Amosi Ìfáàrà

Ìfáàrà
Ìfáàrà sí ìwé Wòlíì Amosi
Ohun tí gbogbo ìwé yìí dálé lórí ni ó wà nínú orí karùn-ún ẹsẹ kẹrìnlélógún “Jẹ́ kí òtítọ́ sàn bí odò àti òdodo bí ìsun tí kò lé è gbẹ!” Ìdájọ́ àti òdodo Ọlọ́run ni Amosi tẹpẹlẹ mọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀, nígbà tí ó jẹ́ pé Hosea tẹpẹlẹ mọ ìfẹ́ Ọlọ́run, oore-ọ̀fẹ́, àánú ti ìdáríjì. Amosi ṣàlàyé pé Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ aláìṣòótọ́, aláìgbọ́ràn àti àwọn tó ba májẹ̀mú rẹ̀ jẹ́. Amosi tún bá gbogbo àwọn tí wọn pe ara wọn ní alágbára àti ọlọ́rọ̀ lórí àwọn ènìyàn tókù wí. Ó ṣàlàyé pe gbogbo àwọn tí ó kọ́ ilé iyebíye, tí wọn sì ni àwọn ohun àlùmọ́nì tí ó ni iye lórí nínú ilé náà pẹ̀lú ìrẹ́jẹ, tí wọ́n sì ti pa àwọn aláìní run yóò pàdánù gbogbo ohun tí wọ́n ní.
Ìwé yìí jẹ́ kí ó yé wa wí pé ìdájọ́ Ọlọ́run lórí Israẹli kì í ṣe ìkìlọ̀ bí i ti àtẹ̀yìnwá mọ́, bíkòse ìdájọ́ ìparun pátápátá. Àwọn Israẹli kò ro èyí, nítorí pé wọn kò fi ayé wọn fún Olúwa mọ́, Ọlọ́run yóò fa àwọn ènìyàn rẹ̀ tu kúrò lórílẹ̀-èdè ìbọ̀rìṣà. Olúwa ni ọjọ́ iwájú rere fún àwọn ènìyàn rẹ̀, Ọlọ́run Israẹli, Olúwa tó ní ìtàn, kò ní gbàgbé àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ tàbí àwọn tó ti yàn fún ìràpadà. Amosi tún jẹ́ kí a mọ títóbi Ọlọ́run, ó fi yé ni pé Ọlọ́run tí ó tóbi ni, òun ni ọba àwọn ọba ó sì ju gbogbo ẹ̀dá ayé lọ.
Kókó-ọ̀rọ̀
Ìṣẹ̀dá Amosi 1.1.
Ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ Amosi 1.2.
Ìdájọ́ lórí àwọn orílẹ̀-èdè 1.3–2.16.
Ìdájọ́ lórí Israẹli 3.1–5.17.
Àwọn ìkéde fún ìgbèkùn 5.18–6.14.
Ìfihàn ohun rere 7.1–9.10.
Dídá ìbùkún àwọn ọmọ Israẹli padà 9.11-15.

ទើបបានជ្រើសរើសហើយ៖

Amosi Ìfáàrà: BMYO

គំនូស​ចំណាំ

ចែក​រំលែក

ចម្លង

None

ចង់ឱ្យគំនូសពណ៌ដែលបានរក្សាទុករបស់អ្នក មាននៅលើគ្រប់ឧបករណ៍ទាំងអស់មែនទេ? ចុះឈ្មោះប្រើ ឬចុះឈ្មោះចូល