Obadiah Ìfáàrà

Ìfáàrà
Ìfáàrà sí ìwé Wòlíì Obadiah
Obadiah ìránṣẹ́ Olúwa sọ nípa ìṣubú tó ń bọ̀ wá sórí Edomu. Ó jẹ́ kí a rí i pé Edomu gbéraga lórí ààbò rẹ̀. Níwọ́n ìgbà tí Edomu ti ṣe èyí, wọn ṣe ohun tó burú níwájú Olúwa, Ọlọ́run sì mú ìbínú wa sórí wọn. Olúwa wí pé òun yóò pa wọ́n run, ṣùgbọ́n òun yóò gba orí òkè Sioni àti Israẹli là, ìjọba Ọlọ́run yóò sì fi ẹsẹ̀ múlẹ̀.
Kókó kan pàtàkì ti ìwé yìí fẹ́ kí a mọ́ ní pe, Edomu kùnà pátápátá, wọn kò ran Israẹli lọ́wọ́, wọ́n sì dá ìjà sílẹ̀. Nítorí pé Ọlọ́run kọ Esau, kò sì ṣí ọ̀nà tí yóò fi gbé àwọn ọmọ Edomu ga. Edomu sá wọ inú òkè agbára lọ, wọn kì yóò sì ní ibùgbé. Ṣùgbọ́n Israẹli yóò ṣe rere nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.
Kókó-ọ̀rọ̀
Àkọlé àti ìbẹ̀rẹ̀ 1.
Ìdájọ́ lórí Edomu 2-14.
Ọjọ́ Olúwa 15-21.

ទើបបានជ្រើសរើសហើយ៖

Obadiah Ìfáàrà: BMYO

គំនូស​ចំណាំ

ចែក​រំលែក

ចម្លង

None

ចង់ឱ្យគំនូសពណ៌ដែលបានរក្សាទុករបស់អ្នក មាននៅលើគ្រប់ឧបករណ៍ទាំងអស់មែនទេ? ចុះឈ្មោះប្រើ ឬចុះឈ្មោះចូល