OHUN KANÀpẹrẹ

Orin Dáfídì 27:4 ṣe ìtọ́kasí àwọn ìgbésẹ̀ àti ẹ̀bẹ̀ Ọba Dáfídì sì Ọlọ́run. Ọ̀kan nínú àwọn ànfàní tí ó ń lépa ni lati TẸJÚMỌ́ ẹwà Olúwa.
Ní àkókò kan, èmi àti ẹbí mi lọ sí ilé ọnà àti iṣẹ̀mbáyé ni orílẹ̀ èdè Ọstirélia. A rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun àfihàn tí wọ́n kó sí orí àtẹ, ohun tí a fi ọ̀dà ṣe ní ọ̀sọ́ àti àwọn iṣẹ́ ọnà, ṣùgbọ́n ohun kan gbòógì ni mo fẹ́ láti rí. Ohun náà ni Òdòdó Orí Omi láti ọwọ́ Claude Monet. Mo gbìyànjú láti fún ara mi ní àsìkò díẹ̀ láti dúró ní iwájú ohun tí a fi ọ̀dà ṣe ní ọ̀ṣọ́ yí, èmi nìkan, fún ìṣẹ́jú 10-15. Mo kàn tẹ ojú mọ sáá. Ó jẹ́ iṣẹ́ ọnà tí ó ní ẹwà ní òtítọ́.
Ṣùgbọ́n ẹwà Olúwa ju èyí lọ!
A mọ èyí ṣùgbọ́n ní ìgbà púpọ̀ ni a máà ń gbá àwọn nǹkan láyè láti sú ojú inú wa àti láti dí wa ní ojú. Ní ìgbà míràn ẹ̀wẹ̀ ojú ara nìkan ni a máà fi ń wo nǹkan dípò kí a fí ojú ìgbàgbọ́ wò ó. Ábúráhámù àti Lọti pẹ̀lú ní irú ìrírí yí.
Lọti fi ojú lásán wo nǹkan tí ó tẹ lọ́rùn nípa ohun tí a fí ojú ara wo, ó sì yàn etí ipa odò. Ṣùgbọ́n Ábúráhámù rí ju èyí lọ. Ó fi ojú ìgbàgbọ́ rí ohun tí ojú lásán kò lè rí.
Ojú mi kò dà bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Bí mo ṣe ń d'àgbà síi ni ojú náà ṣe ń díbàjẹ́ si. Ṣùgbọ́n kí n le ríran kedere, mo ní láti lo ìgò. Àwọn ìgò tí a fi ń wo ibi tí kò jìnà wá bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí a fi ń wo ibi tí ó jìnà réré. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó ṣe rí nípa ojú ẹ̀mí.
A ní láti ló ìgò tí ó wà ní ìbámu láti ríran kedere.
ÌGÒ 5 tí a ní láti ló fún ìríran wa:
ÒTÍTỌ́ - Ìwòye Ìwé Mímọ́
Bí a ṣe ń ka Ìwé Mímọ́ síi ni a óò máà ní ìmọ̀ síi. Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ sí ọkàn, kí n má baà ṣẹ̀ ọ́.
ÌWÀLÁÀYÈ - Ìwòye Ìsìn
Bí a ṣe ń fi ìyìn fún-un, bẹ́ẹ̀ ni ojú wa yíò máa là sí ògo rẹ̀. A dá wa láti máa sin Ọlọ́run. Ìgbé ayé wa ń ṣàn jáde nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀
ADURA - Ìwòye Ìbáṣepọ̀
Ní ìgbà tí a bá súnmọ́ kan ni a óò ní ojú ìwòye tí ó yàtọ̀ sí ti ẹni tí ó gbọ́ nípa wọn nìkan. Ìbáṣepọ̀ wá, pàápàá pẹ̀lú Bàbá wa tí mbẹ ní ọ̀run, wáyé nípa fífi Òun ṣe ààyò.
ÀÀYÒ - Ìwòye Àsìkò
Ọ̀nà tí a gbà lo àkókò wá ń ṣe àfihàn bí nǹkan tí à ń ṣe ti ṣe pàtàkì sí. Ǹjẹ́ o fẹ́ dúró láti TẸJÚMỌ́ ẹwà Jésù bí?
ÌGBÀGBỌ́ - Ìwòye Ìgbẹ́kẹ̀lé
Àpapọ̀ èyí padà sí bí a ṣe rí Ọlọ́run. Ǹjẹ́ a ní ìgbẹ́kẹ̀lé síi pátápátá?
Àwọn ìwòye 5 wọ̀nyí ni wọ́n ràn wá lọ́wọ́ láti rí àti láti TẸJÚMỌ́ ẹwà Olúwa wa. Mímú ìdíwọ́ kúrò. Fífi OHÙN KAN náà ṣe pàtàkì jù lọ.
Charles Spurgeon sọ báyìí pé, 'Mo fẹ́ràn, ní ìgbà míràn, láti fi àdúrà sílẹ̀, kí n sì jókòó jẹ́ẹ́, kí ń sì tẹjúmọ́ òkè títí ọkàn mi yíò rí Olúwa mi'
Nípa Ìpèsè yìí

A máa ri ohun tí ó túnmọ̀ sí láti gbé fún Jésù nínú ayé tí kò ní àfojúsùn. Ayé yìí n sáré, a sì ní ìròyìn ní àtẹ́lẹwọ́ wa ju bí a ṣe nílo lọ. Njẹ́ ìwà ayé tuntun yìí rèé? Báwo ni a ṣe lè rìn jẹ́jẹ́ ní ayé tí ó ń sáré yìí? Sáàmù 27:4 ní ìdáhùn – OHÙN KAN, pẹ̀lú Ps Andrew Cartledge.
More