OHUN KANÀpẹrẹ

Sáàmù 27:4 Ṣe àkójọ àwọn kókó pàtàkì kan tí ó máa ràn wá lọ́wọ́ nígbèésí ayé wa, èyí tí ó máa jẹ́ ká lè máa ṣe nǹkan ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ayé tí ó ń yára kánkán yìí.
Ohun àkọ́kọ́ ni pé ka BÉÈRÈ.
BÁWO la ṣe máa béèrè?
LỌ́WỌ́ ta la tí lè BÉÈRÈ?
KÍNÍ ó yẹ kí á BÉÈRÈ fún?
Mo gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ń gbọ́ àdúrà wa, gbogbo wọn. Kì í fí ìgbà gbogbo dáhùn wọn lọ́nà tá a fẹ́. Nígbà míì, a máa ń ṣi àdúrà gbà. Àdúrà onímọtara-ẹni-nìkan la máa ń gbà tí wọn ò sì ní ète ayérayé kankan.
NT Wright sọ wí pé: 'Ṣùgbọ́n, fún èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wa, ìṣòro náà kì í ṣe pé a ti ń hára gàgà láti béèrè àwọn nǹkan tí kò tọ́. Ìṣòro náà ni pé a ò fi gbogbo ara béèrè ohun tó tọ́.'
Bíbélì fi kọ́ wa, ó sì tẹnu mọ́ pé, kí á máa BÉÈRÈ.
Ìwé Ẹ́sítérì sọ ìtàn nípa bí wọ́n ṣe fi ìgboyà béèrè ohun kan . Ayaba kan wọ yàrá ìtẹ́ ọba láìgbàṣẹ. Ṣùgbọ́n ó wọlé. Ọba náà kò fi ojú rere hàn sí i nìkan, ó tún fún un ní ohun tó béèrè.
A gbọ́dọ̀ kọ bí á ṣe lè gbàdúrà sí Ọlọ́run. Ìgboyà, ẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, a mọ̀ pé ilé Ọlọ́run ni, kì í ṣe tiwa, a sì mọ àwọn òfin tó yẹ ká tẹ̀ lé. Ohun tá a máa kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí á jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè gbàdúrà sí Ọlọ́run:
SÚN MỌ́ -Ẹ wá síwájú rẹ̀
JẸ́WỌ́ - Mú ọkàn rẹ mọ́, kó o sì tọrọ ìdáríjì
DÁRÍJÌ -Àwọn mìíràn
ÌJỌSÌN - Máa lo àkókò rẹ láti máa yin orúkọ Rẹ̀ lógo kó o sì máa gbé e ga (ìyìn, ijuba, ìdúpẹ́)
BÉÈRÈ - Ète Ìjọba Náà ('Kí ìjọba Re dé')
BÉÈRÈ - Ìdàgbàsókè Ara Ẹni ('Yọ́ mí bí a ti yọ́ wúrà')
ṢALAGBÀWÍ - Ìtọrọ, àìní, ìdílé, àwọn aṣáájú, àwọn àlùfáà, àwùjọ, àti àwọn ìbéèrè pàtó
ṢÀṢÀRÒ - Nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
ÌDÚPẸ́ - Yin Ọlọ́run fún gbogbo ohun tó ti ṣe àtàwọn ohun tó ṣì máa ṣe
Èyí jẹ́ ọ̀nà tó dára gan-an láti sún mọ́ Ọlọ́run, nítorí pé ó fi hàn pé Ọlọ́run ṣe pàtàkì ju ohun tá a béèrè lọ.
Lára àwọn ohun tá a lè béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run:
-Àwọn Orílẹ̀-Èdè
- Ọgbọ́n
- Ìwòsàn
- Ìdáríjì
- Ìdáǹdè
-Òmìnira nínú àníyàn
- Ìfẹ́ Ọlọ́run ni kí o ṣe
Edward Marbury sọ wí pé, 'Éni kan kò lè ní ìgbàgbọ́ láì béèrè, bẹ́ẹ̀ ni kò lè béèrè fún un láìní ìgbàgbọ́.'
Àdúrà tí a kò bá gbà kò lè gba ìdáhùn.
Kí ni a ń béèrè lọ́wọ́ Olúwa? nítorí pẹ́ ó YẸ ká béèrè.
Nípa Ìpèsè yìí

A máa ri ohun tí ó túnmọ̀ sí láti gbé fún Jésù nínú ayé tí kò ní àfojúsùn. Ayé yìí n sáré, a sì ní ìròyìn ní àtẹ́lẹwọ́ wa ju bí a ṣe nílo lọ. Njẹ́ ìwà ayé tuntun yìí rèé? Báwo ni a ṣe lè rìn jẹ́jẹ́ ní ayé tí ó ń sáré yìí? Sáàmù 27:4 ní ìdáhùn – OHÙN KAN, pẹ̀lú Ps Andrew Cartledge.
More