Àdúrà OlúwaÀpẹrẹ

The Lord's Prayer

Ọjọ́ 7 nínú 8

Ààbò

Má si fà wa sinu ìdánwò, ṣùgbọ́n gbà wa lọwọ́ ẹni búburú náà.

. Bíbélì kàn gbà wípe a wà ninú ìjàkadì pẹlú ibi àti wípé ogún kan wà tí kì í ṣẹ́ ni ìrọ̀rùn tí ó sì táko àwọn ìlànà ẹni ibi, ṣùgbọ́n ibi ni ìrísí tí ènìyàn pẹ̀lú. Díè nínú aburú àti òye agbára ibi tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ayé jẹ nǹkan tí, ó jẹ́ wípé àwọn ènìyàn diẹ ló mọ pé, kò ṣeé fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú, àfi tí wọn ba jẹ́ olùjọ́sìn. Pẹlú ẹrí ibi ni àgbayé lóni eléyìí jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdí ló wà fún àìbìkítà yìí: ibi sábà máa ń jẹ́ àwòkẹ́kọ̀ọ́ (ronu nípa ère ẹni ibi tí a wọ̀ ni aṣọ pupa nínú eré àwòkẹ́kọ́ tí ó mú irin isẹ burúkú dani) tàbí ìlòkulò bíi àwọn iṣẹ̀ ìràpadà tí ó yiwọ́, tàbí àwọn gbólóhùn ìbànújẹ bíi 'èṣù ló mú mí ṣé'.

Ní òtítọ, jẹ́ kí á bẹ̀rẹ̀ pẹlú gbólóhùn iyanilẹ́nú yẹn, ẹní búburú. Ádùrá Olúwa nínú àwọn ẹ̀yà Bíbélì àtijọ ti ní èrò wípé a ‘dá wa nidè kúrò nínú ibi’ bíi ẹni wípé ó jẹ́ iru ipò ìmòye àìrí kan. Àgbájọpọ̀ ìfohùnṣọ̀kan ni wípé, bí ó ti wù kí ó rí, pé ohun tí Jesu ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ níhìn ni ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ ẹni ibí. Nísinsìnyí ọ̀pọlọ́pọ àwọn ọrọ ló jẹyọ níbí àti wípé mo tọ́ka rẹ sí ìwé mí lórí Ádùrá Olúwa fún àlàyé ni kíkún. Síbẹ̀síbẹ̀, ó dà bí ẹni wípé láti jẹ́ irú ‘Onígbàgbọ tí inú Bíbeli’ a ní láti ní ìgbàgbọ wípé àwọn ẹ̀mi búburú kàn wà ninú ayé, ti kò le ba Ọlọ́run dọ́gba láíláí, ṣùgbọ́n síbẹ̀ o ní agbára láti ṣe àtakò Rẹ̀ ati wípé o jẹ onírira àti alágbára alátakò àwọn onígbàgbọ. Ní ododo, ní ayé òde òní, o rọrùn nígba púpọ láti gbàgbọ́ wípé èṣù mbẹ̀ jù láti gbàgbọ́ nínú pé Ọlọ́run rere wá pẹ̀lú

Ẹní búburú náà tí a mẹ́nu bá níbi yí ni ó jẹ́ olùgbọ̀wọ́ fún àdánwò. Eléyìí, pẹ̀lú nílò àbójútó dáradára. Ewú kán ni wípé a léro pé Ọlọ́run fúnra ra Rẹ̀ ni Ó ṣe àdánwò náà àti wípé, nínú Ádùrá Olúwa, a n béèrè ní ọwọ́ Ọlọ́run láti ‘mú kúrò ni’. Bóyá ọnà tí ó dára jùlọ láti wo gbólóhùn yii ní láti ṣe ìyàtọ̀ láàrinìdánwòàtiàdánwò. Ìdánwò, bóyá nípa tí ará tàbí nípa tí ẹ̀mí, jẹ́ ohún tí o dára. Láti yege ìdánwò jẹ́ nkán tí ó ní ìwúrí o sí gbà wa láàyè láti mọ̀ pé a tí dàgbàsókè. Síbẹ̀síbẹ̀, bí Ọlọ́run bá lè lo ìdánwò kan láti mú wa dàgbà, ẹni ibi le sọ ọ́ di àdánwò láti mú wa kọsẹ̀.

Ó lè ṣèrànwọ́ láti ronú pé ohun tí àyọkà yìí ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ ohun kan tí a lè ṣe àpèjúwe re bí àdánwòàti ìdánwò. Láti ìhà Ọlọ́run, ohun tí a ń rí gbà jẹ́ ìdánwò láti fi hàn bí ìgbàgbọ́ wá ṣe dámọ̀ràn to; bí a bá yege ìdánwò náà, yíò le fún wa ní ìṣírí àmì ìdàgbàsókè tí ẹ̀mí wa. Ṣùgbọ́n tí a bá nrò wípé èṣù wa, a lé fí ojú tí ó yátọ wo ìdánwò kánna; bí a bá kùnà, nígbà náà, ó ti ri ọnà kọlu ìgbàgbọ́ Kristẹni wa.

Nitorina kínni ádùrá wa níhin? Ni irọrun a ngbadura wípé, nigbati a ba kọjú sí àdánwò tàbí ìdánwò a óo ṣẹgun a kì yíò ṣubú. A ń gbàdúrà kí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìpèníjà ẹní ibí náà. Jẹ́ ki n pèsè àwọn ìmọràn mẹ́ta níbi.

Ní àkọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ mọ̀ wípé lójoojúmọ́, ní gbogbo ọ̀nà, a ní láti ni ìdojúkọ àwọn àdánwò àti ìdánwò. A sì ní láti wà ní ìmúrasílẹ.

Ekéji ni pé a kò lè kọjú sí ẹni búburú láì dira ogun. Ọlọ́run ti fún àwọn ọmọ rẹ̀ ní Ẹ̀mí Mímọ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Ìwà òmùgọ̀ gbáà ló jẹ́ láti gbìyànjú láti kojú irú àdánwò kan tó burú jáì láìjẹ́ pé a lọ bá ẹni tí Ọlọ́run ti fi fún àwọn ọmọ rẹ̀ láti gbè wọ́n ni ijà.

Ẹ̀kẹ́ta, sì jẹ àrékérekè 'ẹní ibi’ wípé nígbà ti a bá ṣubú - àti pé gbogbo wa lé ṣubú ni àkókò kàn tàbí òmíràn - yío gbìyànjú láti jẹ́ kí a gbàgbọ́ wípé, pẹlú ikunà yìí, o ti parí fún wa pẹlú Ọlọ́run láíláí. Ní tòótọ́, bí a bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run lóòtọ́ nígbà náà bó tilẹ̀ jẹ́ wípé ìkùnà wa láti yege ìdánwò náà lè jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn fún Bàbá wa ti mbẹ ni ọ̀run, kì í ṣe ìdí fún Un láti kọ̀ wá sílẹ̀. Ìkùnà wa láti yege ìdánwò náà kò ní ba àjọṣepọ̀ wa pẹ̀lú Baba wa ọ̀run jẹ́—a jẹ́ ọmọ rẹ̀—ṣùgbọ́n ó mú ìpalára tó dánmọ́rán bá àjọṣepọ̀ wa.

Ààbò

Má si fà wa sinu ìdánwò, ṣùgbọ́n gbà wa lọwọ́ ẹni búburú ná.

.

Bíbélì kàn gbà wípe a wà ninú ìjàkadì pẹlú ibi àti wípé èyí kìí ṣe ogún láti kọjú ija sí awọn ìlànà àìpé lásán kán, ṣùgbọ́n rikiṣi ibi sí ará ẹní. Èròngbà wípé àwọn nkán bíi àkóràn idibajẹ, agbára òye tí ibí tí nṣiṣẹ́ ninú àgbayé lóni jẹ́ ohún kán tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ò fi ọwọ́ pàtàkì mú, àyàfi tí wọ́n bá jẹ́ onísìn. Pẹlú ẹrí ibi ni àgbayé lóni eléyìí jẹ́ ìyàlẹ́nu díẹ sí mi. Oṣeéṣe kí àwọn ìdí mélo kàn wà fún àìbikíta yí: a máa nfi ìgbà púpọ pé èrò ibí gẹ́gẹ́bí àwòrán eré (ro ti bìlísì àwòrán eré ti ó wọ́ ẹ̀wù àwọ̀ pupa tí o mú àwárí dání) tàbí ní ilòkúlo bíi àwọn iṣẹ̀ ìràpadà tí ó yiwọ́, tàbí àwọn gbólóhùn ìbànújẹ bíi 'èṣù ló mú mí ṣé'.

Ní òtítọ, jẹ́ kí á bẹ̀rẹ̀ pẹlú gbólóhùn iyanilẹ́nú yii,ẹní búburú. Ádùrá Olúwa nínú àwọn ẹ̀yà Bíbélì àtijọ ti ní èrò wípé a ‘dá wa nidè kúrò nínú ibi’ bíi ẹni wípé ó jẹ́ iru ipò ìmòye àìrí kan. Ìfohùnṣọ̀kan gbogboo wa, bí ó ti wù kí ó rí, pé ohun tí Jesu ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ níhìn-ín ni ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ ẹni ibí. Báyìí ọ̀pọlọ́pọ àwọn ọrọ ló wà níbí àti wípé mo tọ́kasi sí ìwé mí lórí Ádùrá Olúwa fún àlàyé síwájú síi. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó dà bí ẹni wípé láti jẹ́ irú ‘Onígbàgbọ tí Bíbeli’ a ní láti ní ìgbàgbọ wípé àwọn ẹ̀mi búburú kàn wà ninú ayé, láíláí ti kò le jẹ ẹgbẹ́ sí Ọlọ́run, ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀ gẹ́ o ní agbára láti lòdì síi ati wípé o jẹ ìrira àti alágbára alátakò sí onígbàgbọ. Ní pàápà, ọnà ti àgbáyé wà nísìsiyìí, o rọrùn nígba púpọ láti gbàgbọ́ wípé èṣù mbẹ̀ jù láti gbàgbọ́ ninu Ọlọ́run rere.

