Rúùtù: Ìtàn Ìràpadà ìfẹ́ Ọlọ́runÀpẹrẹ

Bí o ṣe ń ka ìwé Rúùtù, ó ṣeé ṣe kí o gbà wí pé Rúùtù ni ẹni tí a rà padà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òtítọ́ ni èyí, ẹnì kan tún wà tí ó gba ìràpadà ju Rúùtù lọ: Náómì. Rúùtù àti Náómì ní ìrírí àwọn ìyípadà tí ó gbámúṣé, àmọ́ ìyípadà Náómì jẹ́ ọ̀kan l'ára àwọn kókó pàtàkì inú ìwé náà. Ìràpadà rẹ̀ ṣe àpẹẹrẹ ìràpadà gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Olúwa.
Jálẹ̀ ìtàn rẹ̀, Rúùtù ń d'àgbà nínú ìfọ̀kànbalẹ̀, ó sì ní ìrírí ìgbéga ní àwùjọ. Rúùtù bẹ̀ẹ̀rẹ̀ ìtàn náà gẹ́gẹ́ bíi ará Móábù, àlejò kèfèrí ní ilẹ̀ àjèjì, òtòṣì opó. Ní ìgbà tí ó pàdé Bóásì, ó sọ pé òun “rẹlẹ̀ ju ìránṣẹ́ lọ.” L'ẹ́yìn tí Rúùtù ti ṣa oúnjẹ ní ilẹ̀ rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ oṣù, ó fi àyè àjọṣe pẹ̀lú Bóásì sílẹ̀, Bóásì sì ń tọ́jú rẹ̀. Ó ṣe ara rẹ̀ ní ìránṣẹ́ Bóásì ní ìgbà tí ó ní kí ó fẹ́ òun (ìtumọ̀ ohun tí ó ṣe nìyẹn). Fífẹ́ Bóásì ti mú kí ipò rẹ̀ ní àwùjọ ga síi gẹ́gẹ́ bíi aya olówó ònilẹ̀ àti ọkùnrin tí a ṣe àpèjúwe gẹ́gẹ́ bíi “ẹni ẹ̀yẹ.” Síbẹ̀síbẹ̀, ìyípadà Rúùtù kò parí síbẹ̀. A gbé e ga ju ìyàwó tí a bọ̀wọ̀ fún àti ẹnìkan ní àdúgbò ṣá. A kà á mọ́ àwọn ènìyàn ọlọ́lá nínú ìtàn ìdílé Olúwa títí láé. Ṣùgbọ́n ìwé Rúùtù tún jẹ́ nípa ìràpadà Náómì.
Àbábọ́ ìràpadà Ọlọ́run fún Náómì jẹ́ kí a mọ̀ wí pé Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́ àti olùpèsè láì ka ohun tí Náómì ti ṣe sẹ́yìn sí. Ní ìparí Orí 1, Náómì padà sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù gẹ́gẹ́ bíi tálíkà. Ó ṣófo nípa tí ẹ̀mí, nípa ti ara, àti ní ti ìmọ̀lára. Ó sọ wí pé “Olúwa ti bá a lò ní ọ̀nà kíkorò.” Ní ìgbà tí ìwé náà fi máa parí, Náómì ti kún nípa ti ẹ̀mí, nípa ti ara, àti ní ti ìmọ̀lára. Ọlọ́run ko gbàgbé Náómì. Ọmọkùnrin tí óún gbé jó ní itan rẹ̀ jẹ́ ẹ̀ri síi. Naomi, tí ó ṣe ọ̀fọ̀ kíkorò nítorí pé kò ní àrólé, ti ní ẹyọ̀ kan báyìí. Ọlọ́run ti dá ọlá àti ipò rẹ̀ padà ní àwùjọ. Ó ti di ẹni kíkún: l'áti Mara dé Naomi, kíkorò sí dídùn, òfo sí kíkún, l'áti tálíkà sí ìyá-àgbà ọba - ọba tí ó tóbi jù lọ nínú ìtàn Ísráẹ́lì. Ó lọ l'áti arúgbó tí kò ní ọmọ, tí kò ní àrólé, di ìyá-àgbà Imanuẹli, Ọlọ́run pẹ̀lú wa, Jésù Kristi.
Ní ìkẹhin, kókó ìwé Rúùtù ni ìṣeun-ìfẹ́ Ọlọ́run, èyí tí ó n yọ'rí sí ìmúpadàbọ́sípò àti ìbùkún - ti ara àti ti ẹ̀mi. Èyí ni ohun tí Ọlọ́run máa n ṣe; Ó mú ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ àti ìṣọ̀tẹ̀ ti pa run padà bọ̀ sí'pò. A lè kọ́ ẹ̀kọ́ l'áti inú ìyípadà Náómì wípé Ọlọ́run wa mọ àwọn àìní wa délé délé, Ó sì ń ṣe àníyàn gan-an fún ire wa. Ikú Kristi ní orí igi àgbélébùú gbé ire àwọn onígbàgbọ́ ṣíwájú ara ti Rẹ̀.
Ìmúpadàbọ̀sípò àgbàyanu Náómì ni irú ìyípadà tí Ọlọ́run ń ṣe nínú ìgbésí ayé gbogbo àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé E gẹ́gẹ́ bíi Olúwa àti Olùgbàlà wọn. Gbogbo wa ni a ṣe ìyípadà kan náà: l'áti kíkorò sí dídùn, òfo sí kíkún, àjèjì sí ìdílé Ọlọ́run sí jíjẹ́ ọmọ Olódùmarè, àwọn ajogún pẹ̀lú Kristi. Kò leè sí ìyípadà tí ó ju èyí. Nínú ìwé Faithful God: An Exposition on the Book of Ruth, Sinclair Ferguson sọ wí pé, “Èyí ni ọ̀nà Ọlọ́run. Ó tipasẹ̀ àwọn ohun aláìlera ayé yìí da àwọn ohun tí ó ní agbára rú; ní'pa ohun ìrẹ̀lẹ̀ ati ẹ̀gàn, Ó d'ójú ti àwọn alágbára; àti nípasẹ̀ àwọn ohun tí kò sí, Ọ́ dààmú àwọn ohun tí ó wà.”
Ṣé o ní èrò wí pé ìràpadà Náómì tóbi ju ti Rúùtù lọ? Njẹ́ àwọn ènìyàn wà nínú ìgbésí ayé rẹ tí yíò ní ànfààní l'áti gbọ́ nípa ìyípadà rẹ?
Nípa Ìpèsè yìí

Bóyá ọ̀kan l'ára àwọn ìtàn kúkúrú tí ó wunilori jù lọ, ní ìwé Rúùtù tí ó jẹ́ àkọsílẹ̀ ti ìràpadà ìfẹ́ Ọlọ́run. Iwe Rúùtù jẹ́ ìtàn tí ó yanilẹ́nu bí Ọlọ́run ṣe nlo ìgbésí ayé àwọn ènìyàn lásán láti ṣe iṣẹ́ ìfẹ́ Òun ti o jé Ọba Aláṣẹ. Pẹ̀lú àwọn àkàwé tí ó rẹwà ti ìfẹ́ àti ìrúbọ Krístì fún àwọn ènìyàn Rẹ, a fi hàn wá ipele tí Ọlọ́run lọ láti ra àwọn ọmọ Rẹ̀ padà.
More