Àdúrà OlúwaÀpẹrẹ

Ète
Kí ìjọba Rẹ dé, ìfẹ́ tìrẹ ni kí ó ṣẹ, ní ayé bí ó ti wà ní ọ̀run
Ìbéèrè ńlá méjì ni ó wà ní ìgbésí ayé ẹ̀dá. Ìkíni jẹ́ ti ara ẹni: kíni a dá mi fún? Ìkejì jẹ mọ́ gbogbo ẹ̀dá alààyè: ibo ni ayé ń yí lọ? Àwọn ìbéèrè ‘kíni èrèdí gbogbo rẹ̀?’ ni ìwọ̀nyí, gbogbo rẹ̀ ló sì ṣe pàtàkì. Lẹ́hinna, pẹ̀lú ìbànújẹ́ àti ìlọra, ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ti gbà wípé kò sí ète yálà fún ìyè àti gbogbo àgbáyé. Àti wípé ó jẹ́ ohun tí ó jẹ́ ìyàlẹ́nu àti ìbànújẹ́ wípé àwọn kan gbàgbọ́ pé kò sí ìwàláàyè fún ẹ̀dá; ó sì jẹ èrò tí ó tàbùkù ìlọsíwájú àti ìpinnu ẹ̀dá. Ohun tí ó dára jùlọ tí o lè ṣe ni láti ló àkókò tí ó ní ọ̀nà tí yíò mú inú rẹ dùn bí ó ti tọ́ àti bí ó ti yẹ.
Gbólóhùn yìí nínú Àdúrà Olúwa sẹ́ sí gbogbo èrò àìní-túmọ̀ yí dípò bẹ́ẹ̀ ó pèsè ète fún àwa ènìyàn àti gbogbo àgbáyé. Ní ibí yìí Jésù tọ́ka si ìjọba àti ẹ̀kún rẹ̀ Ó sì fi idi rẹ múlẹ̀ pé ìjọba Ọlọ́run àti ìjọba ọ̀run jẹ ọkanna. Ibí yìí máa ń fẹ́ dàrú mọ́ ọ̀pọ̀ olùka Bíbélì lójú diẹ nítorí àwọn ibi mélòó kan ni wọ́n ti mẹ́nu ba ìjọba náà nínú Májẹ̀mú Láéláé àti wípé kò tún wọ̀pọ̀ tí ó bá ti ré kọjá ìwé Mátíù, Máàkù àti Lúùkù. Síbẹ̀síbẹ̀, òtítọ́ ibẹ̀ ni pé Májẹ̀mú Láéláé kò sọ̀rọ̀ lọ títí nípa ìjọba, ó sọ̀rọ̀ nípa Ọba náà lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà. Níbẹ̀ Ọlọ́run jẹ́ Ọba gbogbo àgbáyé ìṣòro àwọn ẹ̀dá ènìyàn sì ni wípé wọ́n kò naani òfin rẹ̀; wọ́n sì ṣe ọ̀tẹ̀ sí Ọba náà àti ìjọba rẹ̀.
Májẹ̀mú Titun wá mú àwọn èrò yí ó sì wá tan ìmọ́lẹ̀ síi wípé nísinsìnyí, bí Jésù ti dé, ìjọba náà ti wà ní àrọ́wọ́tó mùtúmùwà. Ibi gbogbo ni ìjọba náà wà – àti ohunkóhun tí ó bá wà láàyè – tí ó wà lábẹ́ àṣẹ Jésù; ó jẹ́ gbogbo ibi tí ìṣàkóso Ọlọ́run ti ṣe ìtẹ́wọ́gbà nínú ayé àwọn ọkùnrin àti obìnrin. Láti wà nínú ìjọba náà túmọ̀ sí jíjẹ́ ènìyàn tàbí wíwà níbi tí àṣẹ Ọlọ́run ti ṣe ìtẹ́wọ́gbà àti ibi tí a tí mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Lákòókò naa ọ̀run nìkan ni irúfẹ́ ǹkan yìí ti ń ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan a ti ṣe ìlérí fún wa wípé ọ̀tẹ̀ ẹ̀dá ènìyàn ma wá sí òpin bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àgbá-ńlá-ayé ma ṣe ìgbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run.
