Gbígbé Ìgbésí Ayé Rẹ Ní Ìbámu Pẹ̀lú Bíbá Ọlọ́run PàdéÀpẹrẹ

Centering Your Life Around Meeting With God

Ọjọ́ 3 nínú 7

Rírí Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ Bí i Bàbá Wa

Bí orúkọ kan bá wà fún Ọlọ́run tí ó ní agbára láti yí ayé onígbàgbọ́ padà ní ọ̀nà tí ó kàmàmà, òun ni pé a lè pe Ọlọ́run ní "Abba" tàbí "Bàbá.” Láti rí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí i Bàbá wa yí ohun gbogbo padà. Ní inú ìwé Brennan Manning, The Furious Longing of God, o bèèrè ìbéèrè pàtàkì àti alágbára kan:

Ǹjẹ́ ìsọwọ́ gba àdúrà rẹ jẹ́ èyí tí ó rọrùn, bí i ti ọmọdé, pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé aláìlẹ́gbẹ́, àti ìfaramọ́ni ti ọmọ kékeré tí ó ń rọra gun òkè lọ sí ibi eékún Bàbá? Ìfọ̀kànbalẹ̀ wípé bàbá kò bìkítà bí ọmọ náà bá sùn lọ, tí ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi ohun ìṣeré ṣe eré, tàbí tí ó tilẹ̀ ń bá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ nítorí pé bàbá náà mọ̀ pé ọmọ yìí ti yàn láti wà ní ọ̀dọ̀ òun ní àkókò náà? Ṣé irú ẹ̀mí tí ò ń fi ń gba àdúrà nìyìí?

Ní ìgbà tí mo kọ́kọ́ ka àwọn ìbéèrè wọ̀nyìí, èrò mi ni wípé, “Ó dájú pé kò lè rọrùn tó báyìí. Ó dájú pé èyí kò lè jẹ́ gbogbo ohun tí Ọlọ́run ń retí láti ọ̀dọ̀ mi." A ti sọ ìtumọ̀ jíjẹ́ ọmọ Bàbá rere nù, Bàbá tí ó sún mọ́ wa, tí ó sì ní ìfẹ́. A ti gbé àwọn àìdánilójú wa, èrò wa, àti ìrírí wa lé Ọlọ́run tí ìfẹ́ rẹ̀ ṣe é rí gbá mú. Kò sí ohun tí a lè ṣe tí yíó mú kí Ọlọ́run ní ìfẹ́ wa ju bí ó ṣe ti ní ìfẹ́ wa lọ. Kò sì sí ohun tí a lè ṣe tí yíó mú kí ìfẹ́ tí ó ní sí wa dín kù. Ọlọ́run ní ìfẹ́ wa nítorí pé ó ní ìfẹ́ wa. Ó ń gbádùn wa nítorí pé ó ń gbádùn wa. Ó fẹ́ wà pẹ̀lú wa nítorí irú ẹni tí ó jẹ́ nìyẹn, kì í ṣe nítorí pé a ṣe ohun tí yíó mú kí ó wù ú láti wà pẹ̀lú wa.

Jòhánù 3:16 sọ wípé,“Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́, tí Ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fún ni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ má baà ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”

Kódà ní ìgbà tí a ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ tí a sì jìnnà sí Ọlọ́run, ó ní ìfẹ́ wa dé ibi pé ó san ìdíyelé tí ó ga jùlọ láti fi gbà wá. Ìfẹ́ tí ó ní fún wa pọ̀ gan-an dé ibi pé Jésù fi ẹ̀mí ara rẹ̀ lé'lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i ètùtù fún àwọn ìṣìnà wa, àwọn àṣìṣe wa, àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa, àti àwọn àìpé wa. Bí Ọlọ́run bá ní ìfẹ́ wa ní àìní ìdí báyìí ní ìgbà náà l'ọ́hùún, ó ṣì ní ìfẹ́ wa láì kù sí ibì kan náà báyìí. Bí Ọlọ́run bá yàn wá ní ìgbà náà l'ọ́hùún, ó yàn wá náà ní ìsinsìnyí. Bí ó bá jẹ́ pé ọkàn rẹ̀ fà sí wa ní ìgbà náà l'ọ́hùún, ọkàn rẹ̀ fà sí wa náà ní ìsinsìnyí.

