Àdúrà OlúwaÀpẹrẹ

The Lord's Prayer

Ọjọ́ 8 nínú 8

Ìwòye

Nítorí ìjọba ni tìrẹ àti agbára, àti ògo láíláí, Àmín.

Gbólóhùn ìkẹyìn Àdúrà Olúwa yìí kò fi ara hàn nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ àkọ́kọ́ ti Májẹ̀mú Tuntun àti pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń sọ ọ́ nínú àwọn ilé ìjọsìn, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìtumọ̀ Bíbélì òde òní ni ó sọ ọ́ di àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé ẹṣẹ Bíbélì. Ní tìka lára mí, mo dúró lórí rẹ̀. Ìdí kan ni pé àwọn àdúrà Júù ní gbogbo ọjọ́ Jésù parí pẹ̀lú àwọn irú ìbùkún kan fún Ọlọ́run àti pé ó ṣeé ṣe pé àwọn Kristẹni ìgbà ní ṣe ohun kan tí ó jọra. Ìdí mìíran ni pé àdúrà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn àti pé ó jẹ́ ìmọ̀ràn tí ó yẹ láti parí rẹ̀ lóri àkọsílẹ̀ kan náà. Àti ní ìkẹyìn, tí gbólóhùn yìí kò bá sí níbè ó fi ọkàn rẹ sílẹ̀ ní ipò àìbalẹ̀ ní ibi tí ohun tí ó kẹ́yìn àdúrà tọ́'ka sí 'ènìyàn búburú'. Mo rò pé ó ṣe pàtàkì láti rán ara wa l'étí pé ní ìgbà tí a bá n gba àdúrà, bíi ti ìtàn àkọsílẹ̀, èṣù kò ní ọ̀rọ̀ ìkẹyìn.

Ohun tí gbólóhùn ìkẹyìn yìí ṣẹ ni ìwúrí fún wa láti dá ọwọ́ àwọn àdúrà wá fún ìpèsè, ìdáríjì àti ààbò dúró láti rí àwòrán ńlá náà. Ó fi ìdí ìwàláàyè wa hàn. Jẹ́ kí n pe àkíyèsí rẹ sì àwọn nǹkan mẹ́ta yìí.

Ohun àkọ́kọ́ ni wí pé a rán wa létí wí pé ìjọba gbọ́dọ̀ jẹ́ àkọ́kọ́ nínú ayé wa. Gbogbo wa ni a ní ìdojúkọ pẹ̀lú àwọn àṣàyàn àìlópin nínú ìgbésí ayé wa bíi irú iṣẹ́ tí a gbọ́dọ̀ mú, báwo ni a ṣe lè lo àkọ́kọ́ wa tàbí owó wa. Àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ìdààmú fún ọkàn wa, wọ́n sì lè tètè darí ìrònú wa. Ní ibí Ọlọ́run sọ pé kí o gbé ojú rẹ sí òkè kúrò ní ọ̀dọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí tí ó n gbà àkókò rẹ: iṣẹ́ ìfihàn nlá rẹ yẹn, ipò ọkọ̀ ayọ̀kẹ́lẹ́, iwọntún-wọnsì akànti owó rẹ tí ó ṣe àìsàn tàbí ìrora ní èjìká rẹ kí o wo ìjọba Ọlọ́run.

Èkejì ni pé gbólóhùn yìí rán wa létí pé ète ayé wa ni láti kọ́ ìjọba Ọlọ́run kí o sì fún-un ní ògo rẹ̀. Ó ní àwòrán Ogun Àgbáyé Kínní kàn tí o ní òkìkí, nínú èyí tí ọmọbìnrin kékeré kan, tí ó jókòó sí orí itan bàbá rẹ̀, béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, 'Bàbá mí, kíni e ṣe nínú Ogun Ńlá?’. Àwòrán bàbá náà fi hàn pé ìdáhùn náà jẹ́ ‘Ó kéré gan-an.’ Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a yí ìbéèrè yẹn padà láti inú ogun tí ó ti kọjá lọ sí ìgbé ayé wa nísinsìnyí. Ó ri pé ó jẹ́ ìbéèrè kan tí ó mú ìpayà bá ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ní ọ̀nà oríṣiríṣi ní ìgbà tí wọ́n bá fi ẹ̀yìn tì tàbí tí wọ́n bá dé òpin ayé wọn. ‘Kí ni mo fi gbogbo wákàtí tí Ọlọ́run fún mi ṣe? Kíni mo lo agbára mi lórí? Àṣeyọrí mi wo ni ó ní iye lórí fún ìgbà pípẹ́?’ Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé góńgó kan ṣoṣo fún ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn tí ó ní iye lórí títí láé ni Ìjọba Ọlọ́run.

Ìkẹta ni pé a rán wa létí pé a nílò láti di agbára Ọlọ́run mú ṣinṣin nínú ayé wa. Àdúrà Olùwà pè wá ní'jà ó sì béèrè ìgbésí ayé wa. Ó jẹ́ ọ̀nà sí àìní ìsinmi àti ìjákulè láti gbìyànjú láti tẹ́lẹ̀ àdúrà yìí pẹ̀lú agbára wa. Ìrètí wa nìkan ni pé láti wá agbára Ẹ̀mí Mímọ́ láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa.

Ní ìkẹyìn, ẹ jẹ́ kí n sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ kékeré náà Àmín. Sísọ Àmín jẹ́ ìfaramọ́ ohun tí a ti sọ. Ó jẹ́ sísọ pé jẹ́ kí ó ṣẹlẹ̀! Ó dà bíi pé a parí lẹ́tà kan pẹ̀lú ìbùwọlù, gbígbé ọwọ́ rẹ sókè ní àdéhùn lórí àwọn ọ̀rọ̀ ìsípòpadà tàbí pàápàá títẹ bọ́tìnì ìfiránṣẹ́ lóri ẹ̀rọ ímeèli. À ń sọ fún Ọlọ́run, gbogbo ohun tí a ti gba àdúrà rẹ̀, ‘Kí ó ṣẹlẹ̀’! 

Ní òtítọ́, lórí gbogbo ohun tí o ti gba àdúrà nínú gbogbo àdúrà yìí, jẹ́ kí o le sọ pẹ̀lú ìgboyà ní ìparí, Àmín

Kí Ọlọ́run sì dá o lóhùn!


Nípa Ìpèsè yìí

The Lord's Prayer

Da ara pọ̀ mọ́ J.John l'órí ìkẹ́ẹ̀kọ́ ọjọ́ mẹ́jọ l'órí Àdúrà Olúwa, ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ Jésù tí ó ya'ni l'ẹ́nu tí ó sì ṣe ìrànlọ́wọ́ l'órí kíkọ́ni bí ó ṣe yẹ kí a gba àdúrà.

More

A fé láti dúpe lówó J JOHN fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé sí i, jọ̀wọ́ lọ sí: https://canonjjohn.com