Àdúrà OlúwaÀpẹrẹ

Àṣeṣáájú
Nítorí náà, bí ó ti yẹ kí ẹ máa gba àdúrà nìyí . . .
Fí ojú inú wò ó pé o jẹ́ aludùùrù tàbí atagìtá, tí ó ń sapá láti kọ́ orin kan tí ó dà bíi pé kò rọrùn fún ọ láti kọ. Fí ojú inú wò ó pé olórin náà ṣà dédé yọ sí ọ ní òjijì, ó sì dúró ní ẹ̀gbẹ́ẹ̀ rẹ. "Báyìí," wọ́n rọra sọ fún ọ, "ni bí oó ṣe fi ọwọ́ rẹ sí ibí yìí. . . báyìí ni o ṣe máa kọ gbólóhùn tọ̀hún," a sì fi hàn ọ́ ní pàtó ibi àti ìgbà tí ó máa gbé ìka rẹ sí. Wàá dúpẹ́ gan-an fún irú ìtọ́ni bẹ́ẹ̀! Bí orin kì í bá ṣe ohun tí ó wù ọ́, fi ojú inú wo ohun tí ó jọ ọ́ nínú eré ìdárayá, kí wọ́n máa gun òkè, kí wọ́n máa sọ ọ̀rọ̀ ní iwájú àwùjọ tàbí kí wọ́n máa wa ọkọ̀. Ìtọ́sọ́nà tí ó dá lórí ìmọ̀ pípé, ọlá àṣẹ kíkún àti sùúrù tí kò láàlà.
Níbí nínú Àdúrà Olúwa a ní ní nǹkan bíi ọ̀rọ̀ 70 – tí ó sún mọ́ gígùn lẹ́ta 280– ìtọ́sọ́nà tí Jésù fúnra rẹ̀ fún wa nípa bí a ṣe lè bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀. Èyí ni kíkọ́ni nípa kókó tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ní ayé, nípa ọkùnrin tí ó mọ̀ nípa rẹ̀ jù lọ. Èyí jẹ́ ìdí tí ó fi yẹ kí fiyè sí Àdúrà Olúwa.
Àdúrà sì ṣe pàtàkì! Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àdúrà dà bíi nọ́ńbà pàjáwìrì tí ó wà ní orí tẹlifóònù wọn; ní ìgbà tí wàhálà tàbí ìnira bá dé, wọ́n máa ń ké pe Ọlọ́run. Ọlọ́run nínú oore rẹ̀ máa ń ràn wá lọ́wọ́ nínú irú ipò bẹ́ẹ̀ ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun kan ṣoṣo tí àdúrà wà fún. Bí á ṣe máa rí i nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí, àdúrà ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tí ó dára pẹ̀lú Ọlọ́run, nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó ń jẹ́ kí a gbé àwa àti àwọn ìṣòro wá yẹ̀ wò. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé gbogbo wa ni a ti ní ìrírí pé a sún mọ́ ẹnì kan rí, ó lè jẹ́ òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ tàbí aládùúgbò rẹ, ṣùgbọ́n a máa ń rò pé a mọ̀ wọ́n dáadáa lẹ́yìn tí a bá ti bá wọn ní ojúlówó ìjíròrò. Bí àdúrà ṣe rí nìyẹn: ó ń jẹ́ kí a sún mọ́ Ọlọ́run, ó máa ń mú kí a wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀, kí a lè ní ìpìn nínú àwọn ète rẹ̀, ó sì ń mú kí àwọn ohun tí ó jẹ ẹ́ ní ogún di tiwa.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èníyàn ni ó máa ń ka Àdúrà Olúwa ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, mi ò rò pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ní ní ọkàn láti lò ó fún. Àdúrà àwòṣe ni mo kà á sí, àpẹẹrẹ bí a ó ṣe máa gba àdúrà. Bóyá ọ̀nà tí ó dára jù lọ láti ronú nípa rẹ̀ ni bíi ètò lẹ́sẹẹsẹ; àwọn ìgbésẹ̀ tí a ṣe àgbékalẹ̀ àkọ́lé rẹ̀ l'áti tọ́ wa sí ọ̀nà bí á ṣe ń bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀.
Àdúrà tí ó mú iná dé oko ń mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run jinlẹ̀ sí i. Ó ń mú ìdarapọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run pẹ́ títí. Ó ń fi ìpìlẹ̀ lé ilẹ̀ nínú ìmọ́lẹ̀ tí a lè nílò ní ìgbà tí òkùnkùn bá ṣú. Kò sí bí mo ṣe lè tẹ ẹnu mọ́ bí àdúrà ti ṣe pàtàkì tó. Tí o bá fẹ́ ṣe àyẹ̀wò ẹ̀mí, àyẹ̀wò kan péré ni ó pọn dandan: bi ara rẹ wí pé, "Báwo ni àdúrà gbígbà mí ṣe dára tó?" Ní ti ohun tí a ṣe àti ohun tí a jẹ́, àdúrà ni ohun tí ó ń dín agbára kù jù lọ; kò sí kristẹni tí ó lè ṣe ju ohun tí àdúrà rẹ̀ lè fún-un láyè láti ṣe lọ.
Nípa Ìpèsè yìí

Da ara pọ̀ mọ́ J.John l'órí ìkẹ́ẹ̀kọ́ ọjọ́ mẹ́jọ l'órí Àdúrà Olúwa, ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ Jésù tí ó ya'ni l'ẹ́nu tí ó sì ṣe ìrànlọ́wọ́ l'órí kíkọ́ni bí ó ṣe yẹ kí a gba àdúrà.
More