YouVersion Logo
Search Icon

JẸNẸSISI 10

10
Ìran Àwọn Ọmọ Noa
(1Kron 1:5-23)
1Ìran Noa nìyí: àwọn ọmọ rẹ̀ ni Ṣemu, Hamu ati Jafẹti. Lẹ́yìn ìkún omi, àwọn mẹtẹẹta bí ọmọ tiwọn.
2Àwọn ọmọ Jafẹti ni: Gomeri, Magogu, Madai, Jafani, Tubali, Meṣeki ati Tirasi. 3Àwọn ọmọ Gomeri ni: Aṣikenasi, Rifati, ati Togama. 4Àwọn ọmọ Jafani ni: Eliṣai, Taṣiṣi, Kitimu ati Dodanimu. 5Àwọn ni baba ńlá àwọn tí wọn ń gbé etí òkun ati àwọn erékùṣù, tí wọ́n tàn káàkiri. Àwọn ọmọ Jafẹti nìwọ̀nyí ní ìdílé ìdílé wọn, olukuluku ní agbègbè tirẹ̀. Oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè ni wọ́n, wọ́n sì ń sọ oríṣìíríṣìí èdè.
6Àwọn ọmọ Hamu ni: Kuṣi, Ijipti, Puti ati Kenaani. 7Àwọn ọmọ Kuṣi ni: Seba, Hafila, Sabita, Raama ati Sabiteka. Àwọn ọmọ Raama ni: Ṣeba ati Dedani. 8Kuṣi ni baba Nimrodu, Nimrodu yìí ni ẹni kinni tí wọ́n mọ̀ ní akọni láyé. 9Pẹlu àtìlẹ́yìn OLUWA, Nimrodu di ògbójú ọdẹ, tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n máa ń fi orúkọ rẹ̀ súre fún eniyan pé, “Kí OLUWA sọ ọ́ di ògbójú ọdẹ bíi Nimrodu.” 10Ìjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti Babeli, Ereki ati Akadi. Àwọn ìlú mẹtẹẹta yìí wà ní ilẹ̀ Babiloni. 11Láti ibẹ̀ ni ó ti lọ sí Asiria, ó sì tẹ Ninefe dó, ati Rehoboti Iri, ati Kala, 12ati ìlú ńlá tí wọn ń pè ní Reseni tí ó wà láàrin Ninefe ati Kala.
13Ijipti ni ó bí Ludimu, Anamimu, Lehabimu, Nafutuhimu, 14Patirusimu, Kasiluhimu, (lọ́dọ̀ ẹni tí àwọn ará Filistia ti ṣẹ̀) ati Kafitorimu.
15Àkọ́bí Kenaani ni Sidoni, òun náà ni ó bí Heti. 16Kenaani yìí kan náà ni baba ńlá àwọn ará Jebusi, àwọn ará Amori, àwọn ará Girigaṣi, 17àwọn ará Hifi, àwọn ará Ariki, àwọn ará Sini, 18àwọn ará Arifadi, àwọn ará Semari, ati àwọn ará Hamati. Lẹ́yìn náà ni ìran àwọn ará Kenaani tàn káàkiri. 19Ilẹ̀ àwọn ará Kenaani bẹ̀rẹ̀ láti Sidoni, ní ìhà Gerari, ó lọ títí dé Gasa, ati sí ìhà Sodomu, Gomora, Adima, ati Seboimu títí dé Laṣa. 20Àwọn ọmọ Hamu nìwọ̀nyí ní ìdílé ìdílé wọn, olukuluku ní agbègbè tirẹ̀, oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè ni wọ́n, wọ́n sì ń sọ oríṣìíríṣìí èdè.
21Ṣemu, ẹ̀gbọ́n Jafẹti, náà bí àwọn ọmọ tirẹ̀, òun ni baba ńlá gbogbo àwọn ọmọ Eberi. 22Òun náà ni ó bí Elamu, Aṣuri, Apakiṣadi, Ludi, ati Aramu. 23Àwọn ọmọ Aramu ni: Usi, Huli, Geteri, ati Maṣi. 24Apakiṣadi ni baba Ṣela, Ṣela sì ni baba Eberi. 25Àwọn ọmọkunrin meji ni Eberi bí, orúkọ ekinni ni Pelegi, nítorí pé ní ìgbà tirẹ̀ ni ayé pínyà, orúkọ ekeji ni Jokitani. 26Jokitani ni baba Alimodadi, Ṣelefu, Hasamafeti, Jera, 27Hadoramu, Usali, Dikila, 28Obali, Abimaeli, 29Ṣeba, Ofiri, Hafila, ati Jobabu, àwọn ni ọmọ Jokitani. 30Ilẹ̀ tí wọn ń gbé bẹ̀rẹ̀ láti Meṣa, ní ìhà Sefari títí dé ilẹ̀ olókè ti ìhà ìlà oòrùn. 31Àwọn ni ọmọ Ṣemu, ní ìdílé ìdílé wọn, olukuluku ní agbègbè tirẹ̀. Oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè ni wọ́n, wọ́n sì ń sọ oríṣìíríṣìí èdè.
32Ìdílé àwọn ọmọ Noa ni wọ́n jẹ́, gẹ́gẹ́ bí ìran wọn ní orílẹ̀-èdè wọn. Lára wọn ni àwọn orílẹ̀-èdè ti tàn ká gbogbo ayé lẹ́yìn ìkún omi.

Currently Selected:

JẸNẸSISI 10: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy