1
ORIN DAFIDI 46:10
Yoruba Bible
YCE
“Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ni Ọlọrun. A gbé mi ga láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, a gbé mi ga ní ayé.”
Compare
Explore ORIN DAFIDI 46:10
2
ORIN DAFIDI 46:1-2
Ọlọrun ni ààbò ati agbára wa, olùrànlọ́wọ́ tí ó wà nítòsí nígbà gbogbo, ní ìgbà ìpọ́njú. Nítorí náà ẹ̀rù kò ní bà wá bí ayé tilẹ̀ ṣídìí, bí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ṣípò pada, tí wọ́n bọ́ sinu òkun
Explore ORIN DAFIDI 46:1-2
3
ORIN DAFIDI 46:4-5
Odò kan wà tí omi rẹ̀ ń mú inú ìlú Ọlọrun dùn, ìlú yìí ni ibùgbé mímọ́ Ọ̀gá Ògo. Ọlọrun wà láàrin rẹ̀, kò ní tú bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣí kúrò; Ọlọrun yóo ràn án lọ́wọ́ ní òwúrọ̀ kutukutu.
Explore ORIN DAFIDI 46:4-5
4
ORIN DAFIDI 46:9
Ó dáwọ́ ogun dúró ní gbogbo ayé, ó ṣẹ́ ọrun, ó rún ọ̀kọ̀, ó dáná sun kẹ̀kẹ́ ogun.
Explore ORIN DAFIDI 46:9