Ìgbanájẹ: Ìtọ́sọ́nà tí ó Rọrùn fún Àdúrà ÌgboyàÀpẹrẹ

Ignited: A Simple Guide for Bold Prayer

Ọjọ́ 2 nínú 6

Jésù Kọ́ni Ní Ẹ̀kọ́ Tí Ó Ga Nípa Àdúrà

Jésù kò ní èrò wípé ó yẹ kí a mọ ohun gbogbo nípa àdúrà. Ó fi oore-ọ̀fẹ́ kọ̀ àwọn tí ó ń tọ́ lẹ́hìn tí wọn fẹ kọ̀ bí a ṣe ń gbàdúrà ní àkókò Ìwàásù Orí Òkè, Ó sì ń wí bayi pe:

"Nígbàtí ẹ bá ń gbàdúrà, wọ inú iyàrá rẹ lọ, sé ìlẹ̀kùn mọ́ ara rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ ẹni tí ìwọ kò rí. Nígbà náà ni Baba rẹ tí ó mọ gbogbo ohun ìkọ̀kọ̀ rẹ, yóò san án fún ọ. Ṣùgbọ́n nígbà ti ẹ̀yin bá ń gbàdúrà, ẹ má ṣe àtúnwí asán bí àwọn aláìkọlà, nítorí wọn rò pé a ó tìtorí ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ gbọ́ tiwọn. Ẹ má ṣe dàbí i wọn, nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ ohun tí ẹ ṣe aláìní, kí ẹ tilẹ̀ tó béèrè lọ́wọ́ Rẹ̀.
“Nítorí náà, báyìí ni kí ẹ ṣe máà gbàdúrà:
Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run,
Kí á bọ̀wọ̀ fún orúkọ mímọ́ Rẹ.
kí ìjọba Rẹ dé.
Ìfẹ́ tìrẹ ni kí á ṣe
ní ayé bí wọ́n ti ń ṣe ní ọ̀run.
Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí.
Dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá,
gẹ́gẹ́ bí àwa náà ti dárí ji àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ wá.
Má fà wá sinu ìdánwò,
ṣugbọn gbà wá lọ́wọ́ èṣù."
- Mátíù 6:6–13 (YCE)

Ṣe àkíyèsí àwọn òtítọ́ tí Jésù fi kun:

  • Àdúrà kò ní láti gùn lọ títí tàbí kí ó díjú.
  • Àdúrà kìí ṣe ohun ti a ń ṣe eré ní gbangba, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ọ̀nà láti ni ìdàpọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.
  • Àdúrà jẹ́ ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọdọ Ọlọ́run. Ó ní ìfẹ́ láti dáhùn àdúrà wa ti a ba tọ̀ ọ́ wá.
  • Àdúrà jẹ́ ànfàní láti jọ́sìn fún àti láti mọ títóbi Rẹ̀.
  • Àdúrà lè jẹ́ fún ìtọrọ ìdáríjì ẹ́ṣẹ́, ìbéèrè fún ìpèsè, àti wíwá ìfẹ́ Ọlọ́run.
  • Àdúrà a máà mú ìtẹ̀síwájú bá Ìjọba Ọlọ́run ni àgbáyé!

Ìmọ̀ọ́ṣe àti ọ̀làjú wá kò já mọ nǹkan-kan, nítorí wípé a kò gbé ọkàn wa lè agbára àdúrà wa. Ìgbẹ́kẹ̀lé wá wà nínú àgbàrá Ọlọ́run, tí Ó fẹ wá ti O si tẹ́tí sì ìgbé wá, tí Ó sì ń dáhùn tí a bá gbàdúrà sí. Ìdí nìyí tí a fi ń gbàdúrà.

Àwọn "ọ̀rọ̀ títọ́" tàbí irúfẹ́ àgbékalẹ̀ kọ́ ni kókó àdúrà. Jésù fúnra Rẹ̀ ni.

Àdúrà:

Baba wa ọrun, ọ̀wọ̀ ni fún orúkọ mímọ́ rẹ. Kí ìjọba rẹ dé. Ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe ní ayé bí wọn tí ń ṣe ní ọ̀run. Fún wa ní oúnjẹ òójọ̀ wá loni. Dárí ẹ̀ṣẹ̀ wá jì wá, bí a ṣe ń darí ẹ̀ṣẹ̀ jí àwọn tí ó ṣẹ́ wá. Má fà wá sínú ìdẹwò, ṣùgbọ́n gbà wá lọ́wọ́ ẹni ibi.

Nípa Ìpèsè yìí

Ignited: A Simple Guide for Bold Prayer

Àdúrà jé ẹ̀bùn, ànfàní nlá láti ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Bàbá wa lọ́run. Nínú ètò ọlọ́jọ́ mẹ́fa yìí, a ó ṣe àwárí ohun tí Jésù kọ́ wa nípa àdúrà àti a ó sì ṣí ọkàn wa payá láti gbàdúrà lóòrèkóòrè àti pẹ̀lú ìgboyà nlá.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Christine Caine - A21, Propel, CCM fún ìpèsè ètò yìí. Tó bá fẹ́ mọ̀ sí, lọ sí https://www.propelwomen.org