Àdúrà OlúwaÀpẹrẹ

Ìyìn
Ọ̀wọ̀ ni fún orúkọ Rẹ̀
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn gbólóhùn àdúrà Olúwa náà ṣe tààràtà, ṣùgbọ́n ẹyọkan tí ó gbà èrò ni ọ̀wọ̀ ni fún orúkọ Rẹ̀. . The New Living Translation sọ pé 'jẹ́ kí orúkọ Rẹ̀ jẹ́ mímọ,' èyí tí ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa pẹ̀lú. Ó tún lè jẹ́ ìrànlọ́wọ́ láti mọ̀ pé nínú Bíbélì, láti sọ ọ̀rọ̀ nípa orúkọ ẹnìkẹ́ni níí ṣe pẹ̀lú ìtọ́kasí ohun gbogbo tí wọ́n jẹ́ àti tí wọ́n dúró fún. Ní òdodo, a kò jìnà sí eléyìí ni èdè Gèésì ní ìgbà tí a bá sọ wípé 'a ba orúkọ mi jẹ́' tàbí 'orúkọ rẹ gbayì púpọ̀ nínú àwùjo náà'.
Láti bọ̀wọ̀ fún tàbí láti 'ya orúkọ Ọlọ́run sí mímọ́' ni ó dà bíi ohun tí ó rọrùn jù lọ, láti bú ọlá fún Ọlọ́run tàbí láti yín-ín ní ọ̀nà tí Òun àti ohun gbogbo nípa Rẹ̀ ga ju ohun gbogbo tí a jẹ́ lọ. Ó jẹ́ kí ó rán àwa fúnra wa létí pé Ọlọ́run yẹ ní gbígbé ga ju ohun gbogbo lọ. A nílò láti ṣe eléyìí nítorí pé 'ọ́fìfà ẹ̀mí' kan wà tí a fi àyè gbà nínú ayé tí ó ń fà ohun gbogbo wa sílẹ̀, àti Ọlọ́run pẹ̀lú. Fífà Ọlọ́run wa sílẹ̀ yí lè ṣẹlẹ̀ ní gbogbo ìpele. Fún àpẹẹrẹ, ẹnikẹ́ni lè fi ìgboyà sọ wípé nítorí pé wọn 'ń ṣisẹ́ Ọlọ́run,' ìlòdì sì àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ jà sì àtakò sì Ọlọ́run. Ní ọ̀nà kan náà pẹ̀lú mo ní èrò wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wa yíò kọ̀ láti rìn lórí àsíá orílẹ̀ èdè wọn, nítorí náà ṣọ́ra gidigidi nípa ṣíṣe tàbí sísọ ohun tí ó lè jẹ́ àbùkù tàbí jẹ́ àbàwọ́n fún orúkọ Ọlọ́run. Ìbàjẹ̀ púpọ̀ ni a ti ṣe sí ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ nípasẹ̀ àwọn ènìyàn tí wọn ń fi àbùkù kan orúkọ Ọlọ́run nípa àsopọ̀ rẹ pẹ̀lú àwọn òwò tí kò ṣe é gbọ́ sí etí.
Ó ṣe pàtàkì láti rán wa létí pé Àdúrà Olúwa bẹ̀rẹ̀ nípa fífi ọkàn wa sí ọdọ Olúwa fún ra Rẹ̀. Nínú Òfin Mẹ́wàá, a rí i pé àwọn òfin mẹ́rin àkọ́kọ́ níí ṣe pẹ̀lú Ọlọ́run, àwọn mẹ́fà tí ó ṣẹ́kù níí ṣe pẹ̀lú ẹ̀dá ènìyàn. Àdúrà Olúwa ní irú ìlànà kan náà àti pé ó jẹ ìrántí ní ọ̀nà mìíràn pé Ọlọ́run ni ó yẹ kí a gba àdúrà àtọkànwá sì, kìí ṣe àwa ènìyàn.
Láti bẹ̀rẹ̀ àdúrà nípa gbígbé Ọlọ́run s'ókè nínú iyin àti ọlá jẹ́ ọ̀nà tí ó dára jù lọ ní ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀, fún àwọn ìdí púpọ̀:
- Fífi ìyìn fún Ọlọ́run ń rán wa létí nípa òtítọ́ pé àgbáyé wà. Àyíkáyidà wa sì kún fún àwọn aláṣẹ àti ẹnì-kọ̀ọ̀kan tí wọ́n gbà wípé wọn ní agbára lórí gbogbo ohun tí ó kàn wá. Láti yín Ọlọ́run ń rán wa létí pé, ohunkóhun tí ó wù kí a d'ojú kọ bíi ìdààmú ní ojoojúmọ́, Ọlọ́run nìkan ni ó kápá rẹ̀.
