Ìgbanájẹ: Ìtọ́sọ́nà tí ó Rọrùn fún Àdúrà ÌgboyàÀpẹrẹ

Àdúrà máa ń mú kí ìgbàgbọ́ wa ní agbára sí i
Ní ìgbà tí a bá rí àwọn àìní àti àwọn ànfààní ńlá ní àgbáyé, ó lè jẹ́ ìdánwò láti gbé ojú kúrò tàbí kí á rò pé a ní láti yára yanjú wọn. Ṣùgbọ́n ó yẹ kí a fi ìgbọ́ràn àti ìgbàgbọ́ dáhùn, kí a sì ṣe ohun tí Jésù sọ pé kí a ṣe ní ìgbà tí a bá da ojú kọ ìpèníjà “ìkórè ńlá pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ díẹ̀”, ìyẹn sì ni pé kí á kọ́kọ́ gba àdúrà. À ń gba àdúrà ní òòrèkóòrè pẹ̀lú ìgboyà pé kí Ọlọ́run ìkórè ṣe ohun tí o tí ṣe ìlérí láti ṣe: Láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde. Láti mú wá tẹ̀ sí iwájú.
Àdúrà máa ń tú agbára, ìwàláàyè àti ìpèsè Rè sílẹ̀ nínú ayé wa.
Ó jẹ́ ìyàlẹ́nu pé a tilẹ̀ lè sọ ọ̀rọ̀ náà, “Baba wa,” gẹ́gẹ́ bí a ti rí nínú Mátíù 6:9. Ọlọ́run jẹ́ mímọ́ àti ohun ìyanu ní gbogbo ọ̀nà, ṣíbẹ̀ Ó sì tún jẹ́ Baba wa, ẹni tí kì í ṣe pé ó pè wá láti bá a sọ̀rọ̀ nìkan ṣùgbọ́n láti sún mọ́ ìtẹ́ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ (Hébérù 4:16). Ọlọ́run fẹ́ wà pẹlú ìfẹ àìnípẹ̀kun - tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ó fi Ọmọ Rẹ̀ fún wa (Jòhánù 3:16).
Ní ìgbà tí a bá ń gba àdúrà sí Ọlọ́run ní órúkọ Jésù, kì í ṣe pé a ń gba àdúrà sí agbára kàn tí kì í ṣe gidi tàbí tí o jẹ̀ ẹni àìdáa. Ó mọ iye irun orí yín. Ó ti mọ ohun tí o máa jẹ̀ kí o tó bẹ̀rẹ̀ síí mí. Ó yàn ọ́, ó sì tẹ́wọ́ gbà ọ́. Bí ó ṣe ní ìfẹ̀ẹ́ rẹ tó nìyẹn, ìdí nìyí tí ó fi máa ń fi etí sílẹ̀ ní ìgbà tí o bá ń gba àdúrà!
Bí a ti n pinnu láti gba àdúrà fún ìkórè ìjọba ńlá, tí a ń dá orúkọ àwọn àìní ayé àti ti tiwa, Ọlọ́run ń mú kí ìgbàgbọ́ wa ní agbára sí i. Ẹ̀mí rẹ̀ ń ṣiṣẹ́ nínú wa, nípasẹ̀ wa, àti síwá bí a ṣe ń gba àdúrà, tí ó sì ń rán wa létí pé a ju olùbẹ̀bẹ̀ tí ó ń ṣe igbọràn lọ ní iwájú rẹ̀, àwa jẹ́ alábàáṣisẹ́pọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀.
Àdúrà:
Baba, mo dúpẹ́ pé ẹ ní ìfẹ̀ẹ́ mi àti pé ẹ máa ń fi etí sí ádùrá mi. Ẹ ṣeun fún ìdáhùn yín tí ó ní agbára, tí ó bọ́ sí akókò, tí ó sì jẹ́ ti inú rere. Mo dárúkọ àwọn tí o wà nínú ìdílé mi ní iwájú yín àti agbègbè mi ti kò mọ̀ yín, mo beere pé kí ẹ ràn ènìyàn sínú ayé wọn láti wàásù Jésù fún wọn. Mo sì gba àdúrà pé kí ẹ rán mi pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìgboyà níbikíbi tí ẹ bá pè mí láti gba àdúrà tàbí láti sọ ohun tí ẹ ti ṣe. Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àdúrà jé ẹ̀bùn, ànfàní nlá láti ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Bàbá wa lọ́run. Nínú ètò ọlọ́jọ́ mẹ́fa yìí, a ó ṣe àwárí ohun tí Jésù kọ́ wa nípa àdúrà àti a ó sì ṣí ọkàn wa payá láti gbàdúrà lóòrèkóòrè àti pẹ̀lú ìgboyà nlá.
More