Ìgbanájẹ: Ìtọ́sọ́nà tí ó Rọrùn fún Àdúrà ÌgboyàÀpẹrẹ

Ignited: A Simple Guide for Bold Prayer

Ọjọ́ 6 nínú 6

Ó Ṣé Pàtàki Sì Ọlọ́run

A lè gbàdúrà fún ohunkóhun. Gẹ́gẹ́ bí Christine Caine ṣe máà ń sọ "Bí ó bá ṣe pàtàkì sì ọ, ó ṣe pàtàkì sì Ọlọ́run" Bí ó bá jẹ ohun ti a bìkítà fún tàbí ṣe àníyàn nípa rẹ̀ ni, ó yẹ kí o jẹ nǹkan tí ó yẹ láti gbàdúrà nípa rẹ̀ pẹ̀lú.

Pọ́ọ̀lù gbà wá ni ìyànjú nínú ìwé Fílípì 4:6-7 wípé

"Ẹ má ṣe ṣé àníyàn ohunkóhun; ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọ́run. Àti àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmòye gbogbo lọ, yóò pa ọkàn àti èrò yín mọ nínú Krístì Jésù". (CSB).

Kíni ohun tí a lè gbàdúrà nípa rẹ̀? Kedere ní ìdáhùn Pọ́ọ̀lù: ó ní ohun gbogbo! Kò sí ohun tí ó kéré bí ó bá kan tí Ọlọ́run. Àti bi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyìí "Má ṣe ṣé àníyàn nípa ohunkóhun" lè jọ pé wọn kò ní àánú fún ìṣòro èyíkéyìí tí ó d'ojú kọ wa, ó ṣe pàtàkì láti ṣe àkíyèsí wípé ó kọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ìgbà tí ó wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n.

Pọ́ọ̀lù kò sọ fún wa láti sọ "Má ṣe ṣé àníyàn, jẹ́ kí inú rẹ máà dùn" di ògèdè. Láti fi ojú fò tàbí láti mú àdínkù bá òtítọ́ ipò tí a wà lè dàbí í wípé a kò mọ ohun tí a ń ṣé. Ṣùgbọ́n ọ̀nà kan wà fún wa láti ni ìrírí àlàáfíà àti agbára Ọlọ́run nínú àníyàn àti ìnira wá, ìdí rẹ̀ nìyìí tí Pọ́ọ̀lù fi ń gba wa ní ìyànjú láti "mú àwọn ìbéèrè wa wá sí iwájú Ọlọ́run". Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run ń kó ipa púpọ̀ nínú àbójútó àgbáyé àti àwọn ọ̀ràn tí ó ṣe kókó ni àgbáyé, ṣùgbọ́n Bàbá wa tí ń bẹ ni ọrùn náà ń kó ipa, Ó sì ń ṣe àníyàn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ lórí ìgbé ayé àwọn ọmọ Rẹ̀: iṣẹ́ wá, àwọn ìbáṣepọ̀, àwọn ìmọ̀lára, àwọn ìbẹ̀rù, àti àwọn ìdáwọ́lé wá ní ojoójúmọ́

Ọlọ́run rí ọ, Ọlọ́run mọ̀ ọ́, àti wípé ni òtítọ́ Ọlọ́run bìkítà nípa rẹ.

Bí ohun kan bá ṣe pàtàkì sì ọ, ó ṣe pàtàkì sì Ọlọ́run pẹ̀lú. Nítorí náà, gbàdúrà nípa rẹ!

Àdúrà:

Baba, a dúpẹ́ ni ọwọ́ Rẹ̀ pé Ó bìkítà nípa bíbọ́ àwọn ẹyẹ àti wíwọ àwọn òdòdó ni aṣọ, ìyẹn sì jẹ́ ìdá kan nínú bí Ó ṣe bìkítà nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí ó jẹ́ ti ìgbé ayé mi àti àwọn ohun tí ó wà ní ọkàn mi. Lónìí, mo kó gbogbo àwọn ohun tí ó wà ní àkíyèsí mi wá sì iwájú Rẹ̀: jọ̀wọ́ fi ọgbọ́n, ìwàláàyè, àti àgbàrá Rẹ̀ hàn mí ní àwọn àgbègbè wọ̀nyí. Àti wípé mo béèrè pé bí O ṣe bìkítà nípa àwọn nǹkan tí ó ṣe pàtàkì sì mi, ìwọ yíò mọ ìfiyèsí àti ìfẹ́ mi sì àwọn nǹkan tí ó ṣe pàtàkì sì Ọ. Jẹ́ kí ìjọba Rẹ̀ dé ní ayé, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní ọ̀run. Àmín.

Ètò ẹ̀kọ́ kíkà yí wà lórí aṣẹ́ oníṣẹ́ ©2023 Propel Women, tí ó jẹ́ apá kan iṣẹ́ ìránṣẹ́ Equip & Empower. Àyàfi bí a bá kọ ọ́ bẹ́ẹ̀, gbogbo àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ wá láti inú Christian Standard Bible®, Copyright ©2017 láti ọwọ́ Holman Bible Publishers. A lò wọ́n pẹ̀lú àṣẹ. Christian Standard Bible® and CSB® jẹ́ àwọn àmì-ọjà tí Ilé-iṣe Ìtẹ̀wé Bíbélì Holman, a sì ṣe àkọsílẹ̀ wọn pẹ̀lú ìjọba àpapọ̀.

Nípa Ìpèsè yìí

Ignited: A Simple Guide for Bold Prayer

Àdúrà jé ẹ̀bùn, ànfàní nlá láti ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Bàbá wa lọ́run. Nínú ètò ọlọ́jọ́ mẹ́fa yìí, a ó ṣe àwárí ohun tí Jésù kọ́ wa nípa àdúrà àti a ó sì ṣí ọkàn wa payá láti gbàdúrà lóòrèkóòrè àti pẹ̀lú ìgboyà nlá.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Christine Caine - A21, Propel, CCM fún ìpèsè ètò yìí. Tó bá fẹ́ mọ̀ sí, lọ sí https://www.propelwomen.org