Èrò yí nípa ìjọba náà ṣe pàtàkì nítorí àwa ẹ̀dá ènìyàn a máa ronú wípé ìwàláàyè wá kò jẹ mọ́ ohun ti ẹ̀mí àti wípé a wá ní òmìnira. Ní òdodo ipò tí Bíbélì ni wípé kò sí àyè fún ìdúró gangan láì faragbúnra: ojú ogun ni ilé ayé níbi tí àwọn ènìyàn ibi àti agbára búburú (tí a máa sọ̀rọ̀ rẹ̀ tó bá yá) ti ń sá ipá, tàbí gbìyànjú láti sá ipá, àti àṣẹ lórí ohun gbogbo tí a dá. Nígbà tí ẹnì kan bá fi ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ sínú Jésù tí ó sì di Kristẹni, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ǹkan ni ó máa ṣẹlẹ̀; ọ̀kan tó ṣe pàtàkì lọ́nà àrà ni wípé ìṣòòótọ́ wọn ma di ti ìjọba Ọlọ́run tó lógo, kúrò nínú ìbárẹ́ pẹ̀lú ayé.
Àdúrà yí, nígbà náà, ni wípé ibi máa di ìtẹ̀mọ́lẹ̀, wípé ní ọjọ́ kan – bóyá ó tilẹ̀ súnmọ́ ju bí a ti lérò lọ – ayé yìí ma wà ní ipele kan tí àwọn ǹkan tí yóò máa ṣẹlẹ̀ ni rere, àwọn ǹkan tí ó tọ́ tí ó sì ń mú ìdùnnú wá nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọlọ́run. Àwọn ohùn àti ariwo rògbòdìyàn ayé yìí yíò dákẹ́ fún orin dídùn pípé ti ọ̀run.
Botilejepe a gbọ́dọ̀ fi ọjọ́ ọ̀la àgbá-ńlá-ayé ṣe àfojúsùn wa kí a sì máa pòǹgbẹ fún ọjọ́ ńlá nì tí ohun gbogbo yíò wà dáradára títí ayérayé, síbẹ̀ a gbọ́dọ̀ máa gbé ìgbé ayé wa lati ọjọ́ de ọjọ́ kó tó di ìgbà yẹn. Láti gba apá Àdúrà Olúwa yìí túmọ̀ sí wípé àwa fúnra wa gbọ́dọ̀ ṣe ìpinnu kí a sì gbé ìgbésẹ̀ láti ṣúgbàá Ọba náà àti ìjọba rẹ̀. A lè gbàdúrà fún, àti lòdì sí, àwọn ǹkan. Fún ìdí èyí, a gbọ́dọ̀ gbàdúrà fún àwọn ǹkan tí ń mú àwọn àmúyẹ ìjọba náà jẹyọ: fún àpẹrẹ, àwọn ìṣe ojú rere àti àánú àti àwọn ọ̀rọ̀ òtítọ́ àti ore ọ̀fẹ́. A tún lè gbàdúrà lòdì sí àwọn ǹkan tí ń tako ìjọba Ọlọ́run: bí ojúkòkòrò, àránkan, ìfẹ́kúùfẹ́ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Dájúdájú, a kò gbọ́dọ̀ ṣe ségesège. A kò lè gbàdúrà pé kí àwọn àmúyẹ ìjọba náà kí ó jẹ yọ nínú ayé àwọn alábàáṣiṣẹ́ àti alábàágbé wa láìṣe pé àwa fúnra wa gbìyànjú láti so èso ìjọba náà nínú ayé wa.
Gbígba ìsọ̀rí Àdúrà Olúwa yìí pẹ̀lú ìtumọ̀ nííṣe pẹ̀lú wíwo ohun gbogbo nínú ayé wa àti àyíká wa kí a wá sọ nípa gbogbo rẹ̀ wípé ‘Olúwa, gba ìṣàkóso: jẹ́kí ayé yìí dàbí ọ̀run kí ìgbésí ayé wa sì dà bíi ti ọ̀run!’
