Rúùtù: Ìtàn Ìràpadà ìfẹ́ Ọlọ́runÀpẹrẹ

Ruth: A Story of God’s Redeeming Love

Ọjọ́ 1 nínú 7

Ó lè ti ṣe ọ́ ní kàyéfì ìdí tí a kò fi mú ẹsẹ kankan nínú àwọn ẹsẹ fún ẹ́kọ́ wa lónìí nínú ìwé Rúùtù. Ìdáhùn tó ṣe kedere ni pé ìwé Rúùtù kò kàn dá lórí ìtàn Rúùtù. Nípa Jésù ni. Nínú Lúùkù 24:27, Jésù sọ fú n àwọn ọkùnrin tí ó ń bá rìn pé gbogbo Ìwé Mímọ́ jẹ́ nípa Òun. Jòhánù 1 sọ fún wa pé Ọ̀rọ̀ náà wà pẹ̀lú Ọlọ́run ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, a sì dá ohun gbogbo fún Ọ̀rọ̀ náà àti nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ náà. Nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyẹn, Ọ̀rọ̀ náà ń tọ́ka sí Jésù Kristi. Nítorí náà, gbogbo àwọn ìwé tó wà nínú Májẹ̀mú Láéláé, títí kan ìtàn Rúùtù, ló dá lórí Jésù.

Ó tún bá ọgbọ́n mu láti gbà pé kì í ṣe àwọn obìnrin nìkan ni ìwé Rúùtù wà fún. Bó bá jẹ́ pé Jésù ni ìwé Rúùtù dá lé lórí, tí gbogbo Ìwé Mímọ́ sì "wúlò fún kíkọ́ni àti fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà," a jẹ́ pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo èènìyàn kọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ìwé Rúùtù ṣe àkójọ irúfé ohun tó da onírúurú ẹ̀yà èniyàn, lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ọlọ́rọ̀ àti tálákà, ẹ̀yà àti ẹ̀sìn tó yàtọ̀ sí ara wọn pọ̀. A óò rí i pé ìwé Rúùtù ṣe àpèjúwe ìfẹ́ Ọlọ́run àti ìràpadà rẹ̀ nínú ìgbésí ayé àwọn gbáàtúù èèyàn. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ń lo àwọn èèyàn wọ̀nyẹn, aláìpé àti ẹlẹ́ṣẹ̀ bí wọ́n ti rí, láti ṣe ìfẹ́ Rẹ̀ nínú ìgbésí ayé wọn àti láti mú ìgbàlà Rẹ̀ wá fún aráyé.

Ọ̀kan lára ìdí tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni pé ká lè mọ Ọlọ́run dáadáa. Ronú nípa rẹ̀ ná. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé "Ọlọ́run ni ó mí sí gbogbo Ìwé Mímọ́", ó ń jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ gan-an. A máa rí bí Ọlọ́run ṣe ń darí àwọn nǹkan kó bàa lè mú ìfẹ́ rẹ̀ pípé ṣẹ nípasẹ̀ ìbójútó rẹ̀.

Ìbójútó jẹ́ ọ̀rọ̀ àwọn akọ́ ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run tí a máa ń rí nígbà tí a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kí ló túmọ̀ sí gan-an? Ó jẹ́ ọ̀nà tí Ọlọ́run ńgbà bójú tó àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀, pàápàá jù lọ àwọn ènìyàn Rẹ̀àyíká. Ọlọ́run wa jẹ́ Ọlọ́run ààyè àti ipò – níbi tí ó ti ń bá àwọn ènìyàn rẹ̀ lò. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń ṣiṣẹ́ nìyí, a lè gbẹ́kẹ̀ lé ọwọ́ ìbójútó Rẹ̀ nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, nínú iṣẹ́, nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, nínú ìgbéyàwó, nínú ọmọ títọ́, àti nínú gbogbo apá ìgbésí ayé wa yòókù.

