Àdúrà OlúwaÀpẹrẹ

Ìpèsè
Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa ní òní
Ní ọ̀nà kan, ìyípadà wà nínú Àdúrà Olúwa ní ibi tí a wà yìí. A lọ láti ibi, kí á sọ pé, 'gbígbé ojú sí òkè' wo Ọlọ́run, kọjá sí 'wíwo àyíká' sí ọ̀dọ̀ ara wa àti àwọn tí wọ́n yí wa ká. Yíyí ojú padà yí ṣe àkàwé Òfin Mẹ́wàá àti àkótán nnkan tí Jésù pè ní ẹ̀sìn tí ó tọ̀nà: kí á fẹ́ Ọlọ́run kí á sì fẹ́ àwọn ọmọnìkéjì wa (Matiu 22:36-40). Síbẹ̀ kò bá ọgbọ́n lọ láti rò pé à ń yí padà ní ibí yìí kúrò nínú ẹ̀mí sí ti ara; òtítọ́ ibẹ̀ ni pé Ọlọ́run ń kó ipa nínú gbogbo ohun tí ó jẹ mọ́ ayé wa.
A nílò láti ronú dáradára sí ìtumọ̀ gbolóhùn yìi. A ti máa ń rò pé 'àkàrà' túmọ̀ sí gbogbo nnkan kò-ṣeé-má-nìí ayé. Nínú èyí ni gbogbo àwọn nnkan tí a lèè fi ojú rí wà: kìí ṣe ouńjẹ nìkan ṣùgbọ́n omi, ibùgbé, aṣọ, ìlera, owó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó sì tún jù bẹ́ẹ̀ lọ: ó lè tún jẹ́ àwọn nnkan ti ìmọ̀-ọkàn bíi ìfọ̀kànbalẹ̀, ìrètí, àti ìgboyà, àti àwọn nnkan èlò ti ẹ̀mí bíi oore ọ̀fẹ́, ìmọ̀lára pé Ọlọ́run wà, àti ìgbàgbọ̀ fúnrarẹ́. Àkàrà ni gbogbo ohun tí a nílò láti lè máa tẹ̀ sí iwájú. Ṣe àkíyèsí pé láti gbàdúrà fún àkàrà ni láti gbà pé Ọlọ́run ni a gbẹ́kẹ̀lé. Ó rọrùn kí á dúró pẹ̀lú ìgbéraga pé a jẹ́ ẹni tí ó máa ń ṣe àkíyèsí ohun tí a jẹ́ àti tí a ní, kí à sì sọ pé 'èyí ni ohun tí èmí fúnrara mi ṣe’. Nínú ìwé Dáníẹ́lì ori 5, wòòlí náà kéde ìdájọ́ kan lórí ìkà Ọba Beṣásárì tí àwọn ọ̀rọ̀ yìí wà nínú rẹ̀ pé 'Ìwọ kò yin Ọlọrun tí ẹ̀mí rẹ wà lọ́wọ́ rẹ̀ lógo, ẹni tí ó mọ gbogbo ọ̀nà rẹ’ (Danieli 5:23).Bákan náà ni Pọ́ọ̀lù, nígbà tí ó ń dojú kọ ìgbéraga nínú ìjọ Kọ́ríntì kọ pé, 'Kí ni ohun tí ẹ dá ní, tí kò jẹ́ pé ọwọ́ Ọlọrun ni ó ti rí i gbà?’ (1 Korinti 4:7).
Síbẹ̀ tí ìbú kankan bá wà nínú gbólóhùn yí ìdiwọ̀n tún wà pẹ̀lú. Àkàrà jẹ́ ìpìlẹ̀ oúnjẹ fún ìyè, èyí nìkan sì ni Jésù sọ pé kí á gbàdúrà fún; kìí ṣe àwọn nnkan afẹfẹyẹ̀yẹ̀ ayé ṣùgbọ́n àwọn ohun tí wọn ṣe pàtàkì jùlọ. Bí a ti ń gbàdúrà yí ẹ má ṣe jẹ́ kí á gbàgbé pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó wà ní ayé yì tí ó jẹ́ pé kí wọ́n jàjà ní ànfààní láti ní àwọn nnkan kò-ṣeé-má-nìí ayé tí ó kéré jù yóòjẹ́ ìgbádùn ni ó jẹ́ fún wọn. Nígbà tí a bá ń gbàdúrà ní ibi tí a wà nínú Àdúrà Olúwa yì, ẹ jẹ́ kí á rán ara wá létí pé à ń gbàdúrà fún àìní wa ni, kìí ṣe fún ojúkòkòrò wa. A ní láti rántí gbogbo ohun tí a ti fi fún wa.
