OHUN KANÀpẹrẹ

Ní òní, ìfojúsùn wa yíò dá l'órí ìtumò láti máa BÈÈRÈ nínú tẹ́mpìlì Rẹ̀. Ẹ̀yà bíbélì Msg nlo ọ̀rọ̀ èyí tí ó túmọ̀ sí “kíkọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní ibi ẹsẹ Rẹ”. Èyí jẹ́ àlàyé tí ó dára jù lọ fún ohun tí ènìyàn tí ó ní ìdojúkọ kan, tàbí tí ń lé pa OHÙN KKAN, ń ṣe.
A gbọ́dọ̀ kọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Mo ti sọ fún àwọn ìjọ wa ní ìgbà gbogbo wí pé ko dára l'áti gba ohun kan gbó nítorí pé o gbọ nínú ìwàásù kan. O nílò l'áti ṣe àwárí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún ara rẹ. A ní láti jẹ́ ènìyàn tí ó fẹ́ láti kọ́ ẹ̀kọ́.
Àwọn ọ̀nà pàtàkì márùn-ún ni ó wà tí ènìyàn ṣe lè kọ́ ẹ̀kọ́ :
Àwòrán (èyí tí a le rí wò)
Agbohùnsílẹ̀ (èyí tí a le gbó)
Àkọsílẹ̀ (èyí tí a ko, àwọn ató náà fún iṣẹ́ láti ṣe tí a ko)
Ìgbésẹ̀ (ṣe àmúlò)
Àkópọ̀ (ní ṣókí, àkópọ̀ gbogbo èyí tí a ti kọ l'ókè)
Mo sì gbàgbó wí pé ọ̀nà tí ó dára jù lọ fún wa láti kọ́ ẹ̀kọ́ tàbí d'àgbà nínú ìgbàgbó wa jẹ́ nípasẹ̀ àmúlò gbogbo oríṣiríṣi ọ̀nà tí à fi kọ́ ẹ̀kọ́. Kò sí si ohun kan tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́ láti mú ìgbàgbó rẹ dára bí kò ṣe àpapò àwọn nǹkan wọ̀nyí:
Kíka ìwé-mímọ́ (àwòrán)
Gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run (ìgbọràn)
Ìjọsìn àti Àdúrà (tí a kọ / tàbí sọ)
Mú Ìgbàgbó lò (fi ara ṣe)
Onígbàgbọ tí ó dúró ṣinṣin yóò gbé ìgbésí ayé rẹ̀ pẹ̀lú iwọntún-wọnsì gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí. Àti pé bí a ṣe ń kó ẹ̀kọ́ síi, bẹ́ẹ̀ ni a yóò máa ní ìfihàn síi. A wulẹ̀ rò pé tí a bá kàn ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ nìkan, a óò jèrè gbogbo ohun tí a nílò. Ṣùgbọ́n ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, a lè parí pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tí kò jinlẹ̀ tí a kò bá ní oye ohun tí a kà.
Richard Baxter sọ wí pé, Kì í ṣe iṣẹ́ Ẹ̀mí láti sọ ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ fún ọ kí ó sì fún ọ ní ìmọ̀ ti ọ̀run, láì sí ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti làálàá tirẹ̀, ṣùgbọ́n láti bùkún ẹ̀kọ́ yẹn, kí o sì fún ọ ní ìmọ̀ nípa bẹ́ẹ̀… wí pé o kọ̀ láti máa kó ẹ̀kọ́ nítorí ìgbẹ́kẹ̀lé èmi mímọ́, ó já sí wí pé o kọ ìwé mímọ́ fún ara rẹ.'
A nílò láti béèrè l'ọ́wọ́ ara wa ní àwọn ìbéèrè pàtàkì mẹ́ta yìí:
- Kíni a ńkọ́?
- Níbo ni a ti ńkọ́?
- Tani ó ń kọ́ wa?
Àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ orísun ohun èlò wa fún àwọn onígbàgbó láti ní ìmọ̀ àti láti d'àgbà nínú ìgbàgbó wọn, láti ilé-ìwé Bíbélì orí ayélujára sí àwọn ẹ̀kọ́ kékeré, làti àwọn àsọyé sí oríṣiríṣi abala ẹ̀kọ́.
Lẹ́yìn tí òní bá parí, gbogbo rẹ̀ dá lé wa l'órí. Ṣé ó wù wá láti d'àgbà síi? Tí a bá fẹ́, àwa yóò fi ṣe iṣẹ́.
Nípa Ìpèsè yìí

A máa ri ohun tí ó túnmọ̀ sí láti gbé fún Jésù nínú ayé tí kò ní àfojúsùn. Ayé yìí n sáré, a sì ní ìròyìn ní àtẹ́lẹwọ́ wa ju bí a ṣe nílo lọ. Njẹ́ ìwà ayé tuntun yìí rèé? Báwo ni a ṣe lè rìn jẹ́jẹ́ ní ayé tí ó ń sáré yìí? Sáàmù 27:4 ní ìdáhùn – OHÙN KAN, pẹ̀lú Ps Andrew Cartledge.
More