Gbígbé Ìgbésí Ayé Rẹ Ní Ìbámu Pẹ̀lú Bíbá Ọlọ́run PàdéÀpẹrẹ

Yíyan Orísun
Báwo ni ìgbésí ayé wa ì bá ṣe rí bí a bá fi àkókò wa, okun wa, èrò-ara wa, àti àwọn ìlépa sọ orí wíwá Ọlọ́run? Gbogbo wa ni a máa ń yàn láti fi ìgbésí ayé wa sọ orí ohun kan tàbí ẹnìkan. Gbogbo ìpinnu tí à ń ṣe maá ń dá lé orí ohun tí a kà sí pàtàkì jùlọ. Àwọn kan ní ara wa maá ń gbé ìgbésí ayé wọn ká orí ara wọn. Àwọn míìràn sì wà tí ó jẹ́ pé èrò ẹlòmìíràn ni òdinwọ̀n ayé wọn. Síbẹ̀, àwọn mìíràn yàn láti gbé ìgbésí ayé wọn ní ọ̀nà tí ó bá èrò tàbí ìwòye kan mu, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé ó ní iye l'órí gan-an. Mo gba àdúrà pé kí àwa, gẹ́gẹ́ bí i ara Krístì, á bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìgbésí ayé wa ní orí ilẹ̀ ayé yìí sọ orí bíbá Ẹlẹ́dàá wa pàdé nítorí pé òun ni ẹni tí ó yẹ jùlọ láti gba iyì tí ó ṣe iyebíye jù l'ọ́wọ́ wa.
Fífi ayé wa sọ orí ìbápàdé pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ ohun tí ó dára jùlọ tí a lé ṣe ní ìgbèsí ayé wa.
Sáàmù 84:10-12 sọ wípé,“Nítorí pé ọjọ́ kan nínú àgbàlá rẹ sàn ju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ lọ. Mo fẹ́ kí n kúkú máa ṣe adènà ní ilé Ọlọ́run mi, jù láti máa gbé àgọ́ ìwá-búburú. Nítorí Olúwa Ọlọ́run ni òòrùn àti asà; Olúwa yíó fúnni ní oore-ọ̀fẹ́ àti ògo: kò sí ohun rere tí yíó fà s'ẹ́yìn lọ́wọ́ àwọn tí ń rìn déédéé. Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ìbùkún ni fún olúwaa rẹ̀ náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ!”
Ní ìgbà tí a bá gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run tí a sì mọ iyì Rẹ̀, a fi ara wa sí ipò tí a ó lè máa gbé ní ìrẹ́pọ̀ aláyọ̀ pẹ̀lú Bàbá tí ó ní ìfẹ́ wa. Ó wu Ọlọ́run wa pé kí ó bá wa pàdé. Ó fẹ́ kí a tọ́ ọ wò kí a sì rí i pé òun jẹ́ ẹni rere. Àyàfi ìgbà tí a bá ń gbé ìgbésí ayé wa ní ọ̀nà tí ó fi hàn pé àjọṣe wa pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wa ni ó ṣe pàtàkì jùlọ, ni a tó lè gbádùn ìgbésí ayé àgbààyanu tí Ọlọ́run fẹ́ fún wa.
Ó yẹ kí n sọ fún ọ pé Ọlọ́run ni mo fi ṣe orísun ìgbésí ayé mi. Ó yẹ́ kí n sọ pé Jésù ni mo kà sí ẹni tí ó ṣe pàtàkì jùlọ; ṣúgbọ́n àwọn ohun tí mò ń ṣe, àkókò tí mò ń lò, èrò mi, àti bí nǹkan ṣe ń rí ní ara mi kò fi ìgbà kan fi hàn pé òtítọ́ ni bí mo bá sọ bẹ́ẹ̀. O rí i, a máa ń d'ígbà lo àkókò pẹ̀lú àwọn tí a fẹ́ràn jùlọ. A máa ǹ da'rí èrò-ara wa, ìṣe wa, àti èrò-ọkàn wa sí orí ohun tí a kà sí pàtàkì jùlọ. Bí ìgbésí ayé wa kò bá fi hàn pé ní òtítọ́ ni a yí ojú sí Jésù, a gbọ́dọ̀ fi òtítọ́ inú yẹ ara wa wò, kí á sì bẹ Ọlọ́run pé kí ó ràn wá l'ọ́wọ́ láti ṣe àwọn àyípadà tí ó yẹ. A gbọ́dọ̀ mú ìdíbàjẹ́ àti ẹ̀ṣẹ̀ wa wá sí iwájú Ọlọ́run, kí a sì bẹ̀ ẹ́ pé kí ó ràn wá l'ọ́wọ́ láti yí padà di ọmọ tí ó kún fún ìwàláàyè Rẹ̀.
