OHUN KANÀpẹrẹ

Èmi kò mọ̀ nípa rẹ, ṣùgbọ́n ìfojúsí mi á máa tètè yẹ̀ kúrò lórí nǹkan tí mo bá ńṣe, nítorí wí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ni ó ńré kọjá ní àyíká mi. Ǹjẹ́ o ti gbé fóònù rẹ láti ka ètò Bíbélì rẹ, ṣùgbọ́n dípò kí o máa kà á, o rí ìfitónilétí kan wí pé ẹnìkan tí ìwọ kò mọ̀ ṣe àsọyé l'órí ìfìwéránṣẹ́ Instagram rẹ, àti lẹ́hìn ńà ní òjijì o ti lo ogójì iṣẹ́jú lé méje sẹ́yìn tí ò ń wo àwọn memes? Àti pé o gbàgbé l'áti lọ sí ètò Bíbélì rẹ? Ó ti ṣe mí rí!
Gẹ́gẹ́ bíi ẹlẹ́ran ara, ìfojúsí wa máa yà kúrò l'órí nǹkan tí á ńṣe. Àwọn òǹkà fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wí pé láti ogún ọdun sẹ́yìn, àròpin ìfarabalẹ̀ ti dínkù nípasẹ̀ àádọta nínú ọgọ́rùn ún, èyí jẹ́ ìyàlẹ́nu.
AW Tozer sọ èyí nínú ìwé e rẹ̀, The Set of the Sail:
'Nínú u àwọn ọ̀tá Ìfọkànsìn, kòsí èyí tí ó ní ewu bíi kí ọkàn wa pín yà kúrò l'órí nkàn tí à ńṣe. Ohunkóhun tí ó bá rú ìyànilẹ́nu, a má a tú àwọn èrò kalẹ̀, a máa yọ ọkàn lẹ́nu, a sì máa fa àwọn ohun tí a ní ìfẹ̀ẹ́ sí tàbí yí ìdojúkọ ìgbésí ayé wa l'áti ìjọba Ọlọ́run tí ó wà ninú wa sí àgbáyé tí ó yí wa ká — èyí jẹ́ ìpínyà ọkàn; ayé sì kún fún wọn. Ọ̀làjú tí ó dá l'órí ìmọ̀-jìnlẹ̀ ti fún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ànfàní ṣùgbọ́n ó ti fà ìpínyà ọkàn wá àti nítorí náa ó mú lọ púpọ ju bí ó ti fún wa lọ....
'Ohun tí a lè ṣẹ sí ìpínyà ọkàn jẹ́ ọ̀kan náà ní báyìí pẹ̀lú bí ó ti jẹ́ tẹ́lẹ̀ àti ní ìgbà tí nǹkan ṣì rọrùn, bíi, àdúrà, ìṣàrò, àti ìgbìyànjú láti kọ ibi ara sí ohun tí ó ńsẹlẹ̀ nínú wa. Ìwé Sáàmù wí pé "Máa dúró ṣinṣin, kí o sì mọ̀", Kristi sọ fún wa wí pé kí á wọ ibi kọ́lọ́fín wa, kí á pa ìlẹ̀kùn dé àti kí á máa gba àdúrà sí Bàbá. Ó sì ń sisẹ́...
'A gbọ́dọ̀ borí àwọn ìpínyà ọkàn tàbí kí wọ́n borí wa. E jẹ́ kí á gbé ní ìrọ̀rùn; kí á fẹ́ nkan díẹ̀; kí á rìn nínú Ẹ̀mí; kí ọkàn wa kún fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ìyìn. Ní ọ̀nà yíì a lè gbé ní ìgbé àlàáfíà láì bìkítà pé à ńgbé nínú ayé ìdààmú báyìí. "Àlàáfíà ni mo fi sílẹ̀ fún-un yín, mo fún yín ní àlàáfíà mí"
Ní ìgbà náà báwo ni ó se yẹ kí á máa gbé?
Ìdáhùn ṣí ìbéèrè yìí wà ní Sáàmù 27:4.
Ó ye kí á gbé ojú wa sí ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ
Ní ìgbà tí Martha ṣe àròyé fún Jesu wí pé Mary kò ran òhun lọ́wọ́, inú re kò dùn, ọkàn rẹ pín yà, ó ní ìjákulẹ̀. Ṣùgbọ́n Jésù ṣe àgbéyo wí pé Mary yàn láti yí ojú sí OHÙN KAN.
KÍNI OHÙN KAN RẸ?
Ní ọjọ́ díẹ̀ síwájú, a óò ṣe àgbéyẹ̀wò ìdá ìpìlẹ̀ márùn tí ó ṣe pàtàkì tí yóò ràn wá l'ọ́wọ́ l'áti ṣe àtúnrí OHÙN KAN naa.
Nípa Ìpèsè yìí

A máa ri ohun tí ó túnmọ̀ sí láti gbé fún Jésù nínú ayé tí kò ní àfojúsùn. Ayé yìí n sáré, a sì ní ìròyìn ní àtẹ́lẹwọ́ wa ju bí a ṣe nílo lọ. Njẹ́ ìwà ayé tuntun yìí rèé? Báwo ni a ṣe lè rìn jẹ́jẹ́ ní ayé tí ó ń sáré yìí? Sáàmù 27:4 ní ìdáhùn – OHÙN KAN, pẹ̀lú Ps Andrew Cartledge.
More