Gbígbé Ìgbésí Ayé Rẹ Ní Ìbámu Pẹ̀lú Bíbá Ọlọ́run PàdéÀpẹrẹ

Gbígbé Nínú Ìṣọ̀kan
Ọ̀kan nínú àwọn èròǹgbà tí ó ṣòro jùlọ látí yé ènìyàn nípa ìgbàgbọ́ àwa Kristiani ni pé Ọlọ́run, nínú gbogbo ìwà mimọ́ àti ìfẹ́ Rẹ̀, yóò gbé inú ọkàn ènìyàn. Ẹ̀jẹ̀ Jésù ti mú ìwọ àti èmi wá sínú ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Kò sì sí ohun tí ó lè yà wá kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ mọ́. Ó sún mọ́ wa ju èémí imú wa lọ. Ó jẹ́ àrídájú fún wa ju ilẹ̀ tí ó wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ wa lọ.
Májẹ̀mú Tuntun kún fún òtítọ́ nípa ìrẹ́pọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run. Gálátíà 2:20 sọ pé, “A ti kàn mí mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú Kristi, èmí kò sì wà láààyè mọ́, ṣùgbọ́n Kristi ń gbé inú mi, wíwà tí mo sì wà láààyè nínú ara, mo wà láààyè nínú ìgbàgbọ́ ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí ó fẹ́ mi, tí ó sì fi òun tìkára rẹ̀ fún mi." 1 Kọ́ríńtì 6:19-20 so wípé, "Tàbí, ẹ̀yin kò mọ̀ pé ara yín ni tẹmpili Ẹ̀mí Mímọ́, tí ń bẹ nínú yín, tí ẹ̀yin ti gbà ní ọwọ́ Ọlọ́run? Ẹ̀yin kì í ṣe ti ara yín, nítorí a ti rà yín ní iye kan; Nítorí náà ẹ yìn Ọlọ́run l'ógo nínú ara yín, àti nínú ẹ̀mí yín, tì í ṣe ti Ọlọ́run."
Róòmù 6:4 sọ wípé,"Nítorí náà, a sin wá pẹ̀lú Kristi nípa ìtẹ̀bọmi si ikú, kí ó bá le jẹ́ pe bí a ti jí Kristi dìde pẹ̀lú ògo Baba, àwa pẹ̀lú gbé ìgbé ayé tuntun."
Àti ìwé sì àwọn ara Kólósè 1:27 sọ pe,"Àwọn ẹni tí Ọlọ́run yàn láti fi hàn ní àárín àwọn aláìkọlà nípa ọ̀rọ̀ ògo ohun ìjìnlẹ̀ yìí, èyí tí í ṣe Kristi ìrètí ògo nínú yín."Kò sí àkókò kan tí o yapa kúrò ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ọlọ́run wá nínú rẹ àti pẹ̀lú rẹ nípasẹ̀ gbogbo ìdánwò, àṣeyọrí, ìṣẹ́gun, àti ìjákulẹ̀ pẹ̀lú. O wà fún ọ àti pé o wà síbẹ̀ fún ọ ní gbogbo ọjọ́, àti ní ojoojúmọ́. Àti pàápàá nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, Ọlọ́run kò yẹ'sẹ̀ rárá. Pàápàá jùlọ nínú ìṣọ̀tẹ̀ wá, Ọlọ́run ń gbé inú wa. Ohun tí ó kù fún wa láti ṣe ni láti kọ̀ ẹ̀kọ́ bí a ṣe lè jẹ́ kí ìṣọ̀kan yí gba gbogbo àyíkáyídà ìgbésí ayé wa. Láti ṣiṣẹ́ ìgbàlà wa já sí wípé ó ní láti kọ ẹ̀kọ́ láti jọ̀wọ́ ohun tí ó jẹ́ ara wa tẹ́lẹ̀ sílẹ̀ kí o sì gbé ìgbé ayé ìdánimọ̀ tuntun gẹ́gẹ́ bíi ara kan pẹ̀lú Krístì fún ra rẹ̀.
Tí ó bá jẹ́ ní òdodo ni a fẹ́ kí ìgbé ayé wa dúró ní àárín ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, ó di dandan fún wa láti kọ́ ẹ̀kọ́ láti jẹ́wọ́ wípé òun ti wà pẹ̀lú wá tẹ́lẹ̀ rí. Òun kì í ṣe Ọlọ́run tí ó jìnnà réré ti ó ní láti rin ìrìn-àjò láti orí ìtẹ́ Rẹ̀ ni ọrun sọ̀kalẹ̀ sì ọ̀dọ̀ wa nígbàkúùgbà tí a bá gbà l'áàyè. Òun kì í ṣe Ọlọ́run tí ó ń gbé ní àwọn ilé ìjọsìn nìkan, àwọn àjọṣepò àwọn olùjọsìn, àwọn iṣẹ ìránṣẹ́, tàbí àwọn àlùfáà. Òun ni Ọlọ́run tí ó ń gbé inú rẹ, tí ó ní ìfẹ́ rẹ, tí ó fẹ́ràn rẹ, tí ó sì ń fẹ́ láti wá pẹ̀lú rẹ ní ìrẹ́pọ̀ ní gbogbo ìgbà.
