̀nyí gbé ìtàn -àkọọ́lẹ Rúùtù ga lati ìtàn-akọọlẹ ilu kekere kan si ọkan tí ó di pataki ti orilẹ-ede ati ayeraye. Ní àkókò Awọn Onídajọ́ nígbàtí ojú dúdú, a ti fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fun ìran ti Olugbala, Ẹni-àmì-Òróró, ati Olurapada ẹda eniyan ti o sọnu ati alaini yíò gbé tí wá. Irúgbìn obìnrin náà ní a ó ṣe àfihàn rẹ nípasẹ̀ Bóásì àti Rúùtù, Dáfídì àti Batṣeba, àti Jósẹ́fù àti Màríà pẹ̀lú. Ní Orin Dáfídì 132:12, Ọlọ́run ṣèlérí fún ọ̀kan lára àwọn ọmọ Dáfídì, ọ̀kan pàápàá èyí tí ó tóbi ju Dáfídì lọ, yíò jọba títí láé. Nitootọ, Ọlọ́run ṣiṣẹ ohun gbogbo papọ̀ ni awọn ọgọọ̀gọ̀rún ọdún fún ire ti o ga jùlọ ti O ni sì ipamọ fun awọn ti o gbẹkẹ le.
Ní ìpìlẹ̀ ìtàn Rúùtù ni a ti rí awọn otitọ ẹkọ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pataki mẹrin kọ́
1. Ìpèsè Ọlọ́run jẹ́ nǹkan tí a lè gbàrà lè. A le ma ni anfani nígbà gbogbo lati ri tabi loye awọn ohun ti Ọlọrun yíò ṣe, ṣugbọn a ni idaniloju pe iṣakoso wá ní ìkáwọ́ Rẹ̀ ati pe Oun kí yíò kọ awọn ọmọ Rẹ silẹ.
2. A ni lati fi ifẹ inu-rere han si awọn ẹlomiran bi Ọlọrun ti fihan sì wa.
3. Ọlọ́run a máà dáhùn àdúrà àwọn ènìyàn Rẹ̀, àwọn ìbùkún Rẹ̀ sì gbòòrò láti ojú ìwòye ìwọ̀nba diẹ ti ìgbésí ayé wa títí dé ìran tí ń bọ̀ wá.
4. A nilo Ibatan-Olurapada kan ti o nifẹ wa tó bẹ́ẹ̀ ti O ku lati mu wa pada si ọdọ Ọlọrun. Ko si eniti kò ni ore-ọfẹ Ọlọ́run, ati pe “àwọn tí ó kéré ju” – àwọn ẹ̀lẹ́ṣẹ́, Awọn Keferi, ati awọn atako awujọ – ni a tun n rà pada.
Nípa Ìpèsè yìí

Bóyá ọ̀kan l'ára àwọn ìtàn kúkúrú tí ó wunilori jù lọ, ní ìwé Rúùtù tí ó jẹ́ àkọsílẹ̀ ti ìràpadà ìfẹ́ Ọlọ́run. Iwe Rúùtù jẹ́ ìtàn tí ó yanilẹ́nu bí Ọlọ́run ṣe nlo ìgbésí ayé àwọn ènìyàn lásán láti ṣe iṣẹ́ ìfẹ́ Òun ti o jé Ọba Aláṣẹ. Pẹ̀lú àwọn àkàwé tí ó rẹwà ti ìfẹ́ àti ìrúbọ Krístì fún àwọn ènìyàn Rẹ, a fi hàn wá ipele tí Ọlọ́run lọ láti ra àwọn ọmọ Rẹ̀ padà.
More