Bí a bá fẹ́ kí ìbápàdé pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ wá ní ọgún ní ìgbésí ayé wa, a gbọ́dọ̀ ní òye bí ìfẹ́ tí ó ní sí wa ṣe jinlẹ̀ tó. A gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ síí ní àjọṣe pẹ̀lú Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i Bàbá rere àti onífẹ̀ẹ́ jù ohun gbogbo lọ. A gbọ́dọ̀ pa gbogbo ìrònú pé ó ń bínú sí wa, pé ó jìnnà sí wa, pé kò ní ìfẹ́ wa, tàbí pé a kò wù ú tì sí ẹ̀gbẹ́ kan. Òǹfà ìfẹ́ wa sí ọ̀dọ̀ Bàbá wa ọ̀run wà nínú òdiwọ̀n bí a bá ṣe tẹ́ ọwọ́ gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí a sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìfẹ́ rẹ̀ fún wa. Wá àkókò ní òní láti gba ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ Ọlọ́run fún ọ. Jẹ́ kí ìfẹ́ tí o ní fún Ọlọ́run yí èrò rẹ àti ohun tí o gbàgbọ́ padà. Kí ìwọ náà sì dáhùn sí ìfẹ́ Rẹ̀ pẹ̀lú síṣí ọkàn rẹ sílẹ̀ kí o sì ní àjọṣe pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá rẹ, Olùgbéniró àti Bàbá ọ̀run onífẹ̀ẹ́ jùlọ.

Àdúrà

1. Ṣe àṣàrò l'órí oore Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí i Baba pípé. Kíni àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run yíó túmọ̀ sí bí o bá rí i ní ọ̀nà yìí nítòótọ́? Báwo ni o ṣe lè yí èrò rẹ padà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Rẹ̀?

“Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́, tí ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fún ni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ má baà ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” Jòhánù 3:16

“Ẹ má sì ṣe pè ẹnìkan ní bàbá yín ní ayé, nítorí ẹnìkan ni Bàbá yín, ẹni tí ń bẹ ní ọ̀run.” Mátíú 23:9

“Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ẹ̀bùn pípé láti òkè ni ó ti wá, ó sì ń sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Bàbá ìmọ́lẹ̀ wá, ní ọ̀dọ̀ ẹni tí kò le sí ìyípadà tàbí òjìji àyídà.” Jákọ́bù 1:17

2. Àwọn ọ̀nà wo ni o kò gbà ka Ọlọ́run sí Baba onífẹ̀ẹ́? Ọ̀nà wo ní o ti rí i gẹ́gẹ́ bí i akóniṣiṣẹ́, Ẹlẹ́dàá tí ó jìnnà, tàbí Bàbá onínúfùfù tí kò bìkítà?

“Ǹjẹ́ ìsọwọ́ gba àdúrà rẹ jẹ́ èyí tí ó rọrùn, bí i ti ọmọdé, pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé aláìlẹ́gbẹ́, àti ìfaramọ́ni ti ọmọ kékeré tí ó ń rọra gun òkè lọ sí ibi eékún Bàbá? Ìfọ̀kànbalẹ̀ wípé bàbá kò bìkítà bí ọmọ náà bá sùn lọ, tí ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi ohun ìṣeré ṣe eré, tàbí ti ó tilẹ̀ ń bá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ nítorí pé bàbá náà mọ̀ pé ọmọ yìí ti yàn láti wà ní ọ̀dọ̀ òun ní àkókò náà? Ṣé irú ẹ̀mí tí ò ń fi ń gba àdúrà nìyìíí?” Ìwé Brennan Manning, The Furious Longing of God.

3. Bẹ Ọlọ́run kí ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rí ìjìnlẹ̀ ìfẹ́ rẹ̀ ní òní. Lo àkókò láti gba ìwàláàyè rẹ̀ kí o sì sinmi nínú oore Rẹ̀. Ṣí àwọn agbọn ìgbésí ayé rẹ tí kò so èso ìfẹ́ aláìnídìí payá, kí o sì gba gbogbo ìfẹ́ tí ó ní láti fún ni.

“Olùbùkún ni Ọlọ́run àti Bàbá Jésù Krístì Olúwa wa, ẹni tí ó ti fi gbogbo ìbùkùn ẹ̀mí nínú àwọn ọ̀run bùkún wa nínú Krístì.” Éfésù 1:3

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Centering Your Life Around Meeting With God

Ohun tí ó jẹ́ gbòógì ní ayé yìí ni láti yan ohun kan: taani tàbí kíni a óò gbé ìgbésí ayé wa lé lórí? Ohun tí a yàn yí á mú kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe àwọn ìpinnu tí yíó tọ́ka irú ẹni tí a ó jẹ́, bí nǹkan ṣe ń rí ní ara wa, àwọn ẹni tàbí ohun tí a kà sí pàtàkì àti àwọn ohun tí a ó ti gbéṣe níkẹyìn ọjọ́ wa. Tí a bá fi ara wa nìkan ṣoo ṣe kókó tàbí àwọn ohun ti ayé yìí kò ní í da ohunkóhun fún wa ju ìparun lọ.

More

A fẹ́ dúpẹ́ l'ọ́wọ́ First15 fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí: https://www.first15.org/