Kò sí àwọn ọ̀rọ̀ tí kò wúlò nínú Àdúrà Olúwa àti pé ojoojúmọ́gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ yẹ kí ó mú wa séra ró. Ìdánwò ńlá ni pé kí ó jẹ́ pé ohun tí a nílò nísinsìnyí nìkan ni kí á bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, kí á sì má bèèrè ohun tí a lérò pé ó ṣeé ṣe kí á nílò ní ọjọ́ iwájú. Síbẹ̀ ṣíṣe eléyìí jẹ́ ọ̀kan nínú ọ̀pọ̀ ọ̀nà tí a fi ń ṣe mọ̀dàrú èrèdí àdúrà. Ọlọ́run fẹ́ kí àdúrà wa kí ó dá lé ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Òun, àti pé kí á máa mú ìbéèrè wa wá sí ọ̀dọ̀ Òun ní ojoojúmọ́ máa ran èyí lọ́wọ́. Kí á máa gbàdúrà ní ojoojúmọ́ fún àwọn àìní wa jẹ́ ọ̀nà sí ìdàgbàsókè ìbáṣepọ̀ ayérayé.
Ní àkótán, jẹ́ kí n tọ́ka sí ohun kan tí ó wà láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin Àdúrà Olúwa: ọ̀rọ̀ kékeré yẹn wa. Ó sì ṣe pàtàkì púpọ̀. Ó rọrùn kí àfojúsùn àdúrà wa jẹ́ ti ara wa ṣùgbọ́n èyí kìí ṣe àfojúsùn Májẹ̀mú Tuntun. A ní láti pinnu láti tẹ̀lé Krístì kí a sì da ara pọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olóríjorí; ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí Krìstẹ́nì a ní láti rí ara wa gẹ́gẹ́ bí ara àwùjọ kan. Nígbà tí a ba ń gbàdúrà, kí á máa gbàdúrà fun àwọn tí a ní ìsopọ̀ pẹ̀lú: àwọn ẹbí wa nínú ara àti àwọn ẹbí wa nínú ẹ̀mí. Àti ní pàápàá, ó jẹ́ ohun tí ó dára láti máa gbàdúrà fún àwọn ọ̀rẹ̀, alábàáṣiṣẹ́pọ̀ àtí aládùgbóò wa pẹ̀lú.
Níkẹyìn, nígbà tí Ọlọ́run bá fún wa ní 'àkàrà' ojoojúmọ́ wa – àti pé, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà a máa jù bẹ́ẹ̀yẹn lọ – ẹ jẹ́ kí á fi ẹ̀mí ìmoore hàn.
Ìpèsè
Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa ní òní
Ní ọ̀nà kan, ìyípadà wà nínú Àdúrà Olúwa ní ibi tí wà yìí. A lọ láti ibi, kí á sọ pé, 'gbígbé ojú sí òkè' wo Ọlọ́run, kọjá sí 'wíwo àyíká' sí ọ̀dọ̀ ara wa àti àwọn tí wọ́n yí wa ká. Yíyí ojú padà yí ṣe àkàwé Òfin Mẹ́wàá àti àkótán nnkan tí Jésù pè ní ẹ̀sìn tí ó tọ̀nà: kí á fẹ́ Ọlọ́run kí á sì fẹ́ àwọn ọmọnìkéjì wa (Matiu 22:36-40). Síbẹ̀ kò bá ọgbọ́n lọ láti rò pé à ń yí padà ní ibí yìí kúrò nínú ẹ̀mí sí ti ara; òtítọ́ ibẹ̀ ni pé Ọlọ́run ń kó ipa nínú gbogbo ohun tí ó jẹ mọ́ ayé wa.
A nílò láti ronú dáradára sí ìtumọ̀ gbolóhùn yìi. A ti máa ń rò pé 'àkàrà' túmọ̀ sí gbogbo nnkan kò-ṣeé-má-nìí aye. Nínú èyí ni gbogbo àwọn nnkan tí a lèè fi ojú rí wà: kìí ṣe ouńjẹ nìkan ṣùgbọ́n omi, ibùgbé, aṣọ, ìlera, owó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó sì tún jù bẹ́ẹ̀ lọ: ó lè tún jẹ́ àwọn nnkan ti ìmọ̀-ọkàn bíi ìfọ̀kànbalẹ̀, ìrètí, àti ìgboyà, àti àwọn nnkan èlò ti ẹ̀mí bíi oore ọ̀fẹ́, ìmọ̀lára pé Ọlọ́run wà, àti ìgbàgbọ̀ fúnrarẹ́. Àkàrà ni gbogbo ohun tí a nílò láti lè máa tẹ̀ sí iwájú. Ṣe àkíyèsí pé láti gbàdúrà fún àkàrà ni láti gbà pé Ọlọ́run ni a gbẹ́kẹ̀lé. Ó rọrùn kí á dúró pẹ̀lú ìgbéraga pé a jẹ́ ẹni tí ó máa ń ṣe àkíyèsí ohun tí a jẹ́ àti tí a ní, kí à sì sọ pé 'èyí ni ohun tí èmí fúnrara mi ṣe’. Nínú ìwé Dáníẹ́lì ori 5, wòòlí náà kéde ìdájọ́ kan lórí ìkà Ọba Beṣásárì tí àwọn ọ̀rọ̀ yìí wà nínú rẹ̀ pé 'O kò yin Ọlọrun tí ẹ̀mí rẹ wà lọ́wọ́ rẹ̀ lógo, ẹni tí ó mọ gbogbo ọ̀nà rẹ’ (Danieli 5:23).Bákan náà ni Pọ́ọ̀lù, nígbà tí ó ń dojú kọ ìgbéraga nínú ìjọ Kọ́ríntì kọ pé, 'Kí ni ohun tí ẹ dá ní, tí kò jẹ́ pé ọwọ́ Ọlọrun ni ẹ ti rí i gbà?’ (1 Korinti 4:7).
