Gbígbé Ìgbésí Ayé Rẹ Ní Ìbámu Pẹ̀lú Bíbá Ọlọ́run PàdéÀpẹrẹ

Èso Gbígbé inú Rẹ̀
Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, láti inú èròńgbà láti ṣe iṣẹ́ rere àti ìṣe tí ó yin orúkọ Ọlọ́run, a máa ń fi agídí mú èso jáde nínú iṣẹ́ wa láì bìkítà fún àkókò ìsinmi àti ànfàní láti gba àwọn èròjà aṣaralóore tí a lè gbà nípa gbígbé inú Bàbá wa ọ̀run. Ẹ̀ka yòówù tí kò bá sí lára igi òro òyìnbó kò leè so èso gidi kan bí ìwọ àti èmi kò ṣe lè dá iṣẹ́ gidi kan ṣe bíkòṣe pé a n gbé inú ìfẹ́, ore ọ̀fẹ́, àti ní iwájú Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà. Láì sí pé a pa gbogbo ayé wa pọ̀ sí ojú kan láti máa pàdé Ọlọ́run, a kò ní ní ànfàní láti so irú èso tí a dá wa láti so. Jésù fi èyí kọ́ wa nínú Jòhánù 15:1-5,
“Èmi ni àjàrà tòótọ́, Baba mi sì ni olùṣọ́gbà. Gbogbo ẹ̀ka nínú mi tí kò bá so èso, òun a mú kúrò: gbogbo ẹ̀ka tí ó bá sì so èso, òun a wẹ̀ ẹ́ mọ́, kí ó lè so èso sí i. Ẹ̀yin mọ́ nísinsin yìí nítorí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún yín. Ẹ máa gbé inú mi, èmi ó sì máa gbé inú yín. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka kò ti lè so èso fún ara rẹ̀ bí kò ṣe pé ó ba ń gbé inú àjàrà, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin, bí kò ṣe pé ẹ bá ń gbé inú mi. “Èmi ni àjàrà, ẹ̀yin ni ẹ̀ka. Ẹni tí ó ń gbé inú mi, àti èmi nínú rẹ̀, òun ni yóò so èso ní ọ̀pọ̀lọpọ̀: nítorí ní yíya ara yín kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ kò lè ṣe ohun kan."
Ọkàn Ọlọ́run ni kí á máa gbé inú Rẹ̀ ní ojoojúmó. Àgbàyanu ni èyí! Èmi àti ìwọ lè jẹ ọlá gbígbé inú àjàrà Bàbá wa ọ̀run tí ó pé, tí ó dára, tí ó sì ní agbára, ní ojoojúmọ́. A lè máa jí ní ojoojúmọ́, pẹ̀lú ọkàn tí ó ṣí sí Ọlọ́run, kí á sì máa gbé nínú ìṣọ̀kan tí a rí gbà nípasẹ̀ ètùtù Jésù tí ó ní agbára.
Dípò kí á máa tiraka láti ṣe iṣẹ́ rere ní gbàrà tí a bá gbéra, a gbọ́dọ̀ fi àyè sílẹ̀ láti jẹ ọlá ìfẹ́ Bàbá wa ọ̀run. Dípò kí á máa ṣe ètò làti sin Ọlọ́run, ó yẹ kí á gbà á ní ààyè láti tọ́ wa sí iṣẹ́ tí ó ti yà sílẹ̀ fún wa. Dípò kí á máa dù láti tọ́ àwọn ẹlómíràn sí ọ̀dọ̀ Jésù nípasẹ̀ ìyànjú wa, a kàn nílò láti gbé ìgbé ayé tí kò ní kọ̀rọ̀ tí kò sí ní ẹ̀tàn nínú pẹ̀lú ẹnikẹ́ni, nípa báyìí à n fi ọkàn Ọlọ́run hàn láti pàdé àwọn oníròbìnújẹ́ àti àwọn tí ó nílò Rẹ̀. Àti pẹ̀lú dípò kí á máa gbé bíi ẹni pé Ọlọ́run kàn ti fi wá sílẹ̀ láti ṣe ohun tí ó wù wá, a gbọ́dọ̀ máa ṣe ìtọ́ka sí ìṣọ̀kan àwa àti Ẹ̀mí Mímọ́ ní gbogbo ìgbà, nípasẹ̀ èyí à n gba ìfẹ́ wíwà níwájú Rẹ̀ kí ó ṣàn kiri ohun gbogbo tí a n ṣe.
