OHUN KANÀpẹrẹ

ONE THING

Ọjọ́ 3 nínú 7

Bí a ṣe ń tẹ̀síwájú pẹlu wíwá ohun tó jẹ́ OHUN KAN ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ, a wá sí apá tó kàn nínú Sáàmù 27:4 - WÁ.

Ohun kan ni mo ń WÁ.

Kété lẹ́yìn tí Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń gbàdúrà,ó fi ìtàn ọkùnrin kan tí ó nílò nǹkan lọ́wọ́ aládùúgbò rẹ̀, tí ó sì kanlẹ̀kùn títí tí ó fi fún ní nǹkan tí ó fẹ́. Ẹni tí ó sì ń wá kiri, ó rí. Ìdí tí ó fi lè ìráyè sí ni nítorí ìkùgbù rẹ̀, tàbí ìgboyà.

Gbogbo wa la ń wá nǹkan, àmọ́ kí ni ohun tá à ń wá gan-an?

Àǹfààní ara wa tàbí àwọn ohun tó wù wá sábà ni à máa ń wá. Diẹ ninu awọn wọnyi le dara ati diẹ ninu wọn le jẹ ti ara ẹni, ṣùgbọ́n kò sí èyí tí a lè fi wé wíwá ohun kan ṣoṣo náà.

Sáàmù 14:2 sọ pé Olúwa sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run wá lórí àwọn ọmọ ènìyàn bóyá ó le rí ẹnikẹ́ni tó ń wá Ọlọ́run.

Ọ̀nà tó dára jù lọ láti wá Ọlọ́run ni pé ká rí i nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀.Bó o bá ń wá ìdáhùn, ọgbọ́n, ìtọ́sọ́nà, ìdarí tàbí ìgbàgbọ́ - gbogbo rẹ̀ wà nínú Bíbélì.

Bí á ṣe ń ka àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, kì í wulẹ̀ ṣe ọ̀rọ̀ inú ìwé lásán ni wọ́n jẹ́. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mímọ́ tí ó ń gbé ìwàláàyè ró ni, ẹni tí ó pè wá láti máa lépa Òun.Ọ̀nà tó dára jù lọ láti máa lépa Ọlọ́run ni pé ká máa lo àkókò pẹ̀lú Rẹ̀. Gbogbo ìgbà tí á bá ṣí ìwé náà, a ń lo àkókò pẹ̀lú òǹkọ̀wé náà.

Tó bá dí ọ̀rọ̀ kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àwọn àbá kan rèé tí ó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́:

  1. Lákọ̀ọ́kọ́ gbàdúrà - béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run pé kó fi ara rẹ̀ hàn ọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ń kà
  2. Jẹ́ kí èrò rẹ báramu - máa kà Bíbélì, kó o sì máa ṣe ìwádìí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́
  3. Jẹ́ ẹni tó máa ń ṣe nǹkan láìgbèròtẹ́lẹ̀ - máa wá àyè láti ṣí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
  4. Lo àkókò díẹ̀ sí i - bí o bá ṣe túbọ̀ ń lo àkókò pẹ̀lú Ọlọ́run nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni wàá ṣe máa túbọ̀ fẹ́
  5. Ìwé ìròyìn - kọ àwọn kókó tó o máa ronú lé lórí àti àdúrà tó o máa gbà lọ́jọ́ náà sílẹ̀
  6. Ṣàṣàrò - jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà wà nínú rẹ ní gbogbo ọjọ́ náà
  7. Lo oríṣiríṣi áwọn ohun èlò tí a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì - èyí á ràn wá lọ́wọ́ láti tú òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jáde

IẸ̀yin yóò wá mi, bí ẹ̀yin bá sì fi gbogbo ọkàn yín wá mi (Jeremáyà29:13).

‘Má ṣe wá ìrírí, ṣùgbọ́n wá, wá láti mọ̀ ọ́n, wá láti mọwiwa nihin in Rẹ,wá láti nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀. Wá lati kú si ara rẹ ati ohun gbogbo miiran, kí o lè wà láàyè ní kíkún nínú Rẹ̀ àti fún un kí o sì fi ara rẹ fún un pátápátá. Bí Ó bá wà ní àárín, wà a wà ní ààbò.' - David Martyn Lloyd-Jones

Nípa Ìpèsè yìí

ONE THING

A máa ri ohun tí ó túnmọ̀ sí láti gbé fún Jésù nínú ayé tí kò ní àfojúsùn. Ayé yìí n sáré, a sì ní ìròyìn ní àtẹ́lẹwọ́ wa ju bí a ṣe nílo lọ. Njẹ́ ìwà ayé tuntun yìí rèé? Báwo ni a ṣe lè rìn jẹ́jẹ́ ní ayé tí ó ń sáré yìí? Sáàmù 27:4 ní ìdáhùn – OHÙN KAN, pẹ̀lú Ps Andrew Cartledge.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Harvest Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://www.harvestchurch.org.au/onething