Síbẹ̀ tí ìjìnlẹ̀ kankan bá wà nínú gbólóhùn yí òdiwọ̀n tún wà pẹ̀lú. Àkàrà jẹ́ ìpìlẹ̀ oúnjẹ fún ìyè, èyí nìkan sì ni Jésù sọ pé kí á gbàdúrà fún; kìí ṣe àwọn nnkan afẹfẹyẹ̀yẹ̀ ayé ṣùgbọ́n àwọn ohun tí wọn ṣe pàtàkì jùlọ. Bí a ti ń gbàdúrà yí ẹ má ṣe jẹ́ kí á gbàgbé pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó wà ní ayé yì tí ó jẹ́ pé kí wọ́n jàjà ní ànfààní láti ní àwọn nnkan kò-ṣeé-má-nìí ayé tí ó kéré jù yóòjẹ́ ìgbádùn ni. Nígbà tí a bá ń gbàdúrà ní ibi tí a wà nínú Àdúrà Olúwa yì, ẹ jẹ́ kí á rán ara wá létí pé à ń gbàdúrà fún àìní wa ni, kìí ṣe fún ojúkòkòrò wa. A ní láti rántí gbogbo ohun tí a ti fi fún wa.
Kò sí àwọn ọ̀rọ̀ lásán nínú Àdúrà Olúwa àti pé ojoojúmọ́gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ yẹ kí ó mú wa dára dúró. Ìdánwò ńlá ni pé kí ó jẹ́ pé ohun tí a nílò nísinsìnyí nìkan ni kí á bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, kí á sì má bèèrè ohun tí a lérò pé ó ṣeé ṣe kí á nílò ní ọjọ́ iwájú. Síbẹ̀ ṣíṣe eléyìí jẹ́ ọ̀kan nínú ọ̀pọ̀ ọ̀nà tí a fi ń yí èrèdí àdúrà padà. Ọlọ́run fẹ́ kí àdúrà wa kí ó dá lé ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú òun, àti pé kí á máa mú ìbéèrè wa wá sí ọ̀dọ̀ òun ní ojoojúmọ́ máa ran èyí lọ́wọ́. Kí á máa gbàdúrà ní ojoojúmọ́ fún àwọn àìní wa jẹ́ ọ̀nà sí ìbáṣepọ̀ ayérayé.
Ní àkótán, jẹ́ kí n tọ́ka sí ohun kan tí ó wà láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin Àdúrà Olúwa: ọ̀rọ̀ kékeré yẹn wa. Ó sì ṣe pàtàkì púpọ̀. Ó rọrùn kí àfojúsùn àdúrà wa jẹ́ ara wa ṣùgbọ́n èyí kìí ṣe àfojúsùn Májẹ̀mú Tuntun. A ní láti pinnu láti tẹ̀lé Krístì kí a sì da ara pọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olóríjorí; ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí Krìstẹ́nì a ní láti rí ara wa gẹ́gẹ́ bí ara àwùjọ kan. Nígbà tí a ba ń gbàdúrà, kí á máa gbàdúrà fun àwọn tí a ní ìsopọ̀ pẹ̀lú: àwọn ẹbí tiwa nínú ara àti àwọn ẹbí wa nínú ẹ̀mí. Àti ní pàápàá, ó jẹ́ ohun tí ó dára láti máa gbàdúrà fún àwọn ọ̀rẹ̀, alábàáṣiṣẹ́pọ̀ àtí aládùgbóò wa pẹ̀lú.
Níkẹyìn, nígbà tí Ọlọ́run bá fún wa ní 'àkàrà' ojoojúmọ́ wa – àti pé, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà yó jù bẹ́ẹ̀yẹn lọ – ẹ jẹ́ kí á dúpẹ́.
Nípa Ìpèsè yìí

Da ara pọ̀ mọ́ J.John l'órí ìkẹ́ẹ̀kọ́ ọjọ́ mẹ́jọ l'órí Àdúrà Olúwa, ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ Jésù tí ó ya'ni l'ẹ́nu tí ó sì ṣe ìrànlọ́wọ́ l'órí kíkọ́ni bí ó ṣe yẹ kí a gba àdúrà.
More