Rúùtù: Ìtàn Ìràpadà ìfẹ́ Ọlọ́runÀpẹrẹ

Ruth: A Story of God’s Redeeming Love

Ọjọ́ 3 nínú 7

Ọ̀rọ̀ Rúùtù sí Náómì nínú Rúùtù 1:16-17 wà lára àwọn ohun tó ṣe kókó nínú gbogbo Ìwé Mímọ́. Ìfihàn ìfẹ́ àti òtítọ́ tó rẹwà yìí ni wọ́n sábà máa ń lò fún ètò ìgbéyàwó. Ṣùgbọ́n Rúùtù tún ń jẹ́wọ́ ìyípadà rẹ̀ sí Ọlọ́run kannáà tòótọ́. Ó ti wá mọ Ọlọ́run Náómì gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ tí agbára àti oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ gùn kọjá ààlà Israẹli. Ìpinnu Rúùtù láti tẹ̀lé Náómì àti Ọlọ́run rẹ̀ yóò yọrí sí ìgbésí ayé tí ó kọjá ohunkóhun tí ó lè rò.

Gbólóhùn kọ̀ọ̀kan nípa ọ̀rọ̀ Rúùtù tọ́ láti tú.

"Níbi tí o bá lọ, ni èmi yóò lọ" - nípa sísọ èyí, Rúùtù sọ fún Náómì pé òun kò ní fi í sílẹ̀ láéláé. Rúùtù ṣe ìfarajọ ìfọkànsìn Ọlọ́run hàn sí Náómì. Yíò tẹ̀lé Náómì níbikíbi tí wọ́n bá lè lọ. Rúùtù ṣe àfẹ́rí Náómì ju bí ó ṣe ṣe sí àwọn ènìyàn tirẹ̀ lọ. Ìfarajìn rẹ̀ sí Náómì jẹ́ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ayérayé.

"Níbi tí o bá gbé kalẹ̀, ni èmi náà yóò gbé" - jẹ́ àfikún "ibi tí o bá lọ, ni èmi yóò lọ," ọ̀rọ̀ yìí fi ìfẹ́ Rúùtù hàn fún Náómì ní ìpele tó jinlẹ̀. Kò ṣe pàtàkì bóyá Náómì ń gbé ní ẹsẹ̀ àgbàrá tàbí ilé ńlá; Rúùtù máa dúró tì í. Rúùtù sọ fún Náómì pé, "Níbi tí o bá ń gbé, èmi yóò gbé." Rúùtù fi èrò rẹ̀ hàn láti di ọmọbìnrin tòótọ́ fún Náómì. Gbólóhùn ife yi lẹwa jọjọ!

"Àwọn ènìyàn rẹ yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ yóò sì jẹ́ Ọlọ́run mi" - pẹ̀lú ìjẹ́wọ́ yìí, Rúùtù jẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ tuntun rẹ̀. Rúùtù lo èdè májẹ̀mú Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí a ti fihàn nínú Ẹ́kísódù 6:7 àti Sekariah 8:8. Rúùtù sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlérí májẹ̀mú Ọlọ́run padà sí Ọlọ́run. Ó nífẹ̀ẹ́ Náómì àti Ọlọ́run Náómì pẹ̀lú ìfẹ́ bíi Ọlọ̀run. Rúùtù fi apẹẹrẹ nla ti nkan ti o yẹ ki a ṣe ninu adura hàn: sọ awọn ileri Ọlọrun pada si I. Kì í ṣe nítorí Ọlọ́run nílò wa láti ránÒun létí awọn ileri rẹ, Kò gbàgbé wọn. Ó fẹ́ kí á tún àwọn ìlérí Rẹ̀ ṣe nítoría gbàgbé wọn. Ìfọkànsìn Rúùtù sí Ọlọ́run ni ìpìlẹ̀ ìfarajìn rẹ̀ sí Naomi.

-"‭Ibiti iwọ ba kú li emi o kú si, nibẹ̀ li a o si sin mi:" - Nítòsí Ìlà Oòrùn àtijọ́, níbi tí wọ́n bá sin òkú sí tọ́ka irú ọlọ́run tí o jọ́sìn fún. Rúùtù tẹnumọ́ ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Ọlọ́run kannáà tòótọ́ nípa sísọ pé kí á sin ín sí Isráẹlì. Kò tilẹ̀ sí ikú tí yóò yà Rúùtù kúrò lọ́dọ̀ Náómì.

Nípa títẹ̀lé Náómì lọ sí Bẹtilẹhẹmu, Rúùtù fi ara rẹ̀ sílẹ̀ láti gbé ìgbé ayé opó aláìní. Síbẹ̀síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin Rẹ̀, Ọlọ́run A máa tọ́jú àwọn opó. Rúùtù gba èyí gbọ́. Kò ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run nìkan; ó jọ̀wọ́ ohun gbogbo tí ó ní tí ó sì jẹ́ fún Un. Ni Matteu 19:29, Jésù kéde pé ẹnikẹ́ni tí ó fi ìdílé sílẹ̀ tàbí ilé làti tẹ̀lé Òun yóò gba ẹbí yẹn padà ní ọgọ́rọ̀rún àti iyè àìnípẹ̀kun. Rúùtù kò ì tíì rí àwọn ìbùkún wọ̀nyí tí Ọlọ́run ti ṣèlérí, ṣùgbọ́n ó ṣe tán láti gbé ìgbésẹ̀ ìgbàgbọ́ tó ń yí ayé padà.

Iwọ náà ńkọ́? Báwo ni ìgbàgbọ́ rẹ nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run ṣe lágbára tó? Kini o ṣetan lati fi sílẹ̀ fun U?

Nípa Ìpèsè yìí

Ruth: A Story of God’s Redeeming Love

Bóyá ọ̀kan l'ára àwọn ìtàn kúkúrú tí ó wunilori jù lọ, ní ìwé Rúùtù tí ó jẹ́ àkọsílẹ̀ ti ìràpadà ìfẹ́ Ọlọ́run. Iwe Rúùtù jẹ́ ìtàn tí ó yanilẹ́nu bí Ọlọ́run ṣe nlo ìgbésí ayé àwọn ènìyàn lásán láti ṣe iṣẹ́ ìfẹ́ Òun ti o jé Ọba Aláṣẹ. Pẹ̀lú àwọn àkàwé tí ó rẹwà ti ìfẹ́ àti ìrúbọ Krístì fún àwọn ènìyàn Rẹ, a fi hàn wá ipele tí Ọlọ́run lọ láti ra àwọn ọmọ Rẹ̀ padà.

More

A fẹ́ dúpẹ́ l'ọ́wọ́ Ilé-iṣẹ́ Ìtẹ̀wé Armchair Theology fún ìpèsè ètò yí. Fún àlàyé sí'wájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.timothymulder.com/