Gbígbé Ìgbésí Ayé Rẹ Ní Ìbámu Pẹ̀lú Bíbá Ọlọ́run PàdéÀpẹrẹ

Centering Your Life Around Meeting With God

Ọjọ́ 6 nínú 7

Lílo Àkókò Wa Ní Ọ̀nà Tí ó Dára Jù Lọ

Éfésù 5:15-16 kìlọ̀ fún wa pé, "Ẹ máa ṣọ́ra ní ojú méjèèjì bí ẹ ti ń rìn, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bíi aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bíi ọlọ́gbọ́n, ní ríra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín nítorí pé àwọn ọjọ́ burú.Àkókò wa ṣe pàtàkì gan-an níhìn-ín ní orí ilẹ̀ ayé. A kò tún ní rí àwọn ọjọ́ tí a fi ń lépa àwọn nǹkan ayé láì ní ìdí gbà mọ́ láé. A kò ní rí àkókò tí a lò ní ìta láti gba àti fún ni ní ìfẹ́ láti ọwọ́ Ọlọ́run padà. Àkókò tí a ní níhìn-ín kò tó nǹkan, ó sì ṣe pàtàkì gan-an dé'bi pé a kò lè lò ó fún àwọn ẹrù ìnira, àníyàn, ẹ̀ṣẹ̀, àti àwọn nǹkan ayé. Bí a bá fẹ́ lo ìgbésí ayé yìí dé ibi tí ó dára jù lọ, a gbọ́dọ̀ kọ́ láti máa lo àkókò wa fún àǹfààní ayérayé tí ó wà nínú bíbá Ọlọ́run pàdé. Ìdí nìyí tí Jakọbu 4:13-15 fi sọ pé,

Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sọ pé, "Ní òní tàbí ọ̀la a yíò lọ sí ìlú kan, a yíò sì lo ọdún kan níbẹ̀, a yíò ta ọjà, a yíò sì jèrè", ẹ má mọ ohun tí yíò ṣẹlẹ̀ sí yín lọ́la. Kí ni ìgbésí ayé rẹ? Nítorí ẹ̀yin jẹ́ ìkùukùu tí ń fi ara hàn fún ìgbà díẹ̀, tí ó sì wá pòórá l'ẹ́yìn náà. Nítorí náà, ohun tí ó yẹ kí ẹ sọ ni pé, "Bí Olúwa bá fẹ́, a yíò wà l'áàyè, a yíò sì ṣe èyí tabi èyí".

Ọ̀kan l'ára ọ̀nà tí ó dára jù lọ tí a lè gbà mọ ohun tí ó wà ní ọkàn wa ni pé kí a wo bí a ṣe ń lo àkókò wa. Tí a bá ń fi gbogbo àkókò wa ṣiṣẹ́ fún àwọn nǹkan ayé, tí a sì ń ronú nípa wọn, a lè mọ̀ pé a kò tíì ní òye tí ó péye nípa àwọn ète Ọlọ́run fún wa. Bí a bá ń lo èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú àkókò wa láti fi gbọ́ bùkátà ara wa, dípò tí a yíò fi máa wá ojú Baba wa ọ̀run kí a bàa lè ní ayọ̀ tí ó ń gbé ẹni ró, tí ó sì ju ti ẹ̀dá lọ, a lè mọ̀ pé a kò tíì fi gbogbo ìgbésí ayé wa fún Ọba wa.

Ohun tí ó dára jù lọ nípa bí àkókò ṣe rí ni pé ó jẹ́ tiwa láti ṣe ohun tí a bá fẹ́. A lè pinnu nísinsìnyí láti lo àkókò wa ní ọ̀nà tí ó dára jù lọ ní ibámu pẹ̀lú àwọn ète Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ṣí i payá fún wa nínú Ìwé Mímọ́. A lè pinnu nísinsìnyí pé a kò ní máa fi ìṣẹ́jú iyebíye ṣòfò lórí ohun tí kì í tọ́jọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, a yíò lo ọjọ́ ayé wa fún àwọn ète Baba wa ọ̀run tí ó wà pẹ́ títí, tí ó sì ń mu èso jáde.

Orin Dáfídì 90:12 sọ pé, "Kọ́ wa láti ka àwọn ọjọ́ wa kí a lè jèrè ọkàn-àyà ọgbọ́n."Ọlọ́run fẹ́ kí a mọ bí a ṣe lè lo ọjọ́ ayé wa ní ọ̀nà tí ó bá ọgbọ́n mu. Ó ń hára gàgà láti fún wa ní ọkàn-àyà ọgbọ́n kí a lè fi ìpàdé pẹ̀lú rẹ̀ ṣíwájú ní ìgbésí ayé wa. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ń gbé inú rẹ, ó sì ṣe tán láti tọ́ ẹ sí ọ̀nà kí o lè gbé ìgbésí ayé tí ó ní ìtumọ̀. Yan ní òní láti ṣí ọkàn àti èrò inú rẹ sí Olùkọ́ náà, ìyẹn Ẹ̀mí Ọlọ́run fúnra rẹ̀, kí o sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀. Ọba á jẹ́ kí o rí àlàáfíà, ayọ̀, àti ète nínú ọ̀nà tí o gbà ń lo àkókò rẹ ní òní.

Àdúrà

1. Máa ṣe àṣàrò l'órí bí ó ti ṣe pàtàkì tó láti máa lo àkókò rẹ ní ọ̀nà tí ó bá ọgbọ́n mu.

"Ẹ máa ṣọ́ra nígbà náà pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n, ní ríra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín nítorí pé àwọn ọjọ́ burú." Éfésù 5: 15-16

"Kọ́ wa láti ka àwọn ọjọ́ wa kí a lè jèrè ọkàn-àyà ọgbọ́n." Orin Dáfídì 90:12

2. Béèrè l'ọ́wọ́ Ẹmi Mimọ láti fi hàn ọ́ bi o ti n lo àkókò rẹ láì ní òye. Mọ̀ pé òun kìí ṣe Ọlọ́run tí ó gba ohun gbogbo tí ó gbádùn. Kò lòdì sí eré ìnàjú, àwọn ọ̀rẹ́, àti ayẹyẹ. Ọlọ́run aláyọ̀ ni, ó sì ní ìfẹ́ rẹ ní òtítọ́. Má ṣe da ìsìn pọ̀ mọ́ ọkàn Baba rẹ ọ̀run. Jẹ́ kí ó dá ọ l'ójú pé ìyípadà yòówù kí ó mú kí o ṣe, yóò yọrí sí ọ̀nà ìgbésí ayé tí ó gbádùn mọ́ni jù lọ, tí ó ń mú èso jáde jù lọ, tí ó sì ń tẹ́'ni l'ọ́rùn jù lọ.

"Wàyí o, ẹ̀yin tí ẹ ń sọ pé, 'Lónìí tàbí lọ́la a yíò lọ sí ìlú kan, a yíò sì lo ọdún kan níbẹ̀, a yíò ta ọjà, a yíò sì jèrè", ẹ kò mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí yín lọ́la. Báwo ni ìgbésí ayé rẹ ṣe rí? Nítorí ẹ̀yin jẹ́ ìkùukùu tí ń fi ara hàn fún ìgbà díẹ̀, tí ó sì wá pòórá l'ẹ́yìn náà. Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin kí ó wípé, Bí Olúwa bá fẹ́, a yíò sì yè, a yíò sì ṣe èyí tàbí èyí." Jakọbu 4:13-15

3. Gba àdúrà pé kí Ọlọ́run ràn ẹ́ l'ọ́wọ́ láti lo àkókò rẹ ní ọ̀nà tí ó bá ọgbọ́n mu ní òní. Bẹ Jèhófà pé kí ó ràn ẹ́ l'ọ́wọ́ kí o lè máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀ bí o ṣe ń lo àkókò rẹ.

"Síbẹ̀síbẹ̀, mo ń sọ òtítọ́ fún yín: Ó jẹ́ fún àǹfààní yín pé mo lọ; nítorí bí èmi kò bá lọ, olùrànlọ́wọ́ náà kì yíò wá sí ọ̀dọ̀ yín. Ṣùgbọ́n bí mo bá lọ, èmi yíò rán-an síi yín." Jòhánù 16:7

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Centering Your Life Around Meeting With God

Ohun tí ó jẹ́ gbòógì ní ayé yìí ni láti yan ohun kan: taani tàbí kíni a óò gbé ìgbésí ayé wa lé lórí? Ohun tí a yàn yí á mú kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe àwọn ìpinnu tí yíó tọ́ka irú ẹni tí a ó jẹ́, bí nǹkan ṣe ń rí ní ara wa, àwọn ẹni tàbí ohun tí a kà sí pàtàkì àti àwọn ohun tí a ó ti gbéṣe níkẹyìn ọjọ́ wa. Tí a bá fi ara wa nìkan ṣoo ṣe kókó tàbí àwọn ohun ti ayé yìí kò ní í da ohunkóhun fún wa ju ìparun lọ.

More

A fẹ́ dúpẹ́ l'ọ́wọ́ First15 fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí: https://www.first15.org/