Ète
Kí ìjọba Rẹ dé, ìfẹ́ tìrẹ ni kí ó ṣẹ, ní ayé bí ó ti wà ní ọ̀run
Ìbéèrè ńlá méjì ni ó wà ní ìgbésí ayé. Ìkíni jẹ́ ti ara ẹni: kíni a dá mi fún? Ìkejì jẹ mọ́ gbogbo ẹ̀dá alààyè: ibo ni ayé ń yí lọ? Àwọn ìbéèrè ‘kíni èrèdí gbogbo rẹ̀?’ ni ìwọ̀nyí, gbogbo rẹ̀ ló sì ṣe pàtàkì. Bí a ti mọ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ti gbà wípé kò sí ète fún àwa ènìyàn àti gbogbo ìṣẹ̀dá. Àti wípé ó jẹ́ ohun tí ó ṣeni làánú wípé àwọn kan gbàgbọ́ pé kò sí ète fún ìṣẹ̀dá; nítorí ète yìí ni arin gbùngbùn ìlépa àti àfojúsùn ẹ̀dá ènìyàn. Ohun tí ó dára jù lọ tí o lè ṣe ni láti dá ara rẹ ní inú dùn bí ó bá ṣe gbà.
Gbólóhùn yìí nínú Àdúrà Olúwa tàpá sí gbogbo èrò nípa àìsí ète àti wípé àdúrà yí wá ṣe àfihàn ète fún àwa ènìyàn àti gbogbo àgbáyé. Ní ibí yìí Jésù sọ̀rọ̀ nípa ìjọba ó sì ṣe pàtàkì fún wa láti ṣe àkíyèsí wípé ọ̀kan ni ìjọba Ọlọ́run àti ìjọba Ọ̀run. Ibí yìí máa ń fẹ́ dàrú mọ́ ọ̀pọ̀ olùka Bíbélì lójú nítorí àwọn ibi mélòó kan ni wọ́n ti mẹ́nu ba ìjọba náà nínú Májẹ̀mú Láéláé àti wípé kò tún wá pọ̀ tó àtẹ̀yìnwá látinú ìwé Mátíù, Máàkù àti Lúùkù síwájú. Àmọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ wípé Májẹ̀mú Láéláé kò sọ̀rọ̀ lọ títí nípa ìjọba, síbẹ̀ ó sọ̀rọ̀ nípa Ọba náà lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà. Níbẹ̀ Ọlọ́run jẹ́ Ọba gbogbo àgbáyé ìṣòro àwọn ẹ̀dá ènìyàn sì ni wípé wọ́n ń tàpá sí òfin rẹ̀; a ti ṣe ọ̀tẹ̀ sí Ọba náà àti ìjọba rẹ̀.
Májẹ̀mú Titun wá mú àwọn èrò yí ó sì wá tan ìmọ́lẹ̀ síi wípé nísinsìnyí, bí Jésù ti dé, ìjọba náà ti wà ní àrọ́wọ́tó mùtúmùwà. Ibi gbogbo ni ìjọba náà wà – àti ìṣẹ̀dá kàànkan – tí ó wà lábẹ́ àṣẹ ti Jésù; ó jẹ́ gbogbo ibi tí ìjọba Ọlọ́run ti ṣe ìtẹ́wọ́gbà nínú ayé àwọn ọkùnrin àti obìnrin. Àti wà nínú ìjọba náà túmọ̀ sí jíjẹ́ ènìyàn tàbí wíwà níbi tí àṣẹ Ọlọ́run ti ṣe ìtẹ́wọ́gbà àti tí ìfẹ́ rẹ̀ ti ṣẹ. Lákòókò yí ọ̀run nìkan ni irúfẹ́ ǹkan yìí ti ń ṣẹlẹ̀, àmọ́ ní ọjọ́ kan a ti ṣe ìlérí fún wa wípé ọ̀tẹ̀ ẹ̀dá ènìyàn ma wá sí òpin bẹ́ẹ̀ni gbogbo àgbá-ńlá-ayé ma ṣe ìgbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run.
Èrò yí nípa ìjọba náà ṣe pàtàkì nítorí àwa ẹ̀dá ènìyàn a máa ronú wípé inú òfìfo ti ẹ̀mí ni a wà níbi tí a ti lè ṣe bí ó ti wù wá. Àmọ́ ohun tí Bíbélì sọ ni wípé kò sí òfìfo: gbàgede ogun ni ilé ayé níbi tí àwọn agbára ibi àti ẹni ibi nì (tí a máa sọ̀rọ̀ rẹ̀ tó bá yá) ti ń sá ipá, tàbí gbìyànjú láti sá ipá, àti àṣẹ lórí ohun gbogbo. Nígbà tí ẹnì kan bá fi ìrètí rẹ̀ sínú Jésù tí ó sì di Kristẹni, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ǹkan ni ó máa ṣẹlẹ̀; ọ̀kan tó ṣe pàtàkì lọ́nà àrà ni wípé ìṣòòótọ́ wọn ma di ti ìjọba Ọlọ́run tó lógo, kúrò nínú ìbárẹ́ pẹ̀lú ayé.
Àdúrà yí, nígbà náà, ni wípé ibi máa di ìtẹ̀mọ́lẹ̀, wípé ní ọjọ́ kan – bóyá ó tilẹ̀ súnmọ́ ju bí a ti lérò – ayé yìí ma wà ní ipele kan tí àwọn ǹkan tí yóò máa ṣẹlẹ̀ ni rere, àwọn ǹkan tí ó tọ́ tí ó sì ń mú ìdùnnú wá nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọlọ́run. Àwọn ohùn àti ariwo ayé yìí ma dákẹ́ fún orin àdídùn ti ọ̀run.
Lóòótọ́ ni a gbọ́dọ̀ fi ọjọ́ ọ̀la àgbá-ńlá-ayé ṣe àfojúsùn wa kí a sì máa pòǹgbẹ fún ọjọ́ ńlá nì tí ohun gbogbo yóò wà dáradára títí ayérayé, síbẹ̀ a gbọ́dọ̀ máa ṣe àkíyèsí òní kó tó di ìgbà yẹn. Láti gba apá Àdúrà Olúwa yìí túmọ̀ sí wípé àwa fúnra wa gbọ́dọ̀ ṣe ìpinnu kí a sì gbé ìgbésẹ̀ láti ṣúgbàá Ọba náà àti ìjọba rẹ̀. A lè gbàdúrà fún, àti lòdì sí, àwọn ǹkan. Fún ìdí èyí, a gbọ́dọ̀ gbàdúrà fún àwọn ǹkan tí ń mú àwọn àmúyẹ ìjọba náà jẹyọ: fún àpẹrẹ, àwọn ìṣe ojú rere àti àánú àti àwọn ọ̀rọ̀ òtítọ́ àti ore ọ̀fẹ́. A tún lè gbàdúrà lòdì sí àwọn ǹkan tí ń tako ìjọba Ọlọ́run: bí ojúkòkòrò, ìránkan, ìfẹ́kúùfẹ́ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Ní òtítọ́, a kò gbọ́dọ̀ rẹ̀wẹ̀sì. A kò lè gbàdúrà pé kí àwọn àmúyẹ ìjọba náà kí ó jẹ yọ nínú ayé àwọn alábàáṣiṣẹ́ àti alábàágbé wa láìṣe pé àwa fúnra wa gbìyànjú láti so èso ìjọba náà nínú ayé wa.
Gbígba ìsọ̀rí Àdúrà Olúwa yìí pẹ̀lú ìtumọ̀ nííṣe pẹ̀lú wíwo ohun gbogbo nínú ayé wa àti àyíká wa kí a wá sọ nípa gbogbo rẹ̀ wípé ‘Olúwa, gba ìṣàkóso: jẹ́kí ayé yìí dàbí ọ̀run kí ìgbésí ayé wa sì dà bíi ti ọ̀run!’
Nípa Ìpèsè yìí

Da ara pọ̀ mọ́ J.John l'órí ìkẹ́ẹ̀kọ́ ọjọ́ mẹ́jọ l'órí Àdúrà Olúwa, ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ Jésù tí ó ya'ni l'ẹ́nu tí ó sì ṣe ìrànlọ́wọ́ l'órí kíkọ́ni bí ó ṣe yẹ kí a gba àdúrà.
More