Ní ọdún 1993, akọrin ìhìnrere Twila Paris gbé orin "God is in Control" jáde. Ọ̀rọ̀ méjì àkọ́kọ́ nínú ègbè orin náà ṣàpèjúwe ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìwé Rúùtù lọ́nà tí ó bá a mu wẹ́kú: "Ọlọ́run ní i Alákóso. A gbàgbọ́ wípé a Kò ní fi àwọn ọmọ Rẹ̀ sílẹ̀.” Ọlọ́run kò ní fi Àwọn ọmọ Rè sílẹ̀. Wọ́n lè ní ìrora àti ìjìyà, àmọ́ Kò ní pa wọ́n tì. Ọ̀kan lára àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú ìwé Rúùtù ni pé Ọlọ́run ni Ọba Alákóso.

A lè kọ́ nínú ìtàn Rúùtù pé, ní gbogbo ìgbà tí a bá ń ka Bíbélì, Ọlọ́run máa ń jẹ́ kí á mọ̀ bí Òun ṣe ń ṣiṣẹ́ àti bí Òun ṣe ń bá àwọn ènìyàn Òun lò kí a lè lóye kí á sì gbẹ́kẹ̀lé Òun nígbà tí a bá rí i tí Óun ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ nínú ìgbésí ayé wa. Nígbà míì, àwọn nǹkan burúkú máa ń ṣẹlẹ̀. Àmọ́, a lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Òun ló ń darí gbogbo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀, Ó sì ń gbèrò láti mú kí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, fún ire wa àti ògo Rẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí ìwé Rúùtù ṣe kọ́ wa nípa ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa, bẹ́ẹ̀ náà ló tún kọ́ wa pé a nílò Olùgbàlà. Ọ̀kan lára kókó pàtàkì tó wà nínú ìwé Rúùtù ni ìwúlò olùràpadà-ẹbí, ipò tí Bóásì kún. Rúùtù àti Náómì wá ní ipò tí wọ́n nílò ẹnì kan gan-an láti gbà wọ́n nínú ipò tí wọ́n wà yìí. Bí a ṣe ń rí i tí Ọlọ́run ń dáhùn àdúrà wọn, tó sì ń pèsè ohun tí wọ́n nílò, ńṣe ló ń mú kí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan wáyé láti mú ìfẹ́ Rẹ̀ ṣẹ, láti mú àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ, àti láti pèsè ìràpadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí o ń mú kí ìyapa wà láàrin ènìyàn àti sí Ọlọ́run. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àrà ọ̀tọ̀ tó wà nínú ìwé Rúùtù ń darí wa sí ìgbàlà gíga jù lọ tí Ọlọ́run pèsè fún aráyé, ìyẹn Jésù Krístì.

Nípa Ìpèsè yìí

Ruth: A Story of God’s Redeeming Love

Bóyá ọ̀kan l'ára àwọn ìtàn kúkúrú tí ó wunilori jù lọ, ní ìwé Rúùtù tí ó jẹ́ àkọsílẹ̀ ti ìràpadà ìfẹ́ Ọlọ́run. Iwe Rúùtù jẹ́ ìtàn tí ó yanilẹ́nu bí Ọlọ́run ṣe nlo ìgbésí ayé àwọn ènìyàn lásán láti ṣe iṣẹ́ ìfẹ́ Òun ti o jé Ọba Aláṣẹ. Pẹ̀lú àwọn àkàwé tí ó rẹwà ti ìfẹ́ àti ìrúbọ Krístì fún àwọn ènìyàn Rẹ, a fi hàn wá ipele tí Ọlọ́run lọ láti ra àwọn ọmọ Rẹ̀ padà.

More

A fẹ́ dúpẹ́ l'ọ́wọ́ Ilé-iṣẹ́ Ìtẹ̀wé Armchair Theology fún ìpèsè ètò yí. Fún àlàyé sí'wájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.timothymulder.com/