OHUN KANÀpẹrẹ

Èròjà míràn tí a rí nínú Orin Dáfídì 27:4 ni ọ̀rọ̀ náà GBÉ.
Kí àwa kí ó gbé nínú ilé Olúwa ní ọjọ́ ayé wa gbogbo.
Àti dúró ní iwájú Rẹ̀ jẹ́ ohun èlò tó ṣe iyebíye, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà ǹjẹ́ a tilẹ̀ fi àyè sílẹ̀ láti gbé nínú Rẹ̀?
Ọ̀rọ̀ náà tí a pé ní gbé ní àwọn ìtumọ̀ bíi mélòó kan tí ó dá yàtọ̀. Àkọ́kọ́ ni láti jókòó. Ó túmọ̀ sí dídá ọwọ́ ohun tí à ńṣe dúró, gbogbo ìsáré sókè sódò, kí a sì jókòó ní ìdákẹ́ rọ́rọ́.
Ìtumọ̀ míràn tí ó ní kìíṣe nípa ká má dúró die, bí kò ṣe dídúró. Mo fẹ́ràn ìtàn Jóṣúà nínú Ẹ́kísódù 33:11, nígbà tí Ọlọ́run ń bá Mósè sọ̀rọ̀ nínú àgọ́, àti lẹ́yìn ìgbà tí Mósè ti kúrò láti padà lọ sí ibùdó, Jóṣúà kò ní fi àgọ́ sílẹ̀. Ó dúró síbẹ̀.
Ní bákan náà 'gbé' túmọ̀ sí dídúró, nínú ìsinmi, àti fífi ara balẹ̀, fífi ibì kan ṣe ibùgbé rẹ. Orin Dáfídì 27:4 sọ wípé 'kí èmi lè gbé ní ilé Olúwa...'
Ìfẹ́ Ọba Dáfídì ni láti fi ilé Olúwa ṣe ibùgbé rẹ̀.
Kíni ǹkan tí ọkàn wa fẹ́? Ṣé láti gbé pẹ̀lú Kristi ni?
Gẹ́gẹ́bí onígbàgbọ́, a sì ní àwọn àṣàyàn láti ṣe nípa ohun tí a yàn ní ààyò ní ìgbé ayé wa. Àmọ́ òtítọ́ náà dúró ṣinṣin: bí a ti ń fi Ọlọ́run, Ilé Rẹ̀, àti Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ṣe ohun tí a yàn ní ààyò, kò ní sí àyè fún ibi àti Ẹ̀ṣẹ̀ láti jọba ní ayé wa.
Charles Spurgeon sọ wípé, 'A kò tíì rí ìwòsàn fún ìfẹ́ ibi nínú ìgbésí ayé Kristẹni bíi ìdàpọ̀ ìgbà-dé-ìgbà pẹ̀lú Jésù Olúwa. Fi ìgbà gbogbo gbé pẹ̀lú rẹ̀, yóò sì nira fún ọ láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀.'
Bẹ̀rẹ̀ lónìí láti máa fi àkókò rẹ pẹ̀lú Rẹ̀ ṣe ààyò kí o bàa lè máa gbé ní iwájú Rẹ̀.
Bí a ti ń tẹ̀síwájú láti lépa OHUN KAN, à ń wo àwọn ǹkan tó ràn wá lọ́wọ́ láti ní àfojúsùn tí ó papọ̀ sójú kan.
Èròjà míràn tí a rí nínú Orin Dáfídì 27:4 ni ọ̀rọ̀ náà GBÉ.
Kí àwa kí ó gbé nínú ilé Olúwa ní ọjọ́ ayé wa gbogbo.
Àti dúró ní iwájú Rẹ̀ jẹ́ ohun èlò tó ṣe iyebíye, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà ǹjẹ́ a tilẹ̀ fi àyè sílẹ̀ láti gbé nínú Rẹ̀?
Ọ̀rọ̀ náà gbé ní àwọn ìtumọ̀ bíi mélòó kan tí ó dá yàtọ̀. Àkọ́kọ́ ni láti jókòó. Ó túmọ̀ sí dídá ọwọ́ ohun tí à ńṣe dúró, gbogbo ìsáré sókè sódò, kí a sì jókòó ní ìdákẹ́ rọ́rọ́.
Ìtumọ̀ míràn tí ó ní kìíṣe nípa má ro'sẹ̀, bí kò ṣe dídúró. Mo fẹ́ràn ìtàn Jóṣúà nínú Ẹ́kísódù 33:11, nígbà tí Ọlọ́run ń bá Mósè sọ̀rọ̀ nínú àgọ́, àti lẹ́yìn ìgbà tí Mósè ti kúrò láti padà lọ sí ibùdó, Jóṣúà kò ní fi àgọ́ sílẹ̀. Ó dúró síbẹ̀.
Ní bákan náà 'gbé' túmọ̀ sí dídúró, níní ìsinmi, àti fífi ara balẹ̀, fífi ibì kan ṣe ibùgbé rẹ. Orin Dáfídì 27:4 sọ wípé 'kí èmi lè gbé ní ilé Olúwa...'
Ìfẹ́ Ọba Dáfídì ni láti fi ilé Olúwa ṣe ibùgbé rẹ̀.
Kíni ǹkan tí àwa fẹ́? Ṣé láti gbé pẹ̀lú Kristi ni?
Gẹ́gẹ́bí onígbàgbọ́, a sì ní àwọn àṣàyàn láti ṣe nípa àfojúsùn ayé wa. Àmọ́ òtítọ́ náà dúró ṣinṣin: bí a ti ń fi Ọlọ́run, Ilé Rẹ̀, àti Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ṣe àfojúsùn wa, bẹ́ẹ̀ni gbòǹgbò ibi àti ẹ̀ṣẹ̀ yóò máa dínkù nínú ayé wa.
Charles Spurgeon sọ wípé, 'A kò tíì rí ọ̀nà-àbáyọ tó pójú owó kúrò nínú ìfẹ́ ibi nínú ìgbésí ayé Kristẹni bíi ìdàpọ̀ ìgbà-dé-ìgbà pẹ̀lú Jésù Olúwa. Fi ìgbà gbogbo gbé pẹ̀lú rẹ̀, yóò sì nira fún ọ láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀.'
Bẹ̀rẹ̀ lónìí láti máa fi àkókò rẹ pẹ̀lú Rẹ̀ ṣe àfojúsùn kí o bàa lè máa gbé ní iwájú rẹ.
Nípa Ìpèsè yìí

A máa ri ohun tí ó túnmọ̀ sí láti gbé fún Jésù nínú ayé tí kò ní àfojúsùn. Ayé yìí n sáré, a sì ní ìròyìn ní àtẹ́lẹwọ́ wa ju bí a ṣe nílo lọ. Njẹ́ ìwà ayé tuntun yìí rèé? Báwo ni a ṣe lè rìn jẹ́jẹ́ ní ayé tí ó ń sáré yìí? Sáàmù 27:4 ní ìdáhùn – OHÙN KAN, pẹ̀lú Ps Andrew Cartledge.
More