Ẹní búburú yíi ni a dárúkọ gẹgẹbi alárinnà àdánwò. O yẹ kí á ṣọ́ ará lo àpèjúwe yíi náà, paapaa. Ewú kán ni wípé a léro pé Ọlọ́run fúnraarẹ̀ ni Ó ṣe àdánwò náà àti wípé, nínú Ádùrá Olúwa, a n béèrè ní ọwọ́ Ọlọ́run láti ‘rọ̀ọ́ rùn’. Bóyá ọnà tí ó dára jùlọ láti wo gbólóhùn yii ní láti ṣe ìyàtọ̀ láàrinìdánwòàtiàdánwò. Ìdánwò, bóyá nípa tí ará tàbí nípa tí ẹ̀mí, jẹ́ ohún tí o dára. Láti yege ìdánwò jẹ́ nkán tí ó ní ìwúrí o sí gbà wa láàyè láti mọ̀ pé a tí dàgbàsókè. Síbẹ̀síbẹ̀, bí Ọlọ́run bá lè lo ìdánwò kan láti mú wa dàgbà, Bìlísì le sọ ọ́ di àdánwò láti ṣẹ́ wa.

Ó lè ṣèrànwọ́ láti ronú pé ohun tí àyọkà yìí ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ ohun kan tí a lè ṣàpèjúwe bí àdánwòàti ìdánwò. Lójú Ọlọ́run, ohun tí a ń rí gbà jẹ́ ìdánwò láti fi ìjẹ́pàtàkì ìgbàgbọ́ wa hàn; bí a bá yege ìdánwò náà, yíò le fún wa ní ìṣírí àmì ìdàgbàsókè tẹ̀mí wa yìí. Ṣùgbọ́n tí a bá nrò wípé èṣù wa, a lé fí ojú tí ó yátọ wo ìdánwò kánna; bí a bá kùnà, ó ti ri ọnà kọlu ìgbàgbọ́ Kristẹni wa.

Nitorina kínni ádùrá wa níhin? Ni kíún a ngbadura wípé, nigbati a ba kọjú sí àdánwò tàbí ìdánwò a óo ṣẹgun a kì yíò ṣubú. A ń gbàdúrà kí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìpèníjà ẹní ibí náà. Jẹ́ ki n pèsè àwọn ìmọràn mẹ́ta níbi.

Àkọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ mọ̀ wípé lójoojúmọ́, ní gbogbo ọ̀nà, àwọn àdánwò àti ìdánwò wà tí ń kọjú sí ọ̀dọ̀ wa. A ní láti múra.

Ekéji, a kò kọjú sí ẹni búburú l'aìni ààbò. Ọlọ́run ti fún àwọn ọmọ rẹ̀ ní Ẹ̀mí Mímọ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Ìwà òmùgọ̀ gbáà ló jẹ́ láti gbìyànjú láti kọ ojú irú àdánwò tó burú jáì láìjẹ́ pé a lọ bá ẹni tí Ọlọ́run ti fi fún àwọn ọmọ rẹ̀ láti gbè wọ́n ni ijà.

Ẹ̀kẹ́ta, o jẹ ọgbọngbọ́n ti 'ẹní buburu’ wípé nígbà ti a bá ṣubú - àti pé gbogbo wa lé ṣubú ni àkókò kàn tàbí òmíràn - yío gbìyànjú láti jẹ́ kí a gbàgbọ́ wípé, pẹlú ikunà yìí, o ti parí fún wa pẹlú Ọlọ́run láíláí. Ní tòótọ́, bí a bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run lóòtọ́ nígbà náà bó tilẹ̀ jẹ́ wípé ìkùnà wa láti yege ìdánwò náà ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá Bàbá wa ọ̀run, kì í ṣe ìdí fún un láti kọ̀ wá. Ìkùnà wa láti ṣẹ́pá ìdánwò náà kò ní ba irúfẹ́ àjọṣe wa pẹ̀lú Baba wa ọ̀run jẹ́—a jẹ́ ọmọ rẹ̀—ṣùgbọ́n ó fa ìpalára didánmọ́rán àjọṣe wa.

Nípa Ìpèsè yìí

The Lord's Prayer

Da ara pọ̀ mọ́ J.John l'órí ìkẹ́ẹ̀kọ́ ọjọ́ mẹ́jọ l'órí Àdúrà Olúwa, ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ Jésù tí ó ya'ni l'ẹ́nu tí ó sì ṣe ìrànlọ́wọ́ l'órí kíkọ́ni bí ó ṣe yẹ kí a gba àdúrà.

More

A fé láti dúpe lówó J JOHN fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé sí i, jọ̀wọ́ lọ sí: https://canonjjohn.com