Gbígbé Ìgbésí Ayé Rẹ Ní Ìbámu Pẹ̀lú Bíbá Ọlọ́run PàdéÀpẹrẹ

Jésù ni Orísun
Gbogbo ayérayé dá lé orí ikú, àti àjíǹde Jésù. Òun ni Ọmọ Ọlọ́run alààyè tí Ó ṣe pàtàkì jùlọ, tí Ó ń yí ìwàláàyè padà títí láí, tí ó sì tún ń gba aráyé là. Kólósè 1:15 sọ fún wa wípé“Ẹnití í ṣe àwòrán Ọlọ́run tí a kò rí, àkọ́bí gbogbo ẹ̀dá.”
Hébérù 1:3 sọ wípé,“Ẹnití í ṣe ìtànsàn ògo Rẹ̀, àti àwòrán Òun tìkaararẹ̀, tí Ó sì ń fi ọ̀rọ agbára Rẹ̀ mú ohun gbogbo dúró, lẹ́yìn tí Ó tí ṣe ìwẹ̀nù ẹ̀ṣẹ̀, Ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọláńla ní òkè.”
Àti ní ìgbà ìpadàbọ̀ Rẹ̀, Ìfihán 19:16 sọ wípé, “Ó sì ní ní ara aṣọ Rẹ̀ àti ní ìtàn Rẹ̀ orúkọ kan tí a kọ: Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa.”
Láti dá ayé wa lé orí ìbápàdé pẹ̀lú Ọlọ́run túmọ̀ sí fífi ìpìlẹ̀ wa lé'lẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ tí kò lè mì, tí ó jẹ́ ti ayérayé. Láti gbé ìgbésí ayé wa ka orí bíbá Jésù pàdé, jẹ́ fífi ìdákọ̀ró ìrètí wa sí inú Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa. Jésù nìkan ni Ó máa ń mú ìlérí Rẹ̣̀ ṣẹ. Jésù nìkan ni yíó mú ìlérí tí Ó ṣe fún wa ṣẹ.
1 Jòhánù 2:17 sọ wípé, “Ayé sì ń kọjá lọ, àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀: ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ní yíó dúró títí láíláí.” Ìfè Ọlọ́run ní láti dá ayé wa lé orí ìwàlááyè Rẹ̀ tí ó kún fún ìfẹ́. Òfin Ọlọ́run tí ó ga jùlọ ni pé kí a fẹ́ Ẹ pẹ̀lú ohun gbogbo ohun tí à ń ṣe. Láti gbé ìgbésí ayé tí ó yàtọ̀ pátápátá sí ti ayé tí ó yí ọ ká nípa gbígbé ìgbésí ayé rẹ ka orí bíbá Jésù pàdé, jẹ́ títọ ọ̀nà tuntun tí yíó y'ọrí sí ìgbésí ayé tí ó peregedé ní ẹkúnrẹ́rẹ́.
Láti gbé ìrètí rẹ̀ lé Jésù nìkan ṣoṣo lé jọ ìwà agọ̀ ní ojú ayé, ṣùgbọ́n kò sí ohun tí ó ṣe pàtàkì ju èyí lọ. Ó lè dà bíi ohun tí ó ṣe àjèjì láti pa àwọn ohun tí àwùjọ ń lépa tì, bí i ìtura, ipò, àti òkìkí, ṣùgbọ́n, kò sí ìpinnu tí ó dára jù tí ènìyàn lè ṣe ju èyí lọ. Ò ń sìn Ọlọ́run tí Ó ti wà, tí Ó wà, tí Ó sì ń bọ̀ wàá. Ọba tí Ó fi ẹ̀mí ara Rẹ̀ lé ilẹ̀ kí o lè wà l'áàyè ní tòótọ́ ni Ó ni ọ́. O kò lè rí ayọ̀, àlàáfíà, tàbí ète tí ó ju sísin Jésù nìkan lọ. Kò sí ìgbésí ayé tí ó sàn ju kí ènìyàn fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sin Ọba gbogbo ayé.
Lo àkókò díẹ̀ ní òní láti fi ara rẹ fún Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa ní òtun. Yẹ'ra fún èrò òdì, kí o sì ronú nípa ìjọba ayérayé ti Ọlọ́run. Jẹ́ kí òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ìfẹ́ Rẹ̀ fún ọ ní ìgboyà láti yàn ìfọkànsìn sí Ọlọ́run ju ṣíṣe iṣẹ́ sìn ara rẹ àti ayé tí ó yí ọ ká lọ. Ǹjẹ́ kí ìwàláàyè Jésù Ọba kún inú ayé rẹ ní òní.
Àdúrà
1. Ṣe àṣàrò lé orí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa Jésù.Rántí pé Ó wà l'áàyè, Ó sì ń bẹ ní ìtòsí. Òun ni Ọlọ́run alààyè, Ìwé Mímọ́ sì sọ pé ayè rẹ wà nínú Rẹ̀.
“A ti kàn mí mọ́ àgbélégbèbú pẹ̀lú Krístì, ṣùgbọ́n mo wà l'áàyè, síbẹ̀ kìí ṣe èmi mọ́, ṣùgbọ́n Jésù wà l'áàyè nínú mi. Wíwà tí mo sì wà l'áàyè nínú ara, mo wà l'áàyè nínú ìgbàgbọ́ Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí Ó fẹ́ mi, tí Ó sì fi Òun tìkaararẹ̀ fún mi.” Gàlátíà 2:20
“Nítorí a bí ọmọ kan fún wa, a fi ọmọkùnrin kan fùn wa; ìjọba yíó sì wà ní èjìká Rẹ̀, a ó sì máa pe orúkọ Rẹ̀ ní Ìyanu, Olùdámọ̀ràn, Ọlọ́run Alágbára, Baba Ayérayé, Ọmọ-Aládé Àlááfíà.” Àìsáyà 9:6
“Kí á máa wo Jésù olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláṣepé ìgbagbọ́ wa; ẹni tí, nítorí ayọ̀ tí a gbé ká iwájú Rẹ̀, Ó fi ara da àgbélébùú láì ka ìtìjú sí, tí Ó sì jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.” Hébérù 12:2
2. Àwọn ọ̀nà wo ni ìgbésí ayé rẹ kò gbà dá lé orí Jésù? Àwọn ọ̀nà wo ni ò ń gbà gbé ìgbé ayé rẹ fún ayé yìí dípò ìyè àìnípẹ̀kun?
3. Bẹ Ẹ̣̀mí Mímọ́ pé kí Ó ràn ọ̣́ l'ọ́wọ́ láti gbé ìgbésí ayé rẹ ka orí irú ẹni tí Jésù jẹ́. Bẹ Ẹ̀ pé kí Ó kún ọ pẹ̀lú ìmọ́ sísúmọ́ itòsí Rẹ̀ àti ìfè Rẹ̀ fún ọ. Ṣí ọkàn rẹ payá, kí o sì gba ìwàálàyè Jésù. Bèèrè pé kí Ó fi àwọn ọ̀nà tí o lè gbà fi ìgbésí ayé rẹ sọ orí Rẹ̀ ní òní.
“Ǹjẹ́ bí a bá ti jí yin dìde pẹ̀lú Krístì, ẹ máa ṣe àfẹ́rí àwọn ǹǹkan tí ń bẹ l'óké, ní ibi tí Krístì gbé wà tí Ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.” Kólósè 3:1
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ohun tí ó jẹ́ gbòógì ní ayé yìí ni láti yan ohun kan: taani tàbí kíni a óò gbé ìgbésí ayé wa lé lórí? Ohun tí a yàn yí á mú kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe àwọn ìpinnu tí yíó tọ́ka irú ẹni tí a ó jẹ́, bí nǹkan ṣe ń rí ní ara wa, àwọn ẹni tàbí ohun tí a kà sí pàtàkì àti àwọn ohun tí a ó ti gbéṣe níkẹyìn ọjọ́ wa. Tí a bá fi ara wa nìkan ṣoo ṣe kókó tàbí àwọn ohun ti ayé yìí kò ní í da ohunkóhun fún wa ju ìparun lọ.
More