Àdúrà OlúwaÀpẹrẹ

Ànfàní
Baba wa ní ọ̀run
Àṣírí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkan - tí kìí bá ṣe fún gbogbo nkan - nínú ayé jẹ́ ìwọ̀ntúnwọ̀nsì; mímú ohun méjì tàbí ju bẹ́ẹ̀ lọ sí inú ẹdọfu. Fún àpẹẹrẹ, olùpèsè ọlọgbọ́n yíò fẹ́ ṣe ẹ̀dá ọjà kan tí ó dára tí iye rẹ̀ sì ṣe déédé; òbí ọlọ́gbọ́n yóò fẹ́ ṣe ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ìfẹ́ àti ìbáwí, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ṣókí rẹ̀ tí ó wà nínú Àdúrà Olúwa ṣe èyí pẹ̀lú Baba wa ní ọ̀run.
Ní àkọ́kọ́, a rán wa létí pé Ọlọ́run jẹ́ Bàbá. Mo nílò láti sọ ní kíá mọ́sá pé, bí ọ̀pọ̀ ènìyàn òde òní bá ní irú ìrírí tí kò dára bẹ́ẹ̀ nípa jíjẹ́ bàbá, tí ọ̀rọ̀ náà gan-an sì ń mú kí ìfúnpá rẹ ga, ó lè pọn dandan pé kí o ṣiṣẹ́ lé e lórí. Ó lè di dandan fún ọ láti máa rán ara rẹ létí ní ìgbà gbogbo pé Ọlọ́run ni bàbá tí ó dára jù lọ tí o kò mọ̀ rí, tàbí kí o tiẹ̀ máa wò ó gẹ́gẹ́ bíi "òbí pípé"; ẹnì kan tí ó ní ìfẹ̀ẹ́ rẹ tí ó sì fi ọgbọ́n bójú tó ọ kí o lè d'àgbà di ẹni tí ó yẹ kí o jẹ́. Ìṣòro ọ̀rọ̀ bàbá kò yẹ kí ó jẹ́ kí o dí ojú wa sí òtítọ́ náà pé a lè mọ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bíi òbí onífẹ̀ẹ́. A lè mú èrò èyíkéyìí tí a ní nípa Ọlọ́run kúrò gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀dá kan tí ó jẹ́ ẹni tí ó rorò, tí ó ń ṣe ìṣirò, tí ó jẹ́ kámẹ́rà alágbára kan tí ó ń ṣiṣẹ́ ní òkè ọ̀run tàbí kí a mú èrò èyíkéyìí nípa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Olórí Iṣẹ́ Àgbà ní ayé àti ọ̀run kúrò. Jésù sọ pé àdúrà lè ní í ṣe pẹ̀lú àjọṣe ìdílé pẹ̀lú Ọlọ́run, ó sì yẹ kí ó wà bẹ́ẹ̀. Ìyẹn ni pé kí a tó lè ní àjọṣe tí ó ṣe iyebíye yẹn, a gbọ́dọ̀ lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù, kí a sì ti ipa bẹ́ẹ̀ di arákùnrin àti arábìnrin rẹ̀. Òtítọ́ tí ó dára ni ó wà níhìn-ín: láti fi ìgbàgbọ́ rẹ sí inú Kristi láti lè di ẹni tí a gbà sí inú ìdílé Ọlọ́run, àti nípa bẹ́ẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú ìtumọ̀, láti wà nínú ìbátan ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin pẹ̀lú Ọlọ́run. A wà ní ‘ìsopọ̀’ sí àwọn àjọṣepọ̀ tuntun ní ọ̀run àti ní ayé sí àwọn onígbàgbọ́ mìíràn.
Òtítọ́ àgbàyanu yìí ni ìránnilétí náà pé Ọlọ́run wà ní ọ̀run. Olódùmarè ni, ó jẹ́ ẹni mímọ́ pátápátá, a ò sì lè lóye rẹ̀. Ó lóye ohun gbogbo, ó mọ ohun gbogbo, ó dá ohun gbogbo, ó sì ń gbé ohun gbogbo ró. A nílò èyí. Ó rọrùn gan-an láti dá Ọlọ́run tí ó kéré, tí kò tóbi bíi tiwa ní àwòrán ara wa ṣùgbọ́n Ọlọ́run tí ó wà ní ọ̀run: tí ó tóbi tí ó sì ga ju ohunkóhun tí a lè rò lọ.
Nítorí náà, èyí ni ọ̀nà tí ó dára jù lọ láti wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì; a gbọ́dọ̀ ní ohun kan tí a lè pè ní ìbẹ̀rù onífẹ̀ẹ́ tàbí ìfọkànsìn tí ń mú inú ẹni dùn - pè é bí o ṣe fẹ́ - àmọ́ ó jẹ́ ìdàpọ̀ àwọn òtítọ́ àgbàyanu méjì wọ̀nyí. Èyí ṣe pàtàkì nítorí pé ọ̀pọ̀ àwọn onígbàgbọ́, bóyá gbogbo wa pátá, ni àdúrà kì í sábà bá l'ára mu. Nítorí náà, a lè pa agbára àgbáyé Ọlọ́run tì, kí a sì wá máa wò ó bíi pé ọ̀rẹ́ wa kan tí ó ń gbé lókè ọ̀run ni, tí kì í bìkítà rárá nípa ohun tí a bá ṣe. Tàbí kẹ̀, a lè máa fi ojú kéré ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa gẹ́gẹ́ bíi bàbá, kí a sì máa wò ó bí ẹni tí ó jìnà sí wa, tí kò bìkítà nípa wa, tí ó jẹ́ alákòóso ayé òun ọ̀run. Níhìn-ín, Jésù ń kọ́'ni pé ohun tí a ní jẹ́ àǹfààní àgbàyanu: bí a bá ti lo ìgbàgbọ́ wa nínú Kristi, a lè mọ Ọlọ́run ọ̀run nínú gbogbo agbára àti ògo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi òbí onífẹ̀ẹ́, tí ó bìkítà, tí ó sì jẹ́ ẹni pípé. Ẹ ò rí i pé àgbàyanu ni!
Bí a ti ń lo àdúrà yìí ẹ jẹ́ kí a dúró pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ wọ̀nyìí Bàbá wa ni ọ̀run ẹ jẹ́ kí a wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì.
Nípa Ìpèsè yìí

Da ara pọ̀ mọ́ J.John l'órí ìkẹ́ẹ̀kọ́ ọjọ́ mẹ́jọ l'órí Àdúrà Olúwa, ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ Jésù tí ó ya'ni l'ẹ́nu tí ó sì ṣe ìrànlọ́wọ́ l'órí kíkọ́ni bí ó ṣe yẹ kí a gba àdúrà.
More