- Yínyin Ọlọ́run ń rán wa létí Ẹni tí Ó jẹ́ àti bí àwa náà ṣe jẹ́ pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bíi àfiwé. Pàápàá jù lọ bí a bá mọ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bíi òbí wa tí ó pé nípasẹ̀ Kristi; ní ìgbà tí a bá ń gba àdúrà sí Ọlọ́run ní ìgbà kúùgbà, a kò gbọ́dọ̀ jókòó ní iwájú Rẹ̀ láti bá dọ́gba. Kò kàn jẹ́ wípé ìyìn ń gbé Ọlọ́run sókè nìkan; ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wa ní iwájú Rẹ̀ ni yíò fi wá sí ààyè tí ó tọ́.
- Fífi ìyìn fún Ọlọ́run máà ń gbà wá ní ààyè láti ní àfojúsùn tí ó tọ́. Láti yín Bàbá wa tí mbẹ ní ọ̀run ní ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ àdúrà wa jẹ́ kí a pá ọkàn wa pọ̀ sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nìkan. Ó dà bíi ìwé atọ́ka ìrìn àjò pẹ̀lú irin iṣẹ́ tí ó ń júwe ọ̀nà fún ni tí yíò tọ́ka wa sí àríwá tí ó tọ́. Ohun tí a jẹ́ àti àwọn ohun tí ó kàn wá gbọ̀ngbọ̀n ní agbára púpọ̀ de bí pé ó rọrùn kí àwa gangan jẹ́ àfojúsùn àdúrà wa kí a sì da ohun tí a ń sọ rú, kí ó sì já sí wípé àdúrà wa á fi díẹ̀ dára ju àtòkọ tí a ń mú lọ sí ilé ìtajà. Láì jẹ́ wípé a fi ìyìn gbé àdúrà wa lẹ́sẹ̀, ewu wà ní gbogbo ìgbà pé a kàn wá bá Ọlọ́run tí Ó fi díẹ̀ sàn ju ẹni tí ó lè bá àwọn àìní wá pàdé. Ó wá jọ bíi wípé a gbé òrìṣà kan kalẹ̀ tí ó jẹ́ àgbàyanu oníṣègùn ńlá, ilé ìfowópamọ́ ọrùn tàbí 'ilé ìtajà òfuurufú' ati ẹnì kan tí ó jẹ́ pé ìṣe rẹ̀ fi díẹ̀ ju ẹni tí ó lè wo àìlera wa sàn, kí ó sọ wá di ọlọ́rọ̀ tàbí kí ó fún wa ní ohun tí a ní ìfẹ́ sí.
- Ìyìn á máà rán wa létí ẹni tí Ọlọ́run í se. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Kristẹni ni kò nááni Májẹ̀mú Láíláí, ohun tí kò dára tó nítorí pé ojú àwọn ìwé yìí ni a ti fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún Májẹ̀mú Tuntun nípa ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ gan-an. Nínú Májẹ̀mú Láíláí a rí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bíi Olùsọ́-àgùtàn, Ọba, Onídájọ́, Olùràpadà, Ẹni Mimọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ìyìn tí ó dà lórí Bíbélì fún wa ní ẹ̀tọ́ tí ó kún ojú òṣùwọ̀n tí ó sì jinlẹ̀ nípa ẹni tí Ọlọ́run í ṣe.
- Ìyìn á máà gbé Ọlọ́run sí òkè àti pé yíò gbé sì ibi gíga. Òfin Ilé-ẹ̀kọ́ ọjọ́ ìsinmi àtijọ́ dára àti ọlọ́gbọ́n: 'Ọlọ́run kékeré, ìṣòro nla; Ọlọ́run ńlá, ìṣòro kekere'. Ìyìn á máà gbé Ọlọ́run sí òkè!
Nípa Ìpèsè yìí

Da ara pọ̀ mọ́ J.John l'órí ìkẹ́ẹ̀kọ́ ọjọ́ mẹ́jọ l'órí Àdúrà Olúwa, ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ Jésù tí ó ya'ni l'ẹ́nu tí ó sì ṣe ìrànlọ́wọ́ l'órí kíkọ́ni bí ó ṣe yẹ kí a gba àdúrà.
More