Ìgbanájẹ: Ìtọ́sọ́nà tí ó Rọrùn fún Àdúrà ÌgboyàÀpẹrẹ

Ọ̀nà Mẹ́fà Láti Gbàdúrà
Bí o bá ṣe ìwádìí lórí ayélujára nípa "bí a ṣe ń gbàdúrà,” ìwọ yíó rí ọgọgọ́rọ̀rùn, bí kìí bá ṣe ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀, èrò, ìṣe, àti ìlànà nípa àdúrà. Kò sí ọ̀nà kan pàtó tí a fi ń gbàdúrà, ṣùgbọ́n àwọn ìtọ́sọ́nà wà tí ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́:
Gbàdúrà ní Àwọn Àkókò tí Ó ti là K'alẹ̀ àti Lójú-ẹsẹ̀
Ó ṣe pàtàkí láti ní àwọn àkókò ìyàsọ́tọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run àti àwọn àsìkò ojú-ẹsẹ̀. Ìwe-mímọ́ gbà wá ní ìyànjú láti gbàdúrà láì sinmi (1 Tẹsalóníkà 5:17). Ní ìgbàkúùgbà, ní ibikíbi tí o bá ti lè ṣe bẹ́ẹ̀, gbàdúrà!
Dá Nìkan Gbàdúrà àti Pẹ̀lú Àwọn Ẹ́lòmíràn
Ní ìgbà tí ó bá nira láti gbọ́ ohùn Ọlọ́run, a máa ṣe ìrànwọ́ láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tí ó lè gbàdúrà pẹ̀lú wa. Ní inú Bíbélì, a rí Ọlọ́run tí Ó bá àwọn ènìyàn pàdé lọ́kọ̀ọ̀kan nínú àdúrà (Mátíú 6:6), bí wọn ṣe ń gbàdúrà papọ̀ (Mátíú 18:20), àti ní àgbáríjọpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìjọ (Ìṣe Àpóstélì 2:42).
Gbàdúrà Jẹ́jẹ́ àti S'ókè Lálá
Sọ àwọn ọ̀rọ̀ àdúrà rẹ jàde s'íta, kódà ní ìgbà tí o bá ń dá gbàdúrà. Ó lè jọ ìjíròrò, ìwọ yíó sì ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ bí ó ṣe ń rónu nípa wọn, tí ò ń sọ wọn jáde, tí o sì ń gbọ́ wọn.
Gbàdúrà Pẹ̀lú Ọkàn àti Ara Rẹ
Nínú Bíbélì, a rí àpẹẹrẹ àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbàdúrà ní ìdojúbọlẹ̀, ní eekún wọn, ní ìjókòó, ní ìnàró, tàbí pẹ̀lú ọwọ́ wọn ní gbígbé s'ókè. Yíyí ara padà lè ràn wá lọ́wọ́ láti wà lójú ìṣe kí a sì ní ìsopọ̀ mọ́ Ọlọ́run nínú àdúrà.
Gbàdúrà Pẹ̀lú Ọ̀rọ Tìrẹ àti Ti Àwọn Ẹlòmíràn
Ní ìgbà míràn, àdúrà jẹ́ ìtújáde ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ èrò àti ìfẹ́ ọkàn wa bí a ti ń ṣe tú wọn jáde fún Baba; ṣùgbọ́n nínú gbogbo ìtàn ìjọ, àwọn onígbàgbọ́ ti gba àdúra tí a kọ láti ọwọ́ àwọn ẹlòmíràn (tí à ń pé ní ìsìn). Gbígbà àwọn Sáàmù ní àdúrà tàbí àdúrà Olúwa jẹ́ àpẹẹrẹ èyí nínú Bíbélì.
Gbàdúrà Bí O Ṣe Ń Mí
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ pè é ní “àdúrà èémí”, èyí ni ìṣe tí a gbé k'alẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́ ní fífi ojú sun àwọn ìpele-ìpele òtítọ́ kan nínú Bíbélì: ọ̀kan ní mímí s'ínú, èkejì ní mímí s'óde, kí a sí fi ìyókù s'ílẹ̀ fún Ẹ̀mímímọ́ látí kún un gẹ́gẹ́ bí Ó ti ṣe ìlérí (Róòmù 8:26).
Àdúrà:
- Mo gbàgbọ́ (mí s'ínú). Ran àìgbàgbọ́ mi lọ́wọ́ (mí s'óde).
- O wà pẹ̀lú mi lọ́wọ́lọ́wọ́ (mí s'ínú). O ṣeun (mí s'óde).
- Mo dàbí ẹni àìrí (mí s'ínú). O ṣeun nítorí pé O rí mi (mí s'óde).
- Ìwọ ni O dá ara mi (mí s'ínú). Èmi yíó bù ọlà fún un, èmi yíó sì ṣe ìkẹ́ rẹ̀ (mí s'óde).
- Èyí kò rọrùn (mí s'ínú). Èmi yíó dúro láti rí ọwọ́ Rẹ nínú rẹ̀, Olúwa (mí s'óde).
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àdúrà jé ẹ̀bùn, ànfàní nlá láti ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Bàbá wa lọ́run. Nínú ètò ọlọ́jọ́ mẹ́fa yìí, a ó ṣe àwárí ohun tí Jésù kọ́ wa nípa àdúrà àti a ó sì ṣí ọkàn wa payá láti gbàdúrà lóòrèkóòrè àti pẹ̀lú ìgboyà nlá.
More