Rúùtù: Ìtàn Ìràpadà ìfẹ́ Ọlọ́runÀpẹrẹ

ìbátan-olùtúnnirà jẹ́ ìbátan tímọ́tímọ́ kan tó lọ fẹ́ opó kan kó lè bí ajogún fún ẹni tó kú náà. O dà bí ohun tó ṣàjèjì lójú àwa èèyàn òde òní, àmọ́ ọ̀nà míì tí Ọlọ́run gbà bójú tó àwọn opó àtàwọn ọmọ òrukàn nílẹ̀ Ísírẹ́lì nìyẹn. Gẹ́gẹ́ bí ìbátan tímọ́tímọ́ fún Élímálékì, o seé ṣe ki Bóásì jẹ́ olùtúnnirà fún Rúùtù. Àmọ́, nígbà tí wọ́n parí kíkórè ọkà báálì àti àlìkámà, Bóásì kò tíì ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùtúnnirà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti tó àkókò láti pa ọkà náà, Bóásì ò tíì ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀. Bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn ìyá ọkọ tó máa ń dá sí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ wọn, Náómì pinnu pé òun á túbọ̀ máa fúngun mọ́ Bóásì.
Náómì sọ fún Rúùtù pé kó lọ wẹ ara rẹ̀, kó da òróró oloorun dídùn sára, kó sì wọ aṣọ tó dáa. Ohun tí Náómì ń sọ fún un ni pé kó má ṣe múra bí ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, kó máa múra bí ẹni tó ti pa dà sí ìgbé ayé rẹ̀. Ó sọ fún Rúùtù pé kó lọ bá Bóásì níbi ìpakà, kó tú aṣọ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀, kó sì lọ dùbúlẹ̀. Ó wá sọ fún Rúùtù pé kó dúró dìgbà tí Bóásì ba sun mo.Náómì sọ fún Rúùtù pé kó lọ síbi kan lálẹ́níbi tí kò ye ki obìnrin èyíkéyìí lọ láti pàdé ọkùnrin tí kò tíì laya. Bí Rúùtù ṣe fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ohun tí Náómì so yìí fi hàn pé ńṣe ló ń fi ara rẹ̀ wewu. Kí ló yẹ kí Bóásì rò nígbà tó rí ọ̀dọ́bìnrin tó mọ́ tónítóní, tó lo ororo oloorun dídun, tó sì múra dáadáa yìí tó gun orí ibùsùnw rẹ̀ ní ọ̀gànjọ́ òru? Ó dájú pé ó máa ní èrò tí kò tọ́. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tí Náómì ní lọ́kàn nìyẹn. Rúùtù sì ṣègbọràn sí i. Ó dà bíi pé àìráragba-nǹkan-sí Ọlọ́run ló mú kí Náómì gba Rúùtù nímọ̀ràn, ó sì jọ pé ìwà òmùgọ̀ tó mú kí ìdílé Náómì kó lọ sí Móábù náà ló fà á.
.Tá a bá wo ọ̀rọ̀ yìí látòkèdélẹ̀, a óò rí i pé àkókò tí Ọlọ́run yàn pé kí nǹkan ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ ló máa ń rí. A lè di aláìnísùúrù sí àkókò tí Ọlọ́run yàn kalẹ̀, ká sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì nípa ìṣòtítọ́ Rẹ̀. A sábà máa ń fe ki Olórun fi ìkánjú se nǹkan nígbà Tó bá ń ṣe ìfé Rẹ̀ gégé bi ọba aláṣẹ. Bóyá a ò lè ṣe to ti Náómì àti Rúùtù, àmọ́ a ṣì lè máa bá a nìṣó láti máa sapá láti pinnu bí ọjọ́ ọ̀la wa ṣe máa rí. A kúkú fẹ́ máa se bi Ọlọ́run dípò ká máa fọkàn tán an ká sì máa dúró dè é. Ìwé Mímọ́ jẹ́ kó ṣe kedere pé a gbọ́dọ̀ dúró de Olúwa; ó lé ní ìgbà ogójì tí Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé ká ṣe bẹ́ẹ̀.
Ìdánilójú nínú àkókò Ọlọ́run àti dídúró de E lè jẹ́ ìpèníjà. Ó jọ mí lójú pé àṣẹ tí Náómì pa fún Rúùtù pé kó dúró ti Bóásì kò bọ́gbọ́n mu rárá. Náómì ò fẹ́ dúró de Ọlọ́run, àmọ́ ó sọ fún Rúùtù pé kó dúró de Bóásì kó tó ṣe nǹkan. Ki a sórọ̀ nípa ìkòkò omi gbígbóná tí ó ń pe ìkòkò oúnje ni dúdú! Ká tó máa yára dá Náómì lẹ́jọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ ló mú kó ṣe ohun tó ṣe. Ó ṣeé ṣe kí Náómì gbà gbọ́ pé Ọlọ́run máa lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tóun dá yìí fún ire Rẹ̀. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, láìfi ohun tí Náómì ṣe pè, àwọn ète Ọlọ́run tẹ̀ síwájú.
Ṣé àwọn apá ibì kan wà nínú ìgbésí ayé rẹ tí o ti ń dúró de àkókò tí Ọlọ́run yàn? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé o kò tíì lọ́kọ tàbí láya, tó o sì ń retí ẹni tó máa di ọkọ tàbí aya rẹ lọ́jọ́ iwájú, tàbí kó jẹ́ pé o kò níṣẹ́ lọ́wọ́, tó o sì ń wáṣẹ́ titun. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìṣòro aíìbímọ lò ń bá yí, tó o sì ń retí ìbùkún Ọlọ́run nípa ọmọ bíbí. Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé Ọlọ́run kì í fi nǹkan falẹ̀. Àkókò tó yàn yẹn dára gan-an ni
.Má ṣe sì mí gbó, mo KÓRÌÍRA dídúró. Ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé dídúró lè jẹ́ ká túbọ̀ mọrírì bí Ọlọ́run ṣe ń bójú tó wa lọ́nà àgbàyanu. Nígbà míì, ó máa ń ṣe kedere sí wa pé a ní láti dúró de àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan kí wọ́n tó ṣẹlẹ̀. Àmọ́, ǹjẹ́ o ti rò ó rí pé ìdí tó fi yẹ kó o máa dúró ni pé kí Ọlọ́run lè kọ́ ẹ ní nǹkan kan?
Àwọn apá wo nínú ayé rẹ ni Ọlọ́run ti sọ pé kó o ní sùúrù? Kí ni Oun fi kọ́ ọ bí o ti ń dúró dè É
Nípa Ìpèsè yìí

Bóyá ọ̀kan l'ára àwọn ìtàn kúkúrú tí ó wunilori jù lọ, ní ìwé Rúùtù tí ó jẹ́ àkọsílẹ̀ ti ìràpadà ìfẹ́ Ọlọ́run. Iwe Rúùtù jẹ́ ìtàn tí ó yanilẹ́nu bí Ọlọ́run ṣe nlo ìgbésí ayé àwọn ènìyàn lásán láti ṣe iṣẹ́ ìfẹ́ Òun ti o jé Ọba Aláṣẹ. Pẹ̀lú àwọn àkàwé tí ó rẹwà ti ìfẹ́ àti ìrúbọ Krístì fún àwọn ènìyàn Rẹ, a fi hàn wá ipele tí Ọlọ́run lọ láti ra àwọn ọmọ Rẹ̀ padà.
More