YouVersion Logo
Search Icon

JẸNẸSISI 11

11
Ilé Ìṣọ́ Babeli
1Nígbà kan èdè kan ṣoṣo ni ó wà láyé, ọ̀rọ̀ bíi mélòó kan ni gbogbo wọ́n sì ń lò. 2Bí àwọn eniyan ṣe ń ṣí káàkiri ní ìhà ìlà oòrùn, wọ́n rí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú ní agbègbè Babiloni, wọ́n sì tẹ̀dó sibẹ. 3Wọ́n sọ fún ara wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á ṣe bíríkì, kí á sì sun wọ́n jiná dáradára.” Bíríkì ni wọ́n lò dípò òkúta, wọ́n sì lo ọ̀dà ilẹ̀ dípò ọ̀rọ̀. 4Wọ́n sọ fún ara wọn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á kọ́ ìlú ńlá kan, kí á sì kọ́ ilé ìṣọ́ gíga kan tí orí rẹ̀ yóo kan ojú ọ̀run gbọ̀ngbọ̀n, kí á baà lè di olókìkí, kí á má baà fọ́n káàkiri orí ilẹ̀ ayé.”
5OLUWA sọ̀kalẹ̀ láti wo ìlú tí àwọn ọmọ eniyan ń tẹ̀dó ati ilé ìṣọ́ gíga tí wọn ń kọ́. 6OLUWA wí pé, “Ọ̀kan ni gbogbo àwọn eniyan wọnyi, èdè kan ṣoṣo ni wọ́n sì ń sọ, wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ àwọn ohun tí wọn yóo ṣe ni, kò sì ní sí ohun kan tí wọn bá dáwọ́lé láti ṣe tí yóo dẹtì fún wọn. 7Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á sọ̀kalẹ̀ lọ bá wọn, kí á dà wọ́n ní èdè rú, kí wọn má baà gbọ́ èdè ara wọn mọ́.” 8Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe fọ́n wọn káàkiri sí gbogbo orílẹ̀ ayé, wọ́n pa ìlú náà tí wọn ń tẹ̀dó tì. 9Ìdí nìyí tí wọ́n ṣe pe orúkọ ìlú náà ní Babeli, nítorí níbẹ̀ ni OLUWA ti da èdè gbogbo ayé rú, láti ibẹ̀ ni ó sì ti fọ́n wọn káàkiri gbogbo orílẹ̀ ayé.
Àwọn Ìran Ṣemu
(1Kron 1:24-27)
10Àkọsílẹ̀ ìran Ṣemu nìyí: ọdún keji lẹ́yìn tí ìkún omi ṣẹlẹ̀, tí Ṣemu di ẹni ọgọrun-un (100) ọdún ni ó bí Apakiṣadi. 11Lẹ́yìn tí Ṣemu bí Apakiṣadi tán, ó tún gbé ẹẹdẹgbẹta (500) ọdún sí i láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
12Nígbà tí Apakiṣadi di ẹni ọdún marundinlogoji ni ó bí Ṣela. 13Ó tún gbé ọdún mẹtalenirinwo (403) sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Ṣela, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
14Nígbà tí Ṣela di ẹni ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Eberi. 15Ó tún gbé ọdún mẹtalenirinwo (403) sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Eberi tán, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
16Nígbà tí Eberi di ẹni ọdún mẹrinlelọgbọn ni ó bí Pelegi. 17Eberi tún gbé ojilenirinwo ó dín mẹ́wàá (430) ọdún sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Pelegi tán, ó tún bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
18Nígbà tí Pelegi di ẹni ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Reu. 19Ó tún gbé igba ọdún ó lé mẹsan-an (209) sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Reu, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
20Nígbà tí Reu di ẹni ọdún mejilelọgbọn ni ó bí Serugi. 21Ó tún gbé igba ọdún ó lé meje (207) sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Serugi, ó sì tún bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
22Nígbà tí Serugi di ẹni ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Nahori. 23Ó tún gbé igba (200) ọdún sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Nahori, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
24Nígbà tí Nahori di ẹni ọdún mọkandinlọgbọn ni ó bí Tẹra. 25Ó tún gbé igba ọdún ó lé mọkandinlogun (219) sí i láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
26Nígbà tí Tẹra di ẹni aadọrin ọdún ni ó bí Abramu, Nahori, ati Harani.
Àwọn Ìran Tẹra
27Àkọsílẹ̀ ìran Tẹra nìyí: Tẹra ni baba Abramu, Nahori ati Harani. Harani sì ni baba Lọti. 28Harani kú ṣáájú Tẹra, baba rẹ̀, Uri ìlú rẹ̀, tí ó wà ní ilẹ̀ Kalidea ni ó kú sí. 29Abramu ati Nahori ní iyawo, Sarai ni orúkọ iyawo Abramu, orúkọ iyawo ti Nahori sì ni Milika, ọmọbinrin Harani. Harani ni baba Milika ati Isika. 30Àgàn ni Sarai, kò bímọ.
31Tẹra mú Abramu ọmọ rẹ̀, ati Lọti, ọmọ Harani tíí ṣe ọmọ Tẹra, ati Sarai aya Abramu, ó kó gbogbo wọn jáde kúrò ní Uri ti ilẹ̀ Kalidea, wọ́n ń lọ sí ilẹ̀ Kenaani. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé Harani, wọ́n tẹ̀dó sibẹ. 32Nígbà tí Tẹra di ẹni igba ọdún ó lé marun-un (205), ó kú ní ilẹ̀ Harani.

Currently Selected:

JẸNẸSISI 11: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy