Rúùtù: Ìtàn Ìràpadà ìfẹ́ Ọlọ́runÀpẹrẹ

Ìbásepọ̀ wa pẹ̀lú ẹlòmíràn jẹ itọ́kasí ìbásepọ̀ wa pẹ̀lú Kristi. Bóásì fi ìfẹ́ inú rere Kristi hàn nínú ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ní oko rẹ̀, bí ó ṣe ń bá Rúùtù lò, àti bí ó ṣe ń pèsè oúnjẹ fún Náómì. Ní rírántí pé ìwà títọ́ àti ìwà-bí-Ọlọ́run ṣọ̀wọ́n ní Ísírẹ́lì ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyẹn mú kí ìwà Bóásì túbọ̀ yani lẹ́nu. Àwọn ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ tí Boasi sọ nínú ìwé Rúùtù jẹ́ ìbùkún ní orúkọ Jèhófà. Ọkàn rẹ̀ dá lórí Ọlọ́run débi pé ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn ni pé kí wọ́n ní ìrírí àwọn ìbùkún Olúwa. Ninu gbogbo eyi, Boasi ṣe afihan Kristi.
Bóásì lè tí bá àwọn òṣìṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìgbéraga. Ṣùgbọ́n ó bá wọn ló gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ wọ́n, gẹ́gẹ́ bí arákùnrin rẹ. Ìdáhùn àwọn olùkórè rẹ dára bákan náà, ó sì jẹ ìbùkún fún Bóásì. Ẹ̀kọ́ tí a rí kọ̀ nibẹ nìyí: ṣíṣe paṣípáàrọ̀ ìbùkún pẹ̀lú àwọn tí ó wà ní àyíká wa jẹ onìwà-bí-Ọlọ́run.
Rúùtù tí wá sí pápá Bóásì láti kóra jọ lẹhin àwọn olùkórè. (Gbígbá ọkà ti a fi silẹ lakoko ikore jẹ ọna kan ti Israeli fí ń pese fun awọn talaka). Bóásì sọ fún alábòójútó àwọn nípa Rúùtù. Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kúkúrú, ọga àgbà náà sọ lẹ́rìméjì pé Móábù ni ó tí wá. Bóyá kò mọ́ ọ́n, ó tẹnu mọ ipò tí ó wà gẹ́gẹ́ bí abọ̀rìṣà tí ó wà láti ibi tí a mọ sì ọ̀tá Ísírẹ́lì. Ni idakeji ẹ̀wẹ̀, Bóásì fí ìfẹ́ hàn sí ó sì pe Rúùtù ni ọmọbìnrin rẹ. Ó ṣe ìtọ́jú rẹ̀ bí ara ìdílé rẹ gangan, títí kan omi tí a sábà máa ń fi pamọ́ fún àwọn òṣìṣẹ́ ọkùnrin, ó sì pè é láti jẹ oúnjẹ ọ̀sán pẹ̀lú rẹ̀. Ó fún un ní ọkà tó pọ̀ tó láti kó lọ sí ilé fún Náómì láti pèsè oúnjẹ fún wọn, tó ìdíwọ́n owó ọ̀yà ọ̀sẹ̀ méjì! Ó pè é pé kó kàn dúró sínú oko rẹ̀ fún ìyókù àkókò ìkórè, ó sọ fún àwọn olùkórè rẹ̀ pé kí wọ́n fi àfikún ọkà sílẹ̀ fún òun, ó sì sọ fún àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe yọ lẹ́nu tàbí fọwọ́ kàn án. O ni òye tí ó kọjá abuku rẹ ti àtẹ̀hìnwá o si ri i bi ẹni ọlá ati ẹni iyì ti o yẹ fún ọ̀wọ̀ àti ààbò rẹ.
Ọ̀nà tí Boasi ṣe bá awọn ti o wa ni oko rẹ ló mú inú rere ati ìbọ̀wọ̀fúnni dání. O ṣe akitiyan ni tòótọ́ pẹlu wọn, pàápàá Rúùtù, ọmọbìnrin Móábù tí ó mọ Ọlọrun. Kí nìdí tí Bóásì fi fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn sí Rúùtù? Gẹ́gẹ́ bí ìyókù àwọn ará ìlú náà, ó ti gbọ́ nípa bí ó ṣe ń bá Náómì ìyá ọkọ rẹ̀ lò. Nítorí ìdí èyí, Bóásì fi irú ìfẹ́ inú rere kan náà hàn sí Rúùtù. Bóásì jẹ ọkùnrin ọlọ́lá ti o mọ iwa rere ninu awọn mìíràn. Òun jẹ ẹniti o ni àdéhùn gidi!
Ìbásepọ̀ Bóásì pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn ṣe àfihàn irú ìbásepọ̀ tí Kristi ni pẹ̀lú àwọn míràn. Bí Bóásì ṣe súre fún àwọn òṣìṣẹ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni Kristi ṣe súre fún àwọn tí ó yí í ká ni àkókò tí Ó wà ní orí ilẹ̀ ayé —Ó kò wọn mọ́ra, Ó mú wọ́n lára dá, Ó sì lè àwọn ẹ̀mí Èṣù jáde. Bí Bóásì ṣe bọ́ àwọn òṣìṣẹ́ rẹ tí ó sì bá wọn jẹun, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní Kristi ṣe bọ́ àwọn omolẹ́hìn Rẹ̀ tí Ó sì bá wọn jẹun pọ pẹ̀lú. Bí Bóásì ṣe bá awọn ènìyàn miran ló gẹ́gẹ́ bí arákùnrin àti arábìnrin, Kristi pẹ̀lú ṣe bẹ́ẹ̀ fún wa. Bí Boasi ṣe nífẹ̀ẹ́ ara tí ó sì gba láti ṣe ojúṣe fún àwọn ẹlòmíràn, Kristi pàápàá nífẹ̀ẹ́ ara, ó sì di ojúṣe fún àwọn tí Ó pè.
Ọkàn nínú àwọn ohun ńlá nípa ìjọsìn Ọlọ́run ni pe O kò ipa ti ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ nínú ayé wa. Ọlọ́run kò ṣẹ́da ayé tán kò mú ìjókòó Rẹ̀ sẹ́yìn kí Ó sì palọ́lọ́ síbẹ̀. "Ìfarahàn" Ọlọ́run túmọ̀ sí wípé Ó fẹ́ ká mọ Òun, kí a ní ìwòye Òun, kí a sì lè rí nǹkan di mú nípa Òun. Nípa níní òye ìyàlẹ́nu àlàfo láàrin Ọlọrun alágbára gbogbo àgbáyé ati ara wa, Ọlọrun rán Ọmọ Rẹ ni irisi ọkunrin kan, Jesu Kristi, ki a le mọ Ọ ki a si ni ìbásepọ̀ pẹ̀lú Oun funrararẹ. Eyi ni ìpapòdà ti Kristi, ninu eyiti Ọlọ́run di èniyàn ti o si gbé láàrin ohun tí Ó dà ti o si ṣe ajọṣepọ pẹlu wọn.
Ìfẹ́ inú rere tí Bóásì ṣàpèjúwe rẹ wá sí ìmúṣẹ nípa ikú Kristi lórí àgbélébùú. Nípa ìrúbọ àìmọtara-ẹni-nìkan Rẹ̀, Jésù ti súre fún wa kí a lè lo ayérayé pẹ̀lú Rẹ̀. Kò lè sì ìbùkún ńlá tó jù èyí.
Bóásì mú igbagbọ rẹ lo bí ó ṣe fi ìfẹ́ Kristi hàn sí àwọn tí ó yí í ká, àti àwọn tí àṣà wọn yà sọ́tọ̀ pàápàá. Bí ó ṣe ń bá àwọn òṣìṣẹ́ rẹ lo, Rúùtù àti Náómì pẹ̀lú, "ṣe ìṣelòdì sì àṣà" àti pé ó jẹ àpẹẹrẹ ìyípadà ìfẹ́ ayé tí Kristi yíò mú wá fún wá. Báwo ni ó ṣe ń fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn sí àwọn tí ó yí ọ ká?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Bóyá ọ̀kan l'ára àwọn ìtàn kúkúrú tí ó wunilori jù lọ, ní ìwé Rúùtù tí ó jẹ́ àkọsílẹ̀ ti ìràpadà ìfẹ́ Ọlọ́run. Iwe Rúùtù jẹ́ ìtàn tí ó yanilẹ́nu bí Ọlọ́run ṣe nlo ìgbésí ayé àwọn ènìyàn lásán láti ṣe iṣẹ́ ìfẹ́ Òun ti o jé Ọba Aláṣẹ. Pẹ̀lú àwọn àkàwé tí ó rẹwà ti ìfẹ́ àti ìrúbọ Krístì fún àwọn ènìyàn Rẹ, a fi hàn wá ipele tí Ọlọ́run lọ láti ra àwọn ọmọ Rẹ̀ padà.
More