Rúùtù: Ìtàn Ìràpadà ìfẹ́ Ọlọ́runÀpẹrẹ

Ruth: A Story of God’s Redeeming Love

Ọjọ́ 2 nínú 7

Nínú ìwé Rúùtù orí Kínní, Ọlọ́run fi òtítọ́ Rẹ̀ hàn wá:

.Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́ nígbàtí àwa kò jẹ́ olódodo

.Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́ nígbàtí a kò ní ìrètí

.Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́ nígbàtí a bá gbàgbé àwọn ìlérí Rẹ̀.

Élímélékì, ìyàwó rẹ̀ Náómì àti àwọn ọmọkùnrin wọn méjèèjì gbé ayé lákòókò tí ìyàn mú ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìyàn máa ń yọrí sí nítorí àìgbọràn ńlá tí Ísírẹ́lì ṣe sí Ọlọ́run. Ní àwọn àkókò yẹn, Ọlọ́run gbà àwọn ènìyàn Rẹ̀ láàyè láti jìyà nípasẹ̀ ìyàn kí ó lè darí ọkàn wọn sí ronúpìwàdà kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Dípò kí ó pa dà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, Élímélékì yí ẹ̀yìn rẹ̀ padà sí Olúwa ó sì mú ìdílé rẹ̀ lọ sí Móábù. Wọ́n gbìyànjú láti sá fún ìjìyà Ọlọ́run dípò ìrònúpìwàdà. Ó dà bí ìgbà tí Élímélékì wí pé, “Bí Ọlọ́run kò bá pèsè fún èmi àti ìdílé mi, èmi yóò ní láti ṣe aájò sí ọ̀rọ̀ ara mi.” Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kórìíra Móábù àti ìjọsìn wọn sí Kémóṣì ọlọ́run èké. Ó ti sọ fún àwọn èèyàn Rẹ̀ ní kedere pé kí wọ́n má ṣe ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú Móábù. Élímélékì yan àtilà láàyò ju ìgbọràn lọ. Bíbójútó ìdílé rẹ̀ kì í ṣe ìdáláre fún rírú òfin Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò dá àìnígbàgbọ́ wa padà pẹ̀lú ohun kan náà (Róòmù 3:3-4). A máa rí i pé Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́ síbẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀.

Nígbà tí ó wà ní Móábù, Élímélékì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ kú, ó sì fi Náómì sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn aya ọmọ rẹ̀ méjèèjì, Ópà àti Rúùtù. Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo ohun tí Náómì ńlà kọjá? Níwájú ibojì olùfẹ́ kẹta, Náómì ti kan ìṣẹ̀lẹ̀ àpáta. Kò ní ìrètí mọ́. Ìpàdánù ọkọ rẹ̀ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì kọjá ìdílé. Wọ́n di opó mẹ́ta aláìní nílẹ̀-lọ́nà láti gbọ́ bùkátà ara wọn.

Ìpọ́njú ígbàgbogbo a máa mú ènìyàn ṣiyèméjì nínú Ọlọ́run. Ojú Náómì di sí àwọn ètò ńlá tí Ọlọ́run ní ṣùgbọ́n kọ ṣiyèméjì sí ìwàláyé Ọlọ́run; Ó ṣiyèméjì sí ìfẹ́ àti ìtọ́jú Rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí nǹkan bá dà bíi pé ó ṣókùnkùn fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọjọ́ àánú Ọlọ́run ń súnmọ́lé. Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa nínú ìpọ́njú wa. A gbọ́dọ̀ rántí pé Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́ kódà nígbà tí a kò bá nírètí.

Nígbà tí ayọ̀ àwọn ará ìlú kún láti kí Náómì, ó sọ fún wọn pé kí wọ́n pe òun ní Márà. Náómì rò wípé Ọlọ́run dojú ìbínú kọ òun nítorípé “Ó ti bá a lò lọ́nà kíkorò.” Nípa bẹ́ẹ̀, ó ti pààrọ̀ orúkọ tí Ọlọ́run fún un (Naomi, tó túmọ̀ sí “dídùn”) fún orúkọ kan tí a gbé ka ipò àti ìmọ̀lára rẹ̀ (Mara, tó túmọ̀ sí “kíkorò”).Náómì kò rí i pé Ọlọ́run ní àwọn nǹkan “dídùn” ní ìpamọ́ fún òun. Ó yí ojú ìwòye rẹ̀ nípa òtítọ́ padà, àti pẹ̀lú, ó tún èrò rẹ̀ nípa Ọlọ́run ṣe. Náómì ò rí Ọlọ́run bí olóòótọ́ àti onífẹ̀ẹ́ sí i mọ́. Kò tilẹ̀ lè “rí” Rúùtù tí ó dúró tì í lẹ́gbẹ̀ẹ́. Rúùtù, ẹnití ó tí polongo ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti ìfọkànsìn fún Náómì, lè máa ronú pé, “Mo dúró níhìn-ín gan-an!” Náómì ti gbàgbé àwọn ìlérí Ọlọ́run (Deuteronomy 31:8). Náómì gbàgbé pé Ọlọ́run ṣèlérí pé Òun Òun yóò wà pẹ̀lú rẹ̀, kò sì ní fi í sílẹ̀ tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ láé. Síbẹ̀síbẹ̀, Ọlọ́run jẹ́ olódodo, pàápàá nígbàtí a bá gbàgbé àwọn ìlérí Rẹ̀.

Ní gbogbo Ìwé Mímọ́, a rán wa létí ìfẹ́ dídúróṣinṣin ti Ọlọ́run. Nípàṣẹ àwọn orísìírísìí ìṣẹ̀lẹ̀ nínú ìgbésí-ayé Náómì, ìfẹ́ Ọlọ́run si i kò yí padà. Nígbàtí Élímélékì àti Náómì kẹ̀yìn sí Ọlọ́run, Ó jẹ́ olóòótọ́. Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́ nígbàtí Náómì kò ní ìrètí lẹ́yìn ikú ọkọ rẹ̀ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjì. Nígbàtí ó gbàgbé àwọn ìlérí Ọlọ́run, Ọlọ́run rántí níti ara Rẹ̀. Ipò yòówù tí a ti lè bá ara wa, a lè gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run láti jẹ́ olódodo sí wa. Kò ní fi àwọn ọmọ Rẹ̀ sílẹ̀.

Ǹjẹ́ o ti ní ìmọ̀lára kíkorò tàbí àìníreti bi Náómì rí? Ǹjẹ́ o ti pàdánù àwọn ìbùkún tí ó wà ní àyíká rẹ nítorí gbogbo èrò rẹ dá lórí ìrora rẹ? Gbogbo wa máa ń gbàgbé àwọn ìlérí Ọlọ́run fún wa a sì ma ń gbé bí àwọn aláìníbaba dípò àwọn ajogún ìjọba Rẹ̀. Kí ni díẹ̀ lára ​​àwọn ohun tí o lè ṣe láti rán ara rẹ létí òtítọ́ Ọlọ́run?

Nípa Ìpèsè yìí

Ruth: A Story of God’s Redeeming Love

Bóyá ọ̀kan l'ára àwọn ìtàn kúkúrú tí ó wunilori jù lọ, ní ìwé Rúùtù tí ó jẹ́ àkọsílẹ̀ ti ìràpadà ìfẹ́ Ọlọ́run. Iwe Rúùtù jẹ́ ìtàn tí ó yanilẹ́nu bí Ọlọ́run ṣe nlo ìgbésí ayé àwọn ènìyàn lásán láti ṣe iṣẹ́ ìfẹ́ Òun ti o jé Ọba Aláṣẹ. Pẹ̀lú àwọn àkàwé tí ó rẹwà ti ìfẹ́ àti ìrúbọ Krístì fún àwọn ènìyàn Rẹ, a fi hàn wá ipele tí Ọlọ́run lọ láti ra àwọn ọmọ Rẹ̀ padà.

More

A fẹ́ dúpẹ́ l'ọ́wọ́ Ilé-iṣẹ́ Ìtẹ̀wé Armchair Theology fún ìpèsè ètò yí. Fún àlàyé sí'wájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.timothymulder.com/