“Ọjọ́ náà ń bọ,” ni OLúWA wí,
“tí ẹni tí ń tulẹ̀ yóò lé ẹni tí ń kórè bá
Tí ẹni tí ń fún èso àjàrà yóò lé ẹni tí ń gbìn bá
Àwọn òkè ńlá yóò sì kán ọtí wáìnì sílẹ̀
Tí yóò sì sàn láti ara àwọn òkè kéékèèkéé.
Èmi yóò si tún mú ìgbèkùn Israẹli ènìyàn mi padà bọ̀.