Jákọ́bù 2:26 kọ́ wa, "Nítorí bí ara ní àìsí ẹ̀mí ti jẹ́ òkú, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú ni ìgbàgbọ́ ní àìsí iṣẹ́ jẹ́ òkú.” So ara rẹ pọ̀ àjàrà ìyanu ti Jésù ní òní yìí. Dá gbogbo ìgbé ayé rẹ sórí pípàdé pẹ̀lú Rẹ̀. Nípa gbígbé inú Ọlọ́run nìkan ni ìgbàgbọ́ rẹ ti lè so èso ààyè, tí ó wà títí, tí ó sì kún fún agbára Ẹ̀mí Ọlọ́run tí ó ń yí ènìyàn padà. Èròńgbà ni pé oó ṣe àwárí òmìnira àti ìfẹ́ tí o ní ànfàní sí ní òní yìí látàrí ìbáṣepọ̀ rẹ gbogbo ìgbà pẹ̀lú Bàbá rẹ ọ̀run.
Àdúrà
1. Ṣe àṣàrò lórí pàtàkì gbígbé nínú àjàrà. Gba Ìwé Mímọ́ ní ààyè láti rù ìfẹ́ ọkàn rẹ s'ókè láti sinmi nínú Ọlọ́run ní òní.
“Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run. A ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀-èdè, A ó gbé mi ga ní ayé." Sáàmù 46:10
“Ẹni tí ó ń gbé inú mi, àti èmi nínú rẹ̀, òun ni yóò so èso lọ́pọ̀lọpọ̀: nítorí ní yíya ara yín kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ kò lè ṣe ohun kan." Jòhánù 15:5
“Àwa ń sọ fún yín, èyí tí àwa ti rí, tí àwa sì ti gbọ́, kí ẹ̀yin pẹ̀lú kí ó lè ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú wa. Nítòótọ́ ìdàpọ̀ wa sì ń bẹ pẹ̀lú Baba àti pẹ̀lú ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi." 1 Jòhánù 1:3
2. Ibo ni o ti ń tiraka láti ṣe iṣẹ́ rere láì fi gbígbé ní iwájú Ẹlẹ́dàá rẹ ṣe? Agbọndan ayé rẹ wo ni o nílò láti so pò mọ́ ìfẹ́ Ọlọ́run?
3. Fi ààyè sílẹ̀ láti wà níwájú Ọlọ́run. Máa gbé inú Rẹ̀. Má wò tàbí ronú nípa ohun tí a gbé ka iwájú rẹ ní òní. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àyè ni yóò ṣì wà fún iṣẹ́ àti ìbádọ̀rẹ́. Te ojú rẹ mọ́ òtítọ́ íwà-nítòsí Ọlọ́run kí o sì ṣí ọkàn rẹ payá láti gba gbogbo ìfẹ́ tí ó ní sí ọ ní àkókò yìí.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ohun tí ó jẹ́ gbòógì ní ayé yìí ni láti yan ohun kan: taani tàbí kíni a óò gbé ìgbésí ayé wa lé lórí? Ohun tí a yàn yí á mú kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe àwọn ìpinnu tí yíó tọ́ka irú ẹni tí a ó jẹ́, bí nǹkan ṣe ń rí ní ara wa, àwọn ẹni tàbí ohun tí a kà sí pàtàkì àti àwọn ohun tí a ó ti gbéṣe níkẹyìn ọjọ́ wa. Tí a bá fi ara wa nìkan ṣoo ṣe kókó tàbí àwọn ohun ti ayé yìí kò ní í da ohunkóhun fún wa ju ìparun lọ.
More