Wá ààyè díè ní òní láti ṣe àtúnṣe àyà rẹ kí o lè di ọ̀tun sí òtítọ́ ìṣọ̀kan rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run. Béèrè l'ọ́wọ́ rẹ̀ kí ó fi ítòsí rẹ̀ hàn sí ọ kí ìwọ lè “rìn ní ayé ọ̀tún” ní òní Róòmù 6:4. Wá ààyè nínú ọkàn àti àyà rẹ láti jẹ́ kí ìwàláàyè Ọlọ́run wọ gbogbo kọ̀rọ̀kọ̀ńdù ìgbésí ayé rẹ. Jẹ́ kí ọjọ́ òní ṣe ààmì sí ìyípadà ńlá nínú ìgbésí ayé rẹ bí Ọlọ́run tìkára rẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ láti ṣiṣẹ́, bùkún, àti dá sí ohun gbogbo tí ò ń ṣe.
Àdúrà
1. Ṣe àṣàrò l'órí ìrẹ́pọ̀ rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run. Ṣe àtúnṣe ọkàn rẹ nípa fífi ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ sì inú Ìwé Mímọ́ dípò àwọn ìmọ̀lára tàbí àwọn ìrírí tí ó ti ní s'ẹ́yìn."A ti kàn mí mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú Kristi, èmí kò sì wà láààyè mọ́, ṣùgbọ́n Kristi ń gbé inú mi, wíwà tí mo sì wà láààyè nínú ara, mo wà láààyè nínú ìgbàgbọ́ ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí o fẹ́ mi, tí ó sì fi òun tìkára rẹ̀ fún mi." Gálátíà 2:20
"Nítorí náà bí ẹnìkan bá wà nínú Kristi, ó di ẹ̀dá tuntun: ohun àtijọ́ ti kọjá lọ; kíyèsi i, ohun tuntun ti dé." Kọ́ríńtì keji 5:17
"Tàbí, ẹ̀yin kò mọ̀ pé ara yín ni tẹmpili Ẹ̀mí Mímọ́, tí ń bẹ nínú yín, tí ẹ̀yin ti gbà l'ọ́wọ́ Ọlọ́run? Ẹ̀yin kì í ṣe ti ara yín, nítorí a ti rà yín ní iye kan; Nítorí náà ẹ yìn Ọlọ́run lógo nínú ara yín, àti nínú ẹ̀mí yín, tì í ṣe ti Ọlọ́run." Kọ́ríńtì kini 6:19-20
2. Níbo ni ó kù sí ní ìgbésí ayé rẹ tí kò ní ìtọ́kasì ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́? Báwo ni ó se ń ṣe ìgbésí ayé rẹ bí ẹni pé Ọlọ́run kò wà pẹ̀lú rẹ? Níbo ni ó ti ń tiraka tí o sì n ṣiṣẹ́ fún ohun tí ó jẹ́ tìrẹ tẹ́lẹ̀ nínú Krístì Jésù?
3. Béèrè l'ọ́wọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ láti jẹ́ kí o mọ bí òun ṣe sún mọ́ ọ tó. Béèrè l'ọ́wọ́ rẹ̀ láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti jẹ́ kí ó jẹ́ ẹnìkan tí ó ń rí gbà ní ìrọ̀rùn dípò ìtiraka àti ẹni tí ó ń sinmi yàtọ̀ sí àwọn tí ó ń ṣe làálàá lọ.
“Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé Èmi ni Ọlọ́run" Orin Dáfídì 46:10
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ohun tí ó jẹ́ gbòógì ní ayé yìí ni láti yan ohun kan: taani tàbí kíni a óò gbé ìgbésí ayé wa lé lórí? Ohun tí a yàn yí á mú kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe àwọn ìpinnu tí yíó tọ́ka irú ẹni tí a ó jẹ́, bí nǹkan ṣe ń rí ní ara wa, àwọn ẹni tàbí ohun tí a kà sí pàtàkì àti àwọn ohun tí a ó ti gbéṣe níkẹyìn ọjọ́ wa. Tí a bá fi ara wa nìkan ṣoo ṣe kókó tàbí àwọn ohun ti ayé yìí kò ní í da ohunkóhun fún wa ju ìparun lọ.
More