Fífi ohun míràn yàtọ̀ sí Jésù ṣe orísùn ayé wa yíó mú ìjákulẹ̀ àti àìní ìtẹ́lọ́rùn wá. Kò sí ohun rere kankan nínú ayé yìí. Bí a bá jẹ́ kí ohun ti ara wa nìkan gbà ọkàn wá kan, à ń fi kún ẹrù ìnira àti pákáǹleke ayé yìí ni. Bí ìgbésí ayé wa bá dá lé orí dída ara dé ènìyàn, a ó kàn máa yí ká ní olóbìrípo nínú ẹ̀dùn ọkàn àti ìrẹ̀wẹ̀sì àwọn ẹlòmìíràn. Bí ìgbésí ayé wa bá dá lé orí èrò kan tàbí ìṣe kan, èyí yíó kàn mú wa kó ọ̀rọ̀ tí kò níí tọ́ ọjọ́ ju ayé yìí tí ń kọjá lọ.
Wá ààyè ní ònìí láti fi tọkàntọkàn ṣe àyẹ̀wò ọkàn rẹ. Jẹ́ kí Ẹ̀mí Mímọ́ fi gbogbo ọ̀nà náà hàn ọ́, ibi tí ìgbésí ayé rẹ kò ti dá lé orí ìbápàdé pẹ̀lú Ọlọ́run. Jẹ́wọ́ ìfẹ́ àwọn ohun ti ayé tàbí ti ara ẹni, kí o sì wá ọ̀nà tí ìgbésí ayé rẹ yíó fi dá lé orí àjọṣe tímọ́tímọ́ tí kò ní ìpẹ̀kun pẹ̀lú Bàbá rẹ ọ̀run, ẹni rere àti onífẹ̀ẹ́.
Àdúrà
1. Ṣe àṣàrò l'órí bí ó ti ṣe pàtàkì tó pé kí ìbápàdé pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ ọ́ l'ógún ní ìgbésí ayé rẹ. Gba Ìwé Mímọ́ ní ààyè láti ru ọkàn rẹ sí òkè kí o lè ka bíbá Ẹlẹ́dàá rẹ s'ọ̀rọ̀ sí ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ.
“Olúwa ṣe rere fún gbogbo ẹni tí ó dúró dè é, fún ọkàn tí ó ṣe àfẹ́rí Rẹ̀.” Ẹkún Jeremáyà 3:25
“Òpin gbogbo ọ̀rọ̀ náà tí a gbọ́ ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run kí o sì pa òfin Rẹ̀ mọ́, nítorí èyí ni fún gbogbo ènìyàn.” Ìwé Oníwàásū 12:13
2. Ní ibo ni ìgbésí ayé rẹ kò ti dá lé orí bíbá Ọlọ́run pàdé? Ní ibo ni o fi iye rẹ, agbára rẹ, àkókò rẹ, àti èrò rẹ sí yàtọ̀ sí Jésù?
“Ǹjẹ́ ojúrere ènìyàn ni mò ń wá nísinsìnyí, tàbí ti Ọlọ́run? Àbí ohun tí ó wu ènìyàn ni mo fẹ́ máa ṣe? Bí ó bá jẹ́ pé ohun tí ó wu ènìyàn ni mò ń ṣe síbẹ̀, èmi kì í ṣe ìránṣẹ́ Krístì.” Gàlátíà 1:10
3. Bèèrè pé kí Ẹ̀mí Mímọ́ ràn ọ́ l'ọ́wọ́ láti tún orísun ìgbésí ayé rẹ ṣe ní ònìí. Bèèrè pé kí ó fi ohun tí fífi ìbápàdè pẹ̀lú Ọlọ́run ṣe pàtàkì ní ayé ẹni jẹ́ hàn ọ́. Pinnu pé àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run ni yíó ṣe pàtàkì jùlọ sí ọ.
“Nítorí pé ọjọ́ kan nínú àgbàlá rẹ sàn ju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ lọ. Mo fẹ́ kí n kúkú máa ṣe adènà ní ilé Ọlọ́run mi, jù láti máa gbé àgọ́ ìwá-búburú. Nítorí Olúwa Ọlọ́run ni òòrùn àti asà; Olúwa yíó fúnni ní oore-ọ̀fẹ́ àti ògo: kò sí ohun rere tí yíó fà s'ẹ́yìn l'ọ́wọ́ àwọn tí ń rìn déédéé. Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ìbùkún ni fún olúwaa rẹ̀ náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé!” Sáàmù 84:10-12
“Mo fẹ́ àwọn tí ó fẹ́ mi, àwọn tí ó sì fi tọkàntọkàn wá mi yíó rí mi.” Ìwé Òwe 8:17
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ohun tí ó jẹ́ gbòógì ní ayé yìí ni láti yan ohun kan: taani tàbí kíni a óò gbé ìgbésí ayé wa lé lórí? Ohun tí a yàn yí á mú kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe àwọn ìpinnu tí yíó tọ́ka irú ẹni tí a ó jẹ́, bí nǹkan ṣe ń rí ní ara wa, àwọn ẹni tàbí ohun tí a kà sí pàtàkì àti àwọn ohun tí a ó ti gbéṣe níkẹyìn ọjọ́ wa. Tí a bá fi ara wa nìkan ṣoo ṣe kókó tàbí àwọn ohun ti ayé yìí kò ní í da ohunkóhun fún wa ju ìparun lọ.
More