Gbígbé Ìgbésí Ayé Rẹ Ní Ìbámu Pẹ̀lú Bíbá Ọlọ́run PàdéÀpẹrẹ

Centering Your Life Around Meeting With God

Ọjọ́ 2 nínú 7

Ìpòǹgbẹ Ọlọ́run Láti Bá Ọ Pàdé

Mo máa ń wo àkókò ìkọ̀kọ̀ mi pẹ̀lú Bàbá mi ọ̀run gẹ́gẹ́ bí i ohun tí mo ní láti wá k'órí yá fún ara mi kí n tó ṣe é. Mo máa ń wo òye pé Ọlọ́run ń dúró dè mí nínú yàrá kan, pé ó ti múra tán láti bùkún mi, ṣúgbọ́n èrò mi ni wípé ẹrù wúwo ti ojúṣe láti yàn-án wà ní orí mi. Òtítọ́ nípa ọkàn Ọlọ́run jìnnà sí àwọn èrò òdì yìí tí mo ní tẹ́lẹ̀.

A ń sin Ọlọ́run tí ó ń fi gbogbo ìgbà, tìfẹ́tìfẹ́ àti gbogbo agbára lépa wa ní ìgbà gbogbo.

Ìfihàn 3:20 sọ wípé,“Kíyèsi, mo dúró mí ẹnu ìlẹ̀kùn, mo sì ń kànkùn, bí ẹnikẹ́ni ba gbọ́ ohùn mi, tí ó sì ṣí ìlẹ̀kùn, Èmi yíó sì wọlé tọ̀ ọ́ wá, Èmi yíó sì máa bá a jẹun, àti òun pẹ̀lú mi.”

Ọlọ́run ń kan ìlẹ̀kùn ọkàn rẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. Ọlọ́run ń fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí ọ nínú gbogbo afẹ́fẹ́ tútù tí ó ń fẹ́ sí ọ l'ójú, ní gbogbo ìgbà tí oòrùn bá yọ, àti pẹ̀lú gbogbo ìràwọ̀ tí ó ń tàn yòò ní ojú ọ̀run.

Gbogbo ọ̀nà ni Ọlọ́run ń gbà láti lépa wá. Ohun tí ó wù ú jùlọ ni ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Rẹ̀. Nítorí náà, nínú mímọ̀ àti gbígba bí ìfẹ́ Rẹ̀ sí wa ṣe jinlẹ̀ tó, ni ọkàn wa yíó ti ru s'ókè láti bá a pàdé. Bí a bá wá ààyè láti kíyèsí pé ó ń wá wa kiri ní ìgbà gbogbo, a óò bẹ̀rẹ̀ síi fi ìpàdé pẹ̀lú Bàbá wa ọ̀run ṣe olórí ohun tí à ń lépa ní ìgbésí ayé wa.

Ó yẹ kí ìbápàdé pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ wá l'ógún ní ìgbésí ayé wa nítorí pé ní oókan-àyà rẹ̀ ní ìfẹ́ ńlá aláìlẹ́gbẹ́ láti bá wa pàdé wà. Ó wu Ẹlẹ́dàá ayé àti ọ̀run gan-an pé kí ó máa bá ọ pàdé déédéé. Ọlọ́run, ẹni tí ó jẹ́ Olódùmarè, tí ó mọ ohun gbogbo, tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́, tí ó sì jẹ́ ìmúṣẹ ìfẹ́ pípé, ń fẹ́ kí o mọ Òun. A dá wa ní ọ̀nà tí ó jẹ́ pé ìfẹ́ Ẹlẹ́dàá wa yíó fà wá m'ọ́ra. A dá wa kí a lè mọ̀ wá, kí àwa náa sì lè mọ Bàbá wa ọ̀run. A dá wa kí a lè máa bá a rìn ní gbogbo ìgbà. Kìí ṣe pé “ó yẹ” kí a dá ayé wa lé orí bíbá Ọlọ́run pàdé; a dá wa láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni, a sì gbọ́dọ̀ ṣe é.

Orin Sólómọ́nì 7:10 sọ wípé,“Ti olùfẹ́ mi ni èmi ń ṣe, ìfẹ́ rẹ̀ si ń bẹ sí mi.”Mo gbà á ní àdúrà pé kí o d'àgbà nínú ìmọ̀ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún ọ ní òní. Kí o mọ ara rẹ gẹ́gẹ́ bí i “olúfẹ̀ẹ́ mi.”Kí ayé rẹ jẹ́ ìfihàn ìdáhùn rẹ sí ìlépa Ẹlẹ́dàá rẹ fún ọ. Kí ayé rẹ dá lé orí bíbá Ọlọ́run pàdé, kì í ṣe nítorí pé ó pọn dandan fún ọ, bí kò ṣe nítorí pé ó ń pòǹgbẹ gidigidi láti bá ọ pàdé.

Àdúrà

1. Ṣe àṣàrò l'óri ìfẹ́ Ọlọ́run láti bá ọ pàdé.

“Kíyèsi, mo dúró mí ẹnu ìlẹ̀kùn, mo sì ń kànkùn, bí ẹnikẹ́ni ba gbọ́ ohùn mi, tí ó sì ṣí ìlẹ̀kùn, Èmi yíó sì wọlé tọ̀ ọ́ wá, Èmi yíó sì máa bá a jẹun, àti òun pẹ̀lú mi.” Ìfihàn 3:20

“Kìí ṣe ẹ̀yin ni ó yàn mi, ṣùgbọ́n Èmi ni ó yàn yín.” Jòhánù 15:16

2. Kíni ó túmọ̀ sí fún ìgbésí ayé rẹ pé Ẹlẹ́dàá rẹ onífẹ̀ẹ́ ń lépa rẹ ní ìgbà gbogbo? Báwo ni yíó ṣe rí bí a bá ń gbé ìgbé ayé tí ó ń dáhùn sí ìfẹ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà?

3. Wá àsìkò láti bá Ọlọ́run pàdé. Béèrè l'ọ́wọ́ rẹ̀ bí èrò rẹ̀ ṣe rí sí ọ. Béèrè pé kí ó fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn fún ọ. Ìwọ náa fi ìfẹ́ rẹ hàn sí i ní ìdáhùn sí ìfẹ́ tirẹ̀. Sọ ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ fún-un láì fi ọ̀rọ̀ sí abẹ́ ahọ́n sọ.

“Ti olùfẹ́ mi ni èmi ń ṣe, ìfẹ́ rẹ̀ si ń bẹ sí mi.” Orin Sólómọ́nì 7:10

“Ọlọ́run, èrò inú rẹ ti ṣe iyebíye tó fún mi! Iye wọn ti pọ̀ tó! Èmi ìbá kà wọ́n, wọ́n ju iyanrìn lọ ni iye: ní ìgbà ti mo bá jí, èmi wà ní ọ̀dọ̀ rẹ síbẹ̀.” Sáàmù 139:17-18

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Centering Your Life Around Meeting With God

Ohun tí ó jẹ́ gbòógì ní ayé yìí ni láti yan ohun kan: taani tàbí kíni a óò gbé ìgbésí ayé wa lé lórí? Ohun tí a yàn yí á mú kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe àwọn ìpinnu tí yíó tọ́ka irú ẹni tí a ó jẹ́, bí nǹkan ṣe ń rí ní ara wa, àwọn ẹni tàbí ohun tí a kà sí pàtàkì àti àwọn ohun tí a ó ti gbéṣe níkẹyìn ọjọ́ wa. Tí a bá fi ara wa nìkan ṣoo ṣe kókó tàbí àwọn ohun ti ayé yìí kò ní í da ohunkóhun fún wa ju ìparun lọ.

More

A fẹ́ dúpẹ́ l'ọ́wọ́ First15 fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